Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Olọ́pàá ṣàlàyé lórí ikú Tolufe, gbajúmọ̀ oníṣòwò tí wọ́n ló pa ara rẹ̀ l'Ondo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iwadii lori iku gbajumọ oniṣowo kan; Akinbolusere Kayode, tawọn eeyan mọ si Tolufe.
Lọjọ Ẹti ni Alukoro ọlọpaa Ondo,DSP Abayomi Jimoh, kede eyi pẹlu alaye pe awọn ri ike meji to jẹ ti majele nibi igbo kan to wa nitosi.
Eyi n waye lẹyin ti iroyin iku Tolufe gbode l'Ọjọbọ, ohun to si n lọ kari ayelujara ni pe Tolufe pa ara rẹ ni.
Ṣaaju ni Oloogbe naa ti ṣe fidio ibi to ti n sọ pe oun kó gbogbo nnkan ini oun fun iyawo atawọn ọmọ mẹta toun bi, ati pe ẹnikẹni ko fipa mu oun lati ṣe bẹẹ.
Oloogbe naa sọrọ pẹlu ẹdun ọkan ninu fidio ọhun,bẹẹ lo ki iyawo rẹ pe adurotini lọjọ iṣoro ni.
Lẹyin eyi ni iroyin gbode, pe Tolufe ti ku sinu ọfiisi rẹ lagbegbe Igba, niluu Ondo, l'Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 2026.
Nnkan bii aago mẹta ọsan ni wọn lo dagbere faye, wọn fi to ọlọpaa leti, awọn agbofinro si bẹrẹ iṣẹ lori rẹ .
Ninu atẹjade wọn, Kọmiṣanna ọlọpaa Ondo;Felix Ohagwu,paṣẹ pe ki wọn wadii iku naa de gongo, paapaa lati tan imọlẹ si abala gbigba ẹmi ara rẹ.
Ko si àpá kankan tabi ohunkohun to fi han pe wọn ba a ja ṣaaju iku naa lara oloogbe, gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe fidi ẹ mulẹ.
Wọn ti gbe oku rẹ si ile igbokusi fun ifipamọ ati ayẹwo.
Kọmandi ọlọpaa Ondo rọ araalu lati ma ṣe pin ohun ti ko ṣẹlẹ ka lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn ki wọn jẹ ki iwadii fi ohun to fa iku naa gan-an han.
Bi ẹnikẹni ba ni irobinujẹ ọkan, wọn gba wọn niyanju lati tete sọ ọ jade, dipo gbigbe igbesẹ to le mu awuyewuye wa lẹyin wọn.
Ki ni Oloogbe sọ ṣaaju iku naa?
Ninu fidio ti Oloogbe Akinbolusere gbe jade ṣaaju iku rẹ, o wa ninu ọkọ adani, o si ṣalaye pe:
"Mo n ṣe fidio yii lorukọ ẹbi mi, Èmi, Akinbolusere Kayode, mo n ṣe akọsilẹ ọna pinpin ogún mi.
"Mo n ṣe eyi funra mi ni, ẹnikẹni ko fipa mu mi. Emi ni mo ji funra mi ti mo gba ibiṣẹ lọ, ti mo si fi iyawo mi silẹ sile.
"Maṣinni akọkọ ati ikeji ti mo fi n ṣiṣẹ bajẹ, ikẹta naa tun bajẹ, mo wa wo o pe iru igbesi aye wo ree."
Oloogbe naa tẹsiwaju pe ootọ inu loun fi bẹrẹ aye oun ati okoowo, lasiko ti ko si owo lowo oun rara. Koda, o ni iṣẹ gẹrigẹri (barbing) loun n ṣe tẹlẹ ki ọla too de.
Oloogbe Tolufẹ sọ pe oun loun fi ayọ fọ gbogbo ẹ loju, iyawo oun ko daamu oun nigba kankan.
O fi kun un ninu fidio naa pe:
" Iyawo mi mọ bi mo ṣe jiya, o duro ti mi, ko ni mi lara, obinrin ti wọn fi n ṣe adura fobinrin ni.
"Mo jọwọ gbogbo ohun ti mo fi ọwọ mi ko jọ fun iyawo mi, Akinbolusere Adenike Esther, ọmọ Akinsuyi to wa lati ilu Ekiti, atawọn ọmọ mi mẹtẹẹta to wa lorilẹede Canada."
Nigba aye rẹ, Oloogbe Akinbolusere ni wọn lo ni Estate kan ti a mọ si Esther Estate, bẹẹ lo si jẹ oniṣowo to gbajumọ to si ri ti aje ṣe.
Amọ ohun pato to fa iku naa ko ti I han saye, nitori ko sọ pe oun yoo pa ara oun ninu fidio rẹ, ohun ini nikan lo fi ọrọ ẹnu pin ṣaaju iku.
Ẹni ọdun mẹrindinlaadọta (46) ni wọn pe Oloogbe Akinbolusere Kayode, o si n gbe ni Road 7, Housing Estate, Igba nipinlẹ Ondo, ṣaaju iku ojiji naa.