Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Òní ni ètò ìsìnkú Michael Oyedekun, olùkọ́ tí àwọn ajínigbé gé lórí l'Oyo
Gbogbo eto lo ti pari bayii, fun eto isinku olukọ kan tawọn ajinigbe pa danu lasiko ti wọn ji akẹkọọ ati olukọ gbe nijọba ibilẹ Esinele, ipinlẹ Oyo gbe.
Michael Olugbade Oyedokun lorukọ olukọ naa, ti awọn ajinigbe ọhun pa nipakupa, ti wọn si fi fọnran rẹ sori ayelujara.
Aroko ni awọn ajinigbe ọhun fi iku Oyedokun ṣe fun ijọba apapọ lọjọ naa, pẹlu bi wọn ṣe n beere fun awọn ẹtọ kan.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awon ajinigbe yabo ile ẹkọ mẹta niluu Ogbomoso.
Ahoro Esinele, Yawota ati Alausa ni wọn ti ṣiṣẹ ibi naa, ti wọn pa olukọ kan lasiko ikọlu, ko akẹkọọ mẹtadinlogoji, olukọ meje wọgbo lọ.
Lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ko wọn lọ ni awọn ajinigbe naa fi aworan ibi ti wọn ti bẹ ori olukọ kan, Michael Ojedokun, sori ayelujara, iyẹn lọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun, ọdun 2026.
Latigba naa ni igbesẹ ti n waye lati ri awon to wa nigbekun naa gba kalẹ.
Ṣugbọn ṣa, awọn ti wọn jigbe naa pada gba itusilẹ lọjọ kẹwaa, oṣu Keje, ọdun 2026.
Bawo ni eto isinku naa yoo ṣe lọ?
Ninu atẹjade ti mọlẹbi Oloogbe Oyedokun fi sita eyi to tẹ BBC lọwọ, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe ọjọ Ẹti, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ni eto isinku naa yoo bẹrẹ.
Eto isin onigbagbọ ni awọn mọlẹbi naa sọ pe yoo waye ni gbọngan Eliz to wa lẹyin ileeṣẹ to n ri sọrọ igbokegbodo ọkọ ni Naijiria, FRSC, niluu Osogbo.
Siwaju sii ni wọn sọ pe eto aṣekagba yoo waye ni agboole Olujin to wa ni Caretaker, iyẹn ni adojukọ ile-ẹkọ alakọbẹrẹ ti Baptist, Guusu Ogbomoso.