Igbákejì Ààrẹ kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ lórí ayédèrú ìwé ẹ̀rí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbakeji Aarẹ Indonesia, Gibran Rakabuming Raka ti kọwe fi ipo rẹ silẹ lasiko ti ijọba ilẹ naa n koju awọn iṣoro kan.
Ṣaaju asiko yi ni Gibran ti kọkọ n koju iyọnipo lẹyin ti ile ẹjọ to ga julọ nilẹ naa dajọ pe ayederu iwe ẹri ile ẹkọ girama lo gbe silẹ lasiko ipolongo ibo lọdun 2024.
Ikọwe fipo silẹ rẹ yii lo n waye lẹyin gbas-gbos to n ṣelẹ laarin baba rẹ to jẹ Aarẹ ilẹ naa tẹlẹ, Joko Widodo ati Aarẹ to n ṣejọba lọwọ, Prabowo Subianto.
Lasiko to n ba araalu sọrọ, Prabowo sọ fun awọn akọroyin pe pẹlu ibanujẹ ọkan loun fi gba ikọwefiposilẹ igbakeji oun naa.
Ọgọta ọjọ pere ni ile igbimọ aṣofin orilẹede naa ni lati fontẹ lu eyikeyi ninu eeyan meji ti Aarẹ ọhun fa kalẹ bayii lati rọpo Gibran.
O sọ fun awọn akọroyin naa pe Gibran ti ṣafihan ara rẹ gẹgẹ bii ẹnito ni ifẹ ilu lọkan to si n fẹ ilọsiwaju orilẹede ọhun.
Aarẹ naa sọ siwaju si pe fun anfani orilẹede ọhun ni ikọwefiposilẹ Gibran jẹ.
O ni "O gbagbọ pe o ti pari ẹkọ ni ilana to tọ, amọ a gbọdọ mọ pe bi eto ẹkọ ilẹ okeere ṣe ri yatọ si tiwa nibi ni Indonesia."
Ṣaaju asiko yii ni Gibran ti n koju iṣoro lori boya iwe ẹri rẹ yẹ lati du ipo igbakeji Aarẹ orilẹede naa.
Lẹyin to kawe ni Singapore ati Australia, o lọ gba iwe ẹri kan ti yoo rọpo awọn iwe to ka nilẹ okeere, amọ ọpọ araalu lo gbagbọ pe iwe ẹri naa ko dantọ.
Gẹgẹ bi ofin Indonesia, igbakeji Aarẹ gbọdọ jade nile ẹkọ girama, amọ ile ẹjọ to ga julọ nilẹ naa sọ pe ko si ẹri lati fi han pe Gibran jade nile ẹkọ girama.
Ile ẹjọ ọhun sọ pe "Ko si ẹri maa jẹ mi rinṣo pe Gibran gba oye diploma nilẹ okere tabi iwe ẹri ti a le fi ṣafiwe ile ẹkọ girama tabi iwe ẹri mii to wa nipo rẹ."


























