Amupitan lóun ò ní gba ipò míì lẹ́yìn iṣẹ́ INEC, àlàyé rèé lórí i nǹkan táwọn alága INEC tẹ́lẹ̀ ṣe lẹ́yìn tí wọ́n kúrò nípò

Oríṣun àwòrán, INEC
Alaga ajọ eleto idibo INEC, Ọjọgbọn Joash Amupitan, ti sọ pe oun ko ni gba ipo kankan mọ toun ba ti fi INEC silẹ.
Amupitan sọrọ yii ninu itakurọsọ kan to waye ni Chatham House niluu London l'Ọjọbọ ọjọ kejila oṣu Kọkanla yii.
Alaga INEC fidi ọrọ naa mulẹ nigba to n sọrọ lori akori ti wọn pe ni ''Eto idibo Naijiria ọdun 2027: Irinajo ijọba awarawa ati iduroṣinṣin eto iṣejọba ẹlẹkunjẹkun.''
Ọjọgbọn Amupitan sọ pe oun ko ni gba ipo kankan mọ lọwọ ẹnikẹni tori ṣiṣe alaga INEC da lori i nini igbẹkele ati igboya ninu eniyan.
Ọrọ yii jẹ jade nigba ti ẹnikan beere lọwọ rẹ boya oun naa maa gba ipo lẹyin to ba kuro ni ọfiisi gẹgẹ bi Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ṣe gba ipo aṣoju orilẹede Naijiria nilẹ okeere lẹyin to ṣakoso eto idibo ọdun 2023 tan.
Yakubu wa lara eeyan mejilelọgbọn ti Aarẹ Bola Tinubu forukọ wọn ranṣẹ sile aṣofin agba l'Abuja fun ibuwọlu lọdun 2025 fun ipo aṣoju Naijiria nilẹ okeere.
Orilẹede Qatar ni ijọba Tinubu gbe Yakubu lọ lati maa ṣoju orilẹede Naijiria.
''Iṣẹ ilu ni iṣẹ alaga INEC, ohun aigbọdọ maṣe ni iṣẹ naa.
Kii ṣe iṣẹ ti eeyan maa ṣe tan lẹyin ọdun marun un ti yoo tun maa lọ sin ara rẹ,'' Amupitan lo sọ bẹẹ.
Amupitan ni iṣẹ ilu ni oun ti fi gbogbo ọjọ aye oun ṣe, o ni ko si nnkan to buru ninu koun waye lati ṣe nnkan tara oun naa.
Wọnyi ni igbesẹ tawọn alaga INEC telẹ gbe lẹyin ti wọn kuro nipo.
Justice Ephraim Akpata (1998–2000)
Ephraim Akpata ni alaga ajọ eleto idibo INEC laarin ọdun 1998 si 2000.
Ọgbẹni Akpata to jẹ adajọ fẹyinti ni ile ẹjọ to ga julọ ni Naijira lo ṣakoso eto idibo gbogbogbo ọdun 1999 eyi ti Oloye Olusegun Obasanjo fi wọle ibo aarẹ fun saa kinni.
Ọdun 1999 yii ni ijọba ologun gbejọba pada fun alagbada ni Naijiria.
Akpata ku lọjọ kẹjọ oṣu Kinni ọdun 2000 nigba to si wa lori oye gẹgẹ bi alaga INEC.
Nitori naa, ko lanfaani lati gba ipo mii lẹyin ipo rẹ gẹgẹ bi alaga INEC.
Ọmọwe Abel Guobadia (2000–2005)
Ọmọwe Abel Guobadia lo rọpo Ephraim Akpata gẹgẹ alaga INEC lọdun 2000.
O si wa lori oye naa lati ọdun 2000 si ọdun 2005.
Ọmọwe Guobadia to jẹ onimọ nipa eto ẹkọ fi iṣẹ alaga INEC silẹ lọdun 2005.
Lẹyin naa lo pada sibi iṣẹ gbigba awọn eeyan ni imọran lori eto ẹkọ.
Nigba naa lo ṣe agbekalẹ ajọ to n ṣagbekalẹ oniruuru eto fawọn ile ẹkọ giga fasiti.
O tun kopa ninu idari awọn ile ẹkọ giga fasiti to fi mọ idasilẹ Igbinedon University ni Okada nipinlẹ Edo.
Ọmọwe Guobadia ku lọjọ kẹrin oṣu Keji ọdun 2011 lẹni ọdun mejidinlọgọrin.
Ọjọgbọn Maurice Iwu (2005–2010)
Ọjọgbọn Maurice Iwu to jẹ onimọ nipa pipo oogun di alaga INEC lọdun 2005.
Ọdun 2010 ni o fi INEC silẹ latari oniruuru awuyewuye to ṣuyọ ninu eto idibo ọdun 2007 to ṣe agbatẹru rẹ.
Iwu pada sẹnu iṣẹ oogun pipo rẹ lẹyin to kuro ni ọfiisi gẹgẹ bi alaga INEC.
Ojọgbọn Attahiru Jega (2010–2015)
Ojọgbọn Attahiru Jega jẹ alaga INEC laarin ọdun 2010 si 2015.
Attahiru to jẹ ọjọgbọn ninu eto oṣelu to si tun jẹ ọga agba fasiti Bayero University ni Kano tẹlẹ pari iṣẹ gẹgẹ bii alaga INEC ni ọgbọnjọ oṣu Kẹfa ọdun 2015.
Jega pada sẹnu iṣẹ iwadii rẹ gẹgẹ bii olukọ fasiti lẹyin to kuro lọfiisi gẹgẹ bii alaga INEC.
Bakan naa lo tun n kopa ninu oriṣiiriṣii itakurọsọ nipa eto iṣejọba kaakiri agbaaye.
Ọjọgbọn Mahmood Yakubu (2015–2025)
Ọjọgbọn Mahmood Yakubu di ipo alaga INEC mu laarin ọdun 2015 si 2025.
Ọjọgbọn Yakubu to jẹ onimọ nipa itan to si tun jẹ akọwe agba ajọ TETFund to n ri si idagbasoke eto ẹkọ tẹlẹ ṣe alaga INEC fun saa meji.
Ọjọgbọn Yakubu di aṣoju Naijiria lorilẹede Qatar lẹyin to pari iṣẹ gẹgẹ bi alaga INEC.
Lẹyin to fi INEC silẹ ni Aarẹ Tinubu kede Yakubu gẹgẹ bii ọkan lara awọn aṣoju orilẹede Naijiria mejilelọgbon to yan nigba naa.


























