Àwọn jàǹdùkú ṣe ìkọlù sí Sowore ní Ekiti, òun àtàwọn èèyàn rẹ̀ farapa

Sowore jokoo lori bẹẹdi ile iwosan, o de bandeeji mọ owọ ati orukun ninu fidio to wa ni apa ọtun, eeyan kan ti oṣiṣẹ ilera n tọju wa ni apa osi
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oludije sipo aarẹ Naijiria lẹgbẹ oṣelu African Action Congress, Omoyele Sowore, ti fẹsun kan pe niṣe ni awọn kan ṣe ikọlu si oun ni ile ounjẹ kan ni ipinlẹ Ekiti.

Sowore ninu atẹjade kan to fi soju opo X rẹ lọjọ Ẹti fẹsun kan pe niṣe ni awọn janduku ti ijọba ipinlẹ Ekiti n ṣe atilẹyin fun lo ṣekọlu naa si oun atawọn eeyan oun ni ilu Ado Ekiti.

Bakan naa lo tun fẹsun kan pe awọn ẹṣọ aabo ọtẹlẹmuyẹ DSS lo fun awọn janduku naa lọwọ ibi ti awọn wa nitori awọn DSS ti n tẹle awọn lati ọjọbọ ti awọn ti balẹ si ipinlẹ Ekiti.

O fi kun pe ṣaaju ni awọn DSS ti dunkoko mọ alakooso ile ounjẹ ti awọn ti jẹun, ti wọn si sọ fun pe ko gbọdọ gba awọn laaye ni ile ounjẹ rẹ mọ to si jẹ pe lẹyin ti oun pari ifọrọwerọ ti oun lọ ṣe ni ileeṣẹ redio MIDAS FM ni ikọlu naa waye.

Amọ ileeṣẹ ọlọpaa tẹka ipinlẹ Ekiti ni bẹẹ kọ ni ọrọ ri pe ifanfa kekere lo waye laaarin Sowore atawọn eeyan kan eyi to mu ko farapa to si ti gba itọju nile iwosan.

Ṣugbọn Sowore ninu atẹjade mii to fi lede ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpaa mọọmọ n fi oju kekere wo iṣẹlẹ naa, to si jẹ pe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Michael Falade ṣe abẹwo sibi ikọlu ọhun.

O fi kun pe oun ko ni ifanfa pẹlu ẹnikẹni bikoṣe pe awọn kan lo wa kọlu oun atawọn eeyan oun ti awọn si farapa gidi.

"Kọmiṣanna ọlọpaa ri awọn to farapa, o ri nnkan to ṣẹlẹ lẹyin ikọlu naa, to si mọ bi ikọlu naa ṣe lagbara to. Sibẹ ileeṣẹ ọlọpaa fi oju tẹmbẹlu ikọlu naa, ti wọn si pe ifarapa naa ni kekere."

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu ti fi atẹjiṣẹ kan lede pe Sowore atawọn eeyan rẹ wa ni ile iwosan Police Hospital nibi ti wọn ti n gba itọju lẹyin ikọyin kan.

Abutu kọ sinu atẹjade naa pe awọn ẹṣọ aabo gba iroyin pe Sowore atawọn eeyan kan n ni ifanfa ni ile ounjẹ kan ni Ado Ekiti ti awọn si lọ sibẹ lati lọ ṣe iranwọ fun-un.

O ni lẹyin tawọn ọlọpaa debẹ ni wọn gbe Sowore atawọn eeyan rẹ lọ sile iwosan Police Hospital lati gba itọju lori ara ti wọn fi pa.

O fi kun pe Kọmiṣanna ọlọpaa, Michael Falade ti ni ki iwadii bẹrẹ lori ohun to ṣokunfa ikọlu naa, ki wọn si ṣawari gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ, ki wọn si fi ẹnikẹni ti iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori wina ofin.

O rọ gbogbo awọn eeyan lati ṣe suuru, ki wọn wa ni pẹlẹ kutu, ki wọn kọti ọgbọin si iroyin to ni pe wọn ji Sowore gbe ni Ekiti, ki wọn si ye fidi iroyin ti wọn ko ba ṣewadii rẹ mulẹ.

Ṣaaju ni Sowore ti kọkọ fi soju opo rẹ awọn kan ṣe ikọlu si Sowore, ti awọn ko si mọ ibi to wa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iru iroyin bẹẹ le ṣi awọn eeyan lọkan nitori kii ṣe ootọ nitori ile iwosan ni Sowore to ti n gba itọju.