Ilé-ẹjọ̀ dá Ladi Adebutu ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP padà sínú orúkọ àwọn olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, Lado Media/Facebook
Ileẹjọ giga apapọ to wa niluu Abuja ti paṣẹ fun ajọ eleto idibo ilẹ Naijiria, INEC lati fi orukọ oludije sipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọnarebu Oladipupo Adebutu pada sinu iwe awọn oludije.
Ileẹjọ sọ pe Adebutu ni anfaani ati ẹtọ lati kopa ninu eto idibo apapọ ọdun 2027, gẹgẹ bi oludije sipo gomina.
Onidajọ Peter Lifu to gbọ ẹjọ naa, lo gbe idajọ ọhun kalẹ lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun 2026.
Lifu sọ paṣẹ pe ki INEC da orukọ naa pada laaarin wakati mẹrinlelogun ti idajọ naa jade.
Kí ni ilé-ẹjọ́ sọ?
Ileẹjọ sọ pe ajọ eleto idibo ko ni agbara lati yọ orukọ orukọ oludije ti ẹgbẹ oṣelu fi ibo abẹle yan.
O ṣapejuwe igbesẹ INEC gẹgẹ bi eyi ti ko ba ofin mu, ati eyi ti ko fẹsẹ mulẹ labẹ iwe ofin.
Siwaju sii ni Lifu sọ pe ile-ẹjọ nikan lo ni aṣẹ lati yọ orukọ oludije, tabi kede pe ọna ti wọn gba fa oludije kalẹ gẹgẹ bi oludije, kii ṣe ajọ eleto idibo.
Bi ẹ ko ba gbagbe, inu oṣu Kẹwaa ni ọdun yii ni ajọ eleto idibo yọ orukọ Adebutu kuro ninu akọsilẹ awọn oludije nipinlẹ Ogun.
Kete ti ajọ INEC ti gbesẹ naa ni Adebutu ti sọ pe oun yoo ja fun ẹtọ oun lati wa ninu orukọ awọn oludije lọdun 2027.


























