Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Iná ṣọṣẹ́ lọ́jà Gbagi n'Ibadan, àwọn ọlọ́jà ń bèèrè ìrànlọ́wọ́ ìjọba
Titi di asiko yii ni awọn ontaja lapa ibi ti a mọ si Ajegunle, ninu ọja Gbagi Tuntun, niluu Ibadan, ṣi n tara aje nipa ijamba ina to waye lalẹ Ọjọbọ ọsẹ yii mojumọ ọjọ Ẹti ana.
Gẹgẹ bi awọn eeyan ọja naa ṣe ṣalaye, ina ọhun ṣẹyọ lojiji ni nnkan bii aago meje alẹ Ọjọbọ, ọjọ kọkadinlọgbọn oṣu Kẹwaa odun 2026, ẹnikẹni ko si mọ ohun to fa a.
O le ni isọ mẹtala ti ina naa fọwọ ba ni igun Ajegunle bi wọn ṣe sọ.
Igbiyanju ajọ panapana
Awọn oṣiṣẹ panapana ipinlẹ Oyo wa sibi ijamba ina yii, nnkan bii aago mọkanla aabo alẹ kọja ni wọn si ri ina ọhun pa.
Wọn duro titi di agogo mejila oru ki wọn to kuro ni agbegbe naa.
Adari awọn ẹṣọ panapana Oyo, Adisa Wasiu, rọ awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ lati tete maa fi to ile iṣẹ panapana leti bi wọn ba kẹẹfin iru iṣẹlẹ ijamba ina bayi.
Ki ni awọn ọlọja sọ?
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Abilekọ Ojukonu, ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa kan, salaye pe ni nnkan bii aago meje alẹ ni oun kuro nisọ, ko si ju bii aago meje aabọ ni oun gba ipe pe isọ oun n jona.
Iya naa sọ pe oun sare debẹ, amọ gbogbo isọ oun ti jona raurau.
"Mo ṣẹṣẹ lọ ra ọja ọdun ni, ti gbogbo ọja naa si le ni aadọta miliọnu naira (50m). Gbogbo rẹ lo jona raurau ti ko si ku nnkankan mọ.
"Mo n bẹ ijọba orile-ede Naijiria ati Gomina Oluwaseyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ lati ṣaanu fun wa, nitori pe ọpọ ọja la gba lawin, to jẹ pe ti a ba ta wọn tan ni a too ma da owo naa pada."
Bẹẹ ni Abilekọ Ojukoni wi.
O ni ọmọ oun naa ni isọ ninu ọja yii, koda, isọ ọmọ naa ju ti oun ati ti baba rẹ lọ, amọ ina jo awọn ṣọọbu ọmọ naa pẹlu.
"Ile iwosan ni ọmọ mi wa bayii, nitori ẹmi rẹ ko gbe e mọ."
Bẹẹ ni iya naa wi.
Bakan naa ni Ọlalekan Ayodele toun naa jẹ ọkan lara awọn ti wọn ni isọ nibẹ, salaye pe ko pẹ toun kuro lọja loun gba ipe pe awọn isọ kan n jona l'Ajegunlẹ, ninu Gbagi Tuntun.
Ayodele ni oun ko mọ pe isọ toun gan-an wa lara awọn to n jona nigba ti wọn pe oun naa.
O ni oun ṣẹṣẹ ko ọja wọle ninu ọsẹ yii ni, nitori ọdun tuntun to n bọ lọna.
Ayodele sọ pe awọn ọja to jona ni isọ oun yoo to igba miliọnu (200m).
Awọn ọlọjaa naa rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Oyo ati ijọba apapọ Naijiria lati dide iranlọwọ fun wọn.
Ki ni ijọba wi?
Kọmiṣanna to n ri si Ọrọ aje ati Idagbasoke Awujọ nipinlẹ Oyo, Ọjọgbọn Salihu Abdulwaheed Adelabu,ẹni ti Olajide Mamud Okesade sọrọ lorukọ rẹ, sọ pe:
"Ijọba maa pese ayika to dara fun gbogbo eeyan to n ṣe ọrọ aje nipinlẹ Oyo."
O tun fi da wọn loju pe aabo wa fun ẹmi ati dukia wọn.