Ìjọba Ghana tẹ owó tuntun, ohun tó mú owó náà jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Banki apapaọ orilẹede Ghana ti ko owo Cedis tuntun jade ti wọn yoo bẹrẹ si n na lati inu oṣu Kejila, ọdun 2026 yii.
Awọn owo tuntun naa ti wọn pe ni 'Heritage Series' lo jẹ atunṣe si owo ti wọn n na lọwọ bayii.
Owo to wa lode lọwọ yii ni wọn ti n na ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin ki ijọba to ko owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ṣatunṣe rẹ jade.
Mẹjọ ni apapọ iye owo to wa lode lọwọ yii, awọn owo naa ni Ghc1 Ghc 2 Ghc 5 Ghc10 Ghc20 Ghc 50 Ghc100 Ghc200, gbogbo rẹ ni wọn si ti ṣatunṣe si.
Banki apapọ naa ko gbe iye owo tuntun mii jade, o si sọ pe idiyele kan naa lo wa lori owo atijọ ati owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ tẹ.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, ọjọ kinnni, oṣu Kejila, ọdun 2026 ni wọn yoo ko owo tuntun naa jade.
Ki ni awọn iyatọ to wa ninu owo tuntun yii ati owo atijọ?
- GHC 1 to jẹ owo to kere julọ ni aworan Agnes Oforiwa Tagoe-Quarcoopome wa lara rẹ. Obinrin naa lo jẹ oniṣowo to maa n ta aṣọ lẹyin ọdun 1940 ati ẹni akọkọ to ṣi apo ile iforowopamọ lorilẹede naa.
- GHC 2 lo ni aworan oluṣọ agutan Cardinal Peter Dery, eyii to n ṣapẹrẹ igbagbọ orilẹde naa. Oluṣo agutan naa lo ṣiṣẹ gẹgẹ bii biṣọọbu agba Tamale.Wọn tun kọ 'Nyame Dua' si lara, eyii yo n sapẹrẹ aṣa ati ẹsin adayeba ilẹ naa.
- GHC 5 lo n ṣapẹrẹ itan iwe kika ni Ghana. Owo naa ni aworan James Kwagir Aggrey n ti ọpọ ọmọ ilẹ naa mọ si ẹni to fẹran eto ẹkọ wa. Wọn tun fi aworan ile ẹkọ Achimota, to jẹ ọkan gboogi lara awọn ile ẹkọ to gbajumọ julọ nibẹ si ara rẹ.
- GHC 10 n ṣapẹrẹ idajọ ododo. Wọn si fi aworan adajọ akọkọ lorilẹede naa, Annie Ruth Jiagge si lara, to fi mọ aworan ile ẹjọ to ga juọ nibẹ.
- GHC 20 n ṣapẹre ẹka ere idaraya ati aṣa orilẹede Ghana. Lara rẹ ni aworan Ephraim Amu to ti kọ ọpọlọpọ orin ati ewi wa.
- GHC 50 n ṣapẹre iṣọkan orilẹede naa. O ni aworan Theodosia Okoh to gbe asia orilẹede naa lọwọ.
- GHC 100 ṣapẹrẹ alaafia ati iṣọkan ninu eyii ti aworan Aarẹ Kofi Annan wa.
- GHC 200 to jẹ owo to ga julọ nibẹ n ṣapẹre ominira ilẹ naa. O ni aworan Aarẹ akọkọ nibẹ, iyẹn Kwame Nkrumah, to wa lara awọn to ṣamọna ominira orilẹede naa.
Gomina banki apapọ orilẹede naa, Johnson Asiama sọ pe wọn tẹ awọn owo tuntun naa pẹlu ara ọtọ, wọn si ni awọn ohun idabobo igbalode lara.
Ki ni yoo ṣẹlẹ si owo atijọ?
Banki apapọ ilẹ naa sọ pe wọn yoo maa na owo atijọ papọ pẹlu owo tuntun lọwọ yii.
Lẹyin naa lo kilọ fun araalu ki wọn ma kanju lati ni owo tuntun naa lọwọ nitori yoo kari gbogbo ilu laipẹ.
Wọn tun rọ araalu ki wọn tọju owo tuntun naa daadaa, ki wọn ma run, ki wọn ma si kọ nnkankan si lara.


























