Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ASUU, ẹ̀ka ti Lautech l'Ogbomoso bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nile ẹkọ giga fasiti ni Naijiria, ASUU, ẹka ti ile-ẹkọ Lautech to wa niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo ti gun le iyanṣẹlodi.
ASUU ni Lautech ni wọn n beere fun awọn ohun to jẹ ẹtọ wọn ati owo oṣu ajẹẹlẹ, eyi ti wọn sọ pe ijọba ko san fun awọn.
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ naa ko fi gbedeke ọjọ ti iyanṣẹlodi wọn yoo wa si opin, ṣugbọn wọn sọ pe o digba ti ijọba ba da wọn lohun, ko to di pe awọn pada sẹnu iṣẹ wọn.
Wọn ni lati ọdun 2025 tijọba apapọ ti ba wọn ṣe ipade, ti wọn si ṣe adehun fun wọn, ni awọn ko ti gbọ ohunkohun latigba naa.
Oru Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ni ẹgbẹ naa sọ pe iyaṣẹlodi awọn bẹrẹ, pẹlu ikilọ pe oṣiṣẹ kankan ko gbọdọ lọ sile-ẹkọ naa lati ṣiṣẹ.
Wọn ni ọjọ mẹrinla gbako ni awọn yoo fi gun le iyanṣẹlodi onikilọ naa, ati pe bi ijọba apapọ ba kọ lati tẹti si awọn, yoo di dandan lati lọ fun ọlọjọ gbọgbọrọ.
Ninu atẹjade ti awọn alakoso ASUU, ẹka Lautech fi sita l'Ọjọbọ, awọn alakoso sọ pe awọn ti fẹnuko nibi ipade ti wọn ṣe l'Ọjọru, ọsẹ yii lati gun le iyanṣẹlodi naa.
Atẹjade ọhun ti alaga wọn, Ọjọgbọn Olujimi Dada, ati akọwe rẹ, Ọmọwe Soji Arinola buwọ lu, sọ pe ṣaaju asiko naa lawọn ti ṣe ipade pẹlu awọn alakoso ile-ẹkọ Lautech.
Wọn lawọn jabọ abajade ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn alakoso Lautech fun awọn ọmọ ẹgbẹ, ko to di pe gbogbo wọn fẹnuko nibi ipade pajawiri to waye.
Kí làwọn ohun tí wọ́n ń bèèrè fún?
Gẹgẹ bi ASUU ṣe ṣalaye, wọn sọ pe ninu oṣo Kejila, ọdun 2025 ni ijọba apapọ tọwọ bọwe adehun fun wọn pe ki awọn igbimọ iṣakoso fasiti bẹrẹ sii san awọn owo ajẹẹlẹ ati ẹtọ wọn.
Wọn ni kaka ki awọn fasiti naa mu adehun yii ṣẹ, niṣe ni wọn bẹrẹ sii sọ pe ko sowo nilẹ lati fi san awọn owo ọhun, ti wọn si ni nnkan ko fa idaduro niyẹn.
ASUU sọ pe oniruuru ipade ni awọn ṣe pẹlu awọn alakoso, igbimọ iṣakoso agba fasiti naa, to fi mọ ijọba ipinlẹ Oyo lati le yanju ọrọ naa fun wọn, lai jẹ pe eto ẹkọ dawọ duro.
Wọn ni gbogbo ipade naa ni ko so eso rere, leyi to jẹ ki wọn tun gbe igbesẹ miran lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ti wọn si n beere fun sisan gbogbo gbese naa laaarin ọjọ mẹrinla.
Lara awọn owo ti wọn sọ pe awọn alakoso ati ijọba apapọ n jẹ awọn ni ajẹẹlẹ lati oṣu Kinni, ọdun 2026; awọn owo asanku ti wọn pe ni EAA, ati owo ajẹẹlẹ ori igbega lẹnu iṣẹ laaarin ọdun 2013 si 2025.
Yàtọ̀ sí èyí
Bakan naa ni ẹgbẹ yii tun n beere fun atunto ti yoo mu ayipada rere wa lẹnu iṣẹ wọn, nipa dida igbimọ iwadii ẹsun dide, ati igbimọ ti ọga agba ati awọn olori ẹka ẹkọ.
Siwaju si i ni ASUU tun sọ pe awọn n fẹ ki agbekalẹ ilana eto idibo to ṣoju ṣaara wa, atunṣe awọn ọfiisi awọn oṣiṣẹ, to fi mọ agbekalẹ iṣẹ akanṣe tuntun, paapaa, ẹka ti imọ ayẹlujara tii ṣe 'ICT Unit'.
Ẹgbẹ naa sọ pe lasiko ipade ti awọn ṣe lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹwaa, awọn alakoso fasiti naa sọ pe awọn fẹẹ ṣepade pẹlu Gomina Seyi Makinde, lati le da si ọrọ naa fun wọn, nipa ọna abayọ.
Ṣugbọn sa, wọn ni ipade pẹlu gomina fori ṣanpọn, nitori pe esi ti awọn gba ko lee waye titi digba ti gbedeke ọjọ ti wọn fun wọn fi pe.
Siwaju sii ni wọn jẹ ko di mimọ pe Lautech wa lara fasiti meji ti wọn ko tii bẹrẹ sii mu adehun ọdun 2025 naa ṣẹ lẹkun Guusu-Iwọ-Oorun Naijiria.
Wọn jẹ ko di mimọ pe ile-ẹkọ giga meji to jẹ tipinlẹ Oyo, to fi mọ Lautech ni awọn alakoso rẹ ko tii gbe igbesẹ lori adehun naa.
Ni bayii, wọn ti wa sọ fawọn ọmọ wọn lati dawọ gbogbo ohun to ban ii ṣe pẹlu ẹkọ, idanwo, ipade tabi eyikeyi duro, laaarin asiko iyanṣẹlodi naa.
Bẹẹ ni wọn ṣeleri pe iyanṣẹlodi ọhun yoo maa tẹsiwaju titi digba ti awọn alakoso fasiti naa fi ṣe ohun ti awọn n beere fun.