Kò sóhun tó burú níbẹ̀ bí obìnrin bá ṣe ìyàwó kejì, ìkẹ́ta tàbí ìkẹ́rin nílé ọkọ- Wasila Coded
Gbajumọ ni Bimpe Akintunde tawọn eeyan mọ si Wasila Coded lagbo tiata Yoruba, ọkan lara awọn oṣere ti ki i fi ọrọ sabẹ ahọn sọ si ni.
Laipẹ yii ni Wasila Coded ba BBC News Yoruba lalejo, to si ṣalaye nipa igbeyawo rẹ to foriṣanpon atawọn nnkan mi-in.
Ninu ifọrọwerọ naa ni Bimpe Akintunde ti sọ pe ko sohun to buru bi obinrin ba jẹ iyawo keji, ikẹta tabi ikẹrin paapaa nile ọkọ, nitori bi kadara ba ṣe to ọrọ ẹda lo gbọdọ gba.
Oṣere naa sọ pe ọkunrin ti awọn obinrin to ti fẹ tẹlẹ ti lọ nile rẹ lo ṣoro lati fẹ to ba nawọ ifẹ si obinrin, o ni o yẹ ki obinrin naa beere pe nibo ni awọn iyawo to ti fẹ tẹlẹ wa ni.
Bakan naa ni Wasila Coded sọ pe ile olorogun ṣoro, amọ eeyan yoo fi le Oluwa lọwọ ni.
Ninu eto yii naa ni awọn obinrin ti sọrọ lori gbigba owo ju ọkọ wọn lọ, awọn ti wọn le fẹ ọkunrin bẹẹ atawọn ti wọn lawọn ko le ṣe e.
Ẹkunrẹrẹ wa ninu fidio yii.

Oríṣun àwòrán, Bimpe Akintunde/ Instagram



