Ààrẹ Trump fàṣẹ sí fífún ìyá ọ̀dọ́kùnrin ọmọ Ghana tí wọ́n yìnbọn pa l'America ní físà

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹyin tawọn kan yinbọn pa ọdọkunrin ọmọ ilẹ Ghana ti ọjọ ori rẹ ko ju mẹẹẹdogun lọ, iyẹn Javits Frimpong, l'Ọjọbọ to kọja yii lagbegbe Bronx, l'America; Aarẹ Donald Trump ti faṣẹ si i pe ki wọn fun iya rẹ ni fisa lati wa si America.

Gẹgẹ bi Olootu New York; Zohran Mamdani, ṣe wi, Trump fi anfaani naa silẹ ki iya ọmọde naa le wa lati Ghana si America, lati ṣe ọfọ rẹ bo ṣe yẹ.

''Iya Javits Frimpong yẹ lati waa ki ọmọ rẹ pe o digba. Mo ṣẹṣẹ ba Aarẹ Trump sọrọ tan lorii foonu ni, o si ti gba lati fun un ni fisa lẹsẹkẹsẹ. Gbogbo New York lo n ṣọfọ yii.''

Bẹẹ ni Zohran Mamdani, Olootu New York ṣalaye loju opo X.

O ni iku ọmọ ki I ṣe ohun to yẹ ko ṣẹlẹsi obi, ka ma ti I sọ pe obi ti ko si nitosi ibi ti ọmọ naa ti jade laye.

Iya to bi ọmọ ti wọn pa naa ni Doris Adu Gyamfi, Ghana lo si n gbe.

Ọkọ rẹ; Thomas Frimpong, lo wa l'America ti Jarvits si n gbe pẹlu ki wọn too yinbọn pa a lẹyin ọdun kan ti ọmọ naa de sọdọ baba rẹ.

Ọjọ Aje, ọjọ keji oṣu Kọkanla ni eto iwe irinna ti wọn fẹ fun iya ọmọ yii yoo bẹrẹ ni Accra, olu ilu Ghana.

Bawo ni wọn ṣe pa Javits?

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, nnkan bii aago mẹsan-an aarọ kọja ogun iṣẹju ni awọn kan yinbọn mọ Javits nitosi ile wọn, lasiko ti ọmọ naa n lọ sile ẹkọ.

Ohun ti wọn tori ẹ yinbọn naa ko ti i foju han.

Amọ lọwọ yii, awọn atọpinpin n wa awọn ọdọ mẹta ti wọn jẹ afurasi lori iṣẹlẹ naa.

Ẹrọ ayaworan to wa nibi ti wọn ti yinbọn mọ oloogbe, ṣafihan bi ọmọkunrin naa ṣe n sare ṣaaju ki wọn too yinbọn fun un.

O tun ṣafihan ọkan lara awọn to n le e naa to wọ aṣọ dudu dẹlẹ, to si tun da àwọ̀n boju.

Awọn ọlọpaa sare gbe e lọ si ile iwosan St Barnabas lẹyin ti ibọn ba a, amọ ibẹ lo pada ku si.

Ọjọ ori awọn ọdọ mẹta tawọn alaṣẹ n wa naa ni wọn ni o ṣee ṣe ko wa laaarin mẹrindinlogun si mejidinlogun

Ibi kan ti a mọ si Claremont, nitosi Crotona Park, ni wọn ti yinbọn pa Javits.

Agbegbe yii jẹ ibi ti awọn ọmọ Ghana pọ si l'America.

Ko ti I si ẹnikẹni ti wọn fofin mu lori ọrọ yii lasiko ta a pari iroyin yii, amọ iwadii n tẹsiwaju bi wọn ṣe sọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa New York ni ki ẹnikẹni to ba ni ohunkohun lati sọ lori iṣẹlẹ naa kan si ẹka to n dẹkun iwa ọdaran.

Iru ọmọ wo ni Oloogbe Javits?

Thomas Frimpong to bi Oloogbe Javits, ṣapeju ọmọdekunrin rẹ naa bii ọmọ jẹjẹ.

O ni ọmọ oun ko mọ ibi pupọ l'America bo ṣe jẹ pe o ti pe ọdun kan lọ to de ọdọ oun niluu naa to.

Ọkunrin naa ṣalaye pe Javits ki I fẹẹ jade, o ni boun tiẹ ran an lọ sitosi paapaa, ki I fẹ lọ, nitori ko ni agbaja rara.

Baba naa sọ pe oun gbagbọ pe idunkooko mọ ọmọ oun nile ẹkọ rẹ le fa bi wọn ṣe pa a yii.

O ni:

"O lagbara o. Ibi ni mo wa pẹlu rẹ, o ṣẹṣẹ pe ọdun kan to kuro l'Africa ni. Ana (Ọjọru) lo pe ọdun kan to debi.

"Ki I sọrọ, ọmọ jẹjẹ ni, foonu rẹ lo maa n tẹ.

"Ọga ile ẹkọ wọn sọ fun mi nigba kan pe awọn ọmọkunrin meji kan maa n da ọmọ mi laamu, oun si ti ni ki wọn ma wa sile ẹkọ fun asiko kan nitori ẹ"

"Ọmọ mi paapaa ti sọ fun mi ri pe boun ba fẹ lọ jẹ ounjẹ ọsan, ọkan lara awọn ọmọkunrin naa maa n dunkooko mọ oun."

Bẹẹ ni Baba Javits wi.

Ijọba Ghana naa ti koro oju si iṣẹlẹ yii, lọjọ Ẹti ni Minisita ilẹ okeere fun Ghana, Samuel Okudzeto Ablakwa, sọ pe ijọba Ghana ti ba ẹbi Javits kẹdun.

O ni awọn yoo wa gbogbo ọna lati wadii iku ọmọde yii, awọn yoo si gba idajọ to yẹ fun un.

O fi kun un pe aabo awọn ọmọ Ghana jẹ ijọba ilu naa logun nibikibi ti wọn ba wa.

Ijọba Ghana rọ ti America lati ri I pe wọn wadii iṣẹlẹ yii finni finni.