Ètò ìdìbò 2027: Ìṣẹ̀lẹ̀ rògbòdìyàn 109 ló ti wáyé lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú láwọn ìpínlẹ̀ ní Nàìjíríà ní ìtàpá sí àdéhùn àlááfíà tó wà nílẹ̀

Aworan awọn olukopa nibi eto ipade alaafia.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Igbimọ to n ri sọrọ alaafia lori eto idibo ọdun 2027, National Peace Committee ti sọ pe ipinlẹ mẹrindinlọgbọn lo ti tapa si adehun lati gba alaafia laaye.

NPC sọ pe ofin mọkandinlaadọfa ni awọn ipinlẹ naa ti tapa si laaarin ọsẹ mẹwaa sẹyin, to si kọminu lori eto idibo ọdun 2027.

Igbimọ ọhun ti Ọgagun Abdulsalami Abubakar alaga rẹ sọ pe akọsilẹ awọn agbeyẹwo ti awọn ṣe laaarin ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ si ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa fi han pe eto idibo ọdun 2027 wa ninu ewu.

Ninu abajade iwadii igbimọ NPC, wọn fidi rẹ mulẹ pe FCT tii ṣe olu-ilu orileede Naijiria naa wa lara awọn ibi ti wọn ti tapa si ofin adehun naa.

Kí làwọn àdéhùn náà?

Ọgagun Abdulsalami Abubakar

Lara awọn adehun ti wọn tapa si ni iwa ipa ati jagidijagan nidi oṣelu, gbigbe iroyin ofege ati iroyin ẹlẹjẹ kaakiri, wiwu iwa ipa, ati awọn miran to to mẹtalelọgbọn ati mọkandinlọgbọn.

Ipinlẹ Kaduna, Edo ati Enugu lo n lewaju ninu awọn ibi ti iwa ipa ti ṣẹlẹ, to fi mọ gbigbe nnkan ija oloro kaakiri.

Wọn ni ipinlẹ Kaduna ni lo ni iṣẹlẹ iwa ipa to pọ julọ pẹlu akọsilẹ mẹsan, nigba ti FCT ni akọsilẹ iwa ipa meje.

Igbimọ naa wa pe fun iwadii kikun ninu awọn akọsilẹ ibi ti wọn ti tapa si awọn adehun naa, ti wọn si rọ awọn ileeṣẹ eeto aabo lati pese aabo fun gbogbo awọn to ṣe ipolongo idibo lai fi ẹlẹyamẹya si.

Bẹẹ ni wọn sọ fun gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu ati awọn oludije lati dẹkun iwa ipa, ki wọn si kọ awọn agbebọn silẹ, lati rii pe ko idunkooko.

Ọjọ́ wo ní ètò ìdìbó yóò wáyé?

Ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, INEC ti sọ ṣaaju pe ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2027 ni eto idibo aarẹ ati ile igbimọ aṣofin yoo waye, nigba ti eto idibo gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ yoo waye lọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2027.

Eto ipolongo idibo aarẹ ati ile igbimọ aṣofin ni INEC sọ pe yoo bẹrẹ lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ, nigba ti ipolongo idibo yoo bẹrẹ lọjọ kẹsan, oṣu Kẹsan fawọn gomina ati ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ.

Àwọn wo ló tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn?

Kete ti aṣẹ INEC waye, ni wọn ti gbe igbimọ ti yoo ri sọrọ alaafia lasiko ipolonbo ati idibo dide, lati le dẹkun awọn iwa ipa ati iwa to tako ofin eto idibo.

Ẹgbẹ oṣelu mọkandinlogun lo tọwọ bọwe adehun alalaafia lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ, lati le gba alaafia ati ifẹ laaye lasiko ipolongo ati idibo ọdun 2027.

Ninu iwe adehun naa, gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu ati awọn oludije sipo patapata ni wọn jọ tọwọ bọwe adehun naa, pẹlu ileri wi pe wọn yoo gbogun ti iwa ipa ati idunkooko.

Bakan naa ni wọ tun ṣeleri wi pe awọn ko ni faaye gba iroyin ofege, lilo awọn ikanni iroyin lọna to tọ, bibọwọ fun awọn eleto idibo ati eleto aabo.

Awọn miran ni didẹkun sisọrọ kugbakugbe, aṣilo agbara, to fi mọ awọn miran.

Kí ló wà nínú àkọsílẹ̀ àbájáde náà

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi abajade naa tun ṣe sọ siwaju, wọn ni gbogbo akọsilẹ iṣẹlẹ mọkandinlaadọfa naa lo jẹ mọkanla ninu rẹ lo n ṣẹlẹ lọsẹ-ọsẹ, to si jẹ pe iwa ipa oṣelu ati jagidijagan lo n lewaju wọn.

O tọka sii wi pe iṣẹlẹ iwa ipa oṣelu mẹtalelọgbọn lo mu ida ọgbọn (30.3%) ninu gbogbo ida ọgọrun; nigba ti iṣẹlẹ mọkandinlọgbọn jẹ ida mẹrindinlọgbọn le diẹ (26.6%.)

"Ikọlu si gbogbo eto oṣelu ati ipolongo lo ni akọsilẹ iṣẹlẹ mọkandinlogun, lo ṣafihan ida mẹtadinlogun; nigba ti idunkooko ni akọsilẹ iṣẹlẹ mẹẹdogun gba ida mẹtala."

Abajade naa tun tọka si awọn iṣẹlẹ meje ti ko faaye gba anfaani lati sọrọ ati kikorajọ, ọrọ abuku, ati ikọlu awọn ẹgbẹ oṣelu, ati fifa oludibo mọra.

Bakan naa ni wọn sọ pe ẹgbẹ oṣelu mẹrin to n lewaju lo ni ida mejidinlaadọrun, to duro fun iṣẹlẹ mẹrindinlọgọrun ninu gbogbo mọkandinlaadọfa naa.

"Iṣẹlẹ mẹrin to n lewaju ninu awọn iṣori naa lo jẹ ida mejidinlaadọrun, to duro fun iṣẹlẹ mẹrindinlọgọrun ninu mọkandinlaadọfa ti a ṣe iwadii rẹ lasiko ayẹwo wa," abajade naa sọ bẹẹ.

Ọ fi kun un pe, "Iṣẹlẹ mẹtadinlọgọta, lo duro fun ida mejilelaadọta apapọ iṣẹlẹ naa, ni ko I ija ojukoju nibẹ."

Igbimọ naa wa ṣe ikilọ pe idunkooko, iroyin ofege, idiwọ lati sọrọ inu ẹni jade, ọrọ ẹtanjẹ, ati fifa oju awọn oludibo mọran le di awọn oludibo lọwọ lati lọ dibo fun ẹni to wu wọn lọkan lọjọ idibo.

Àwọn ìpínlẹ̀ wo lẹ̀rẹ̀ yíì bá wí?

Siwaju sii ni igbimọ yii jẹ ko di mimọ pe awọn ipinlẹ bii Kaduna, Edo, Cross River, Kogi ati Borno wa lara awọn ipinlẹ tọrọ naa kan.

Wọn ni akọsilẹ awọn fi han pe ipinlẹ Kaduna lo n lewaju pẹlu iṣẹlẹ mẹsan, nigba ti ipinlẹ Edo, Enugu ati FCT n tẹle e pẹlu iṣẹlẹ meje-meje.

O ṣalaye pe, Awọn iṣẹlẹ wọnyi lo jẹ pe kaakiri agbegbe ti ipolongo ti waye, to fi mọ ori ayelujara, iwọde oṣelu, ipade, ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu, ohun elo idibo, ọrọ ita gbangba ati awọn adojukọ pẹlu awọn eleto aabo."

Nigba ti wọn n tọka si oniruuru iṣẹlẹ ti wọn ṣe akọsilẹ rẹ, NPC sọ pe lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹsan, ni awọn kan da ọkọ akọwọrin gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ, Peter Obi to tun jẹ oludije dipo Aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu NDC duro nitosi Makurdi, ipinlẹ Benue.

Ni ipinlẹ Enugu, NPC sọ pe awọn agbebọn da ipejọpọ ẹgbẹ oṣelu NDC ati PDP ru ninu oṣu Kẹsan ati oṣu Kẹwaa.