Portable olórin ṣàlàyé bó ṣe jí rí àláàtì N100m lẹ́yìn ìpolongò ìbò fún APC

Oríṣun àwòrán, Portablebaeby/Instagram
Bi ipolongo ibo apapọ ti yoo waye ni 2027 ṣe n waye kaakiri orilẹede Naijiria, Habeeb Okikiola, Portable tawọn eeyan tun mọ si Were olorin ti sọ pe oun ji ri alaati owo ti iye rẹ jẹ miliọnu lọna ọgọrun-un naira (N100m) lorii foonu oun.
Portable to sọrọ yii ninu fidio kan to fi soju opo Instagram rẹ lọjọ Ẹti, ṣalaye pe lẹyin ipolongo ibo toun ṣe fun ẹgbẹ oṣelu APC ni oun ri owo naa.
"Mo ma ri alaati N100m, Yayi lo ni ki wọn fun mi o"
Nigba to n ṣalaye bi owo naa ṣe de apo ikowosi rẹ, Portable sọ pe oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ogun, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Solomon Adeola tawọn eeyan mọ si Yayi, lo tẹ owo naa ranṣẹ soun.
" Ẹyin fansi mi, mo ma ri alaati N100m, Yayi lo ni ki wọn fun mi o.
"IBD Dende ọga mi, Ọlọun a bu kun yin. Mo sun ni, Ọlọun lo ni ki n ma ku. Igba ti mo maa ji bayii lasan, tori lanaa, IBD ni ki n maa lọ sile, pe Yayi lawọn maa ranṣẹ si mi."
O tẹsiwaju pe awọn ara adugbo kan ti wọn jẹ ẹgbọn adugbo wa n sọ pe Yayi n wa oun.
O ni ṣe awọn eeyan naa ni yoo ṣẹṣẹ sọ foun pe Yayi n wa oun ni.
Were olorin sọ pe bawọn eeyan naa ṣe ṣe nigba kan niyẹn ti wọn ko foun ni owo ọna ti Yayi fi ranṣẹ, ti owo naa ko de ọdọ oun.
"Ọlọun o ṣe o, Yayi ti tẹ N100m, ẹ ṣe o. IBD Dende, awọn ọmọ yin a ri ogo wọn lo o, ẹ ẹ pẹ fun wa baba mi. Yayi ti tẹ owo, N100m naa o kere. Ko ni i bajẹ."
Portable to wọ aṣọ ti wọn kọ APC si ninu fidio naa, de fila ti wọn kọ Yayi si, bẹẹ lo tun mu aṣọ ti wọn ya Yayi ati Tinubu si dani.
Tẹ o ba gbagbe, eyi kọ ni igba akọkọ ti Portable yoo kede pe oun rowo gba lẹyin ipolongo APC.
Olorin naa kede lọsẹ diẹ sẹyin, pe oun ti ri owo gba lẹyin ipolongo ibo fun Aarẹ Bola Tinubu.
Ṣaa, awọn ti Portable kede lọtẹ yii pe wọn fun oun ni 100m ko ti i sọ nnkan kan, bẹẹ ni a ko fidi rẹ mulẹ.
























