Nigeria vs Tanzania: Wo gbogbo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nipa ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lọjọ Ẹti, ọsẹ yii ni ifẹsẹwọnsẹ bọọlu yoo waye laaarin ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti orileede Naijiria ati akẹgbẹ wọn lati Tanzania.
Papa iṣere Godwill Akpabio to wa niluu Uyo, ipinlẹ Akwa Ibom ni Naijiria yoo ti gbalejo awọn agbabọọlu Tanzania
Ifẹsẹwọnsẹ naa lo wa lara igbaradi awọn orileede ilẹ Afrika lati kopa ninu idije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ tii ṣe Africa Cup of Nations.
Ifẹsẹwọnsẹ ọhun yoo ti waye ti abala Group, ẹlẹẹkẹta ni yoo waye lagogo marun-un irọlẹ ọjọ Ẹti naa.
Gbogbo awọn ololufẹ ere bọọlu, paapaa ti Super Eagles, to fi mọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Tanzania ni yoo wa ni papa iṣere naa.
Nibẹ Naijiria yoo ti maa foju sọna lati bori ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun, leyi ti yoo fun wọn ni afojusun lati yege fun idije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ.
Ifẹsẹwọnsẹ meji ni Super Eagles ti gba ni ipele yii.
Super Eagles koju Madagascar pẹlu aayo meji si ookan ni Uyo kan naa yii, bẹẹ ni wọn padanu sọwọ akẹgbẹ wọn lati Guinea-Bissau ninu ifẹsẹwọnsẹ keji.
Ipò kelòó ni Super Eagles wà lórí tábìli?
Esi ifẹsẹwọnsẹ mejeeji yii lo jẹ ki Super Eagles wa ni ipo keji lori tabili pẹlu ayo mẹta; ti wọn si n tẹle Guinea-Bissau to wa loke tente lori tabili, lori bi wọn ṣe bori ifẹsẹwọnsẹ meji ni ti wọn.
Tanzania lo wa ni ipo kẹta pẹlu ayo kan, nigba ti Madagascar wa ni isalẹ tabili.
Super Eagle nilo maaki mẹta lati le jẹ ki wọn ni aridaju pe awọn yoo yege lati kopa ninu idije to n bọ lọdun 2027.
Ṣugbọn ṣa, awuyewuye to n lọ nigboro ni pe Tanzania ti ni anfaani lati raaye wọ idije naa to fẹẹ waye ni 2027 pẹlu bo ṣe pẹlu awọn orileede bii Kenya ati Uganda ti yoo gbalejo awọn agbabọọlu nilẹ Afrika.
Eyi lo jẹ ki Naijiria, Guinea-Bissau ati Madagascar maa tiraka lati jẹ ki tikẹẹti naa ja mọ awọn lọwọ.
Bi Naijiria ba fi le bori ifẹsẹwọnsẹ naa lọjọ Ẹti, yoo fun ni anfaani lati ni maaki mẹfa lori tabili, ki wọn le di alafo to wa laaarin awọn ati Guinea-Bissau.
Ìgbà wo ni ìpadàbọ̀ yóò wáyé?
Super Eagles naa yoo rin irin ajo lọ sorileede Tanzania lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla lati koju ara wọ fun igbakeji.
Ifẹsẹwọnsẹ mejeeji naa yoo ni ipa to pọ lati ko fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, pẹlu bo ṣe di dandan fun wọn lati bori, lati lee rii daju pe ẹsẹ wọn ko mi lori trabili lati yege.
Orileede Kenya, Tanzania ati Uganda ni idije ifẹ ẹyẹ ilẹ adulawọ yoo ti waye laaarin ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keje, ọdun 2027.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Super Eagles/Facebook
Gẹgẹ bi awọn alakoso Super Eagles sẹ ṣalaye loju opo ayelujara, agbabọọlu mẹrinlelogun ni wọn ti ko lọ si Uyo lati koju akẹgbẹ wọn to wa lati Tanzania.
Awọn naa ni: Calvin Bassy, Ola Aina, Alex Iwobi, Arthur Okonkwo, Semi Ajayi, Benjamin Fredericks, Alhassan Yusuf, Bright Osayi-Samuel, Wilfred Ndidi, Suleiman Mubarak, Abdullahi Bewene, Taiwo Awoniyi ati Fisayo Dele-Bashiru.
Awọn yooku ni Akor Adams, Tochukwu Nnadi, Chibuike Nwaiwu, Moses Simon, Tolu Arokodare, Ademola Lookman, Francis Uzoho, Stanley Nwabali, Tijani Samson, Moses Usor ati Bruno Onyemaechi
Taani Suleiman Mubarak?
Suleiman Mubarak jẹ ọkan lara awọn ọdọ tuntun to ni ẹbun lati gba iwe ipe si inu ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, pẹlu bi ogo rẹ ṣe ṣana idije Czech ti Slavia Prague.
Ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun to n gba ọwọ aarin lori papa ni wọn ṣawari niluu Abuja ninu ẹgbẹ agbabọọlu Right2Win Academy, ko to di pe o lọ darapọ mọ Slavia Prague lọdun 2025.
Gbara to ti darapọ ni awọn eeyan ti bẹrẹ sii ri ọna to n gbe bọọlu rẹ gba, paapaa ninu idije UEFA ti awọn ọdọ.
Goolu marun-un lo gba sinu awọn ninu ifarahan mẹfa to kopa lasiko idije naa.
Bo ṣe fara si idije naa lo fun un lanfaani, leyi to jẹ ki Czech fi kalẹ fun ikọ agba lẹgbẹ agbabọọlu wọn, ko to di pe o darapọ ni ibẹrẹ ọdun 2026.
ỌJọ keje, oṣu Keji, ọdun 2026 ni ogo Suleiman yọ sita, pẹlu bo ṣe kopa ninu goolu mẹrin ti wọn fi bori Czech.
Nigba to ku iṣẹju diẹ ki wọn yọ ọ lati lọ jokoo, Suleiman gba goolu kẹrin sinu awọn, leyi to jẹ ki ariwo tun sọ.
Ipa to n ko ninu ẹgbẹ agbabọọlu naa lo jẹ ki awọn alakoso tun iwe adehun pẹlu rẹ ṣe, ti wọn sọ pe yoo wa pẹlu wọn titi di ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2031.
Ǹjẹ́ Suleiman yóò kópa fún Super Eagles?
Iroyin to n lọ nigboro sọ pe akọnimọ-ọn-gba ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, Eric Chelle ti foju si Suleiman lara, to si ti n wo o lati fi sinu ẹgbẹ agbabọọlu agba U-23 ti yoo lọ fun idije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ lọdun 2027.
Bakan naa ni wọn sọ pe Chelle ti wa lori ipinnu lati lo Suleiman fun Super Eagles, nigba ti wọn ba koju DR Congo, fun ifẹsẹwọnsẹ lati yege fun Africa Cup of Nations.
Suleiman naa ti wa ni ilu Uyo bayii, to si kopa ninu igbaradi ti Super Eagles ṣe lati gbaradi fun kikoju Tanzania lọjọ Ẹti.
Koda orukọ rẹ ti wa ninu akọsilẹ awọn agbabọọlu ti Super Eagles sọ pe yoo kopa.




























