Trump ṣàlàyé ìdí tí ẹgbẹ́ rẹ̀ Republican fi fìdírẹmi nínú ètò ìdìbò sáà kejì Amẹrika

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Aarẹ Donald Trump ti ṣalaye ohun to fa ijakulẹ ẹgbẹ oṣelu rẹ, Republican, ninu eto idibo saa keji to waye lorilẹede Amẹrika.

Trump ni ogun laarin Amẹrika ati Iran gan an lo jẹ ki ẹgbẹ oṣelu Republican fidirẹmi ninu eto idibo naa.

Ẹgbẹ oṣelu Republican ti kuro nipo ẹgbẹ oṣelu to ni aṣoju to pọ julọ nile igbimọ aṣofin agba ati ti aṣoju l'Amẹrika bayii.

Trump sọ ninu ifọrọwerọ ti o ṣe pẹlu Fox News pe ogun ti Amẹrika n ja ni Iran ti ṣokunfa bi epo ṣe gbowo lori lorilẹede Amẹrika.

O ni eyi n ṣakoba fun araalu tori wọn n ra epo ni owo gọbọi.

Trump ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe Amẹrika gbọdọ wa nnkan ṣe lori ọrọ Iran.

O ni Amẹrika ko ni gba ki Iran ko ado oloro jọ.

Ẹwẹ, Aarẹ Trump ti sọ pe oun ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu Democrats, lẹyin ti ẹgbẹ rẹ fidirẹmi ninu eto idibo to waye.

Trump sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu New York Times wi pe oun yoo faramọ esi idibo to jade.

‘’Lai ṣe ani ani, mo ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu Democrats,’’ Trump lo sọ bẹẹ.

Koko to yẹ kí o mọ nipa eto idibo saa keji Amẹrika

Lọdun keji lẹyin ijọba Aarẹ tuntun ni awọn eniyan America maa n dibo maa ṣe e lọ fawọn adari wọn eyi ti wọn n pe ni: 'midterm elections'.

Ninu eto idibo yii lawọn araalu yoo ti dibo yan awọn eeyan sipo aṣojuṣofin ati ipo awọn aṣofin eyi ti iṣẹ wọn jẹ ṣiṣe ofin,jijiroro lori ofin tuntun, bibuwọlu ofin ti yoo di amulo kaakiri America.

Esi eto idibo naa lo maa sọ ibi ti awọn ọmọ ilẹ naa yoo dojukọ ninu eto idibo Aarẹ ọdun 2028.

Egbe Oselu Democrat lo jawe olubori ninu eto idibo to pari yii.

Democrat jawe olubori ipo 54 nigba ti Republican ni ipo 44 ninu Senatọ.

Ninu ipo aṣojuṣofin, ẹgbẹ oselu Democrat lo ni ipo 226 nigba ti ẹgbẹ oṣelu Republican ni ipo 139.

Awọn eniyan Ipinlẹ marun un ọtọtọ lo dibo lori ẹto awọn ọkunrin ti wọn fi iṣẹ abẹ parada si obinrin atawọn obinrin ti wọn pa ara wọn da si ọkunrin.

Lawọn ipinle mii, ọrọ ẹtọ lori oyun ṣiṣẹ lo kan awọn, nigba ti ọrọ owo ori fun awọn olowo gọbọi kan awọn eeyan California.

Pelu ayọ ni awón ọmọ ẹgbe oṣelu Democrat n fihan bi wọn se gbegba oroke ti esi idibo wọn si ya ọpọ lẹnu.

Awọn ẹgbẹ oṣelu Republican ti Donald Trump padanu ọpọ awọn ipo miran ibo to ti jade.

Abajade esi idibo yii yoo fihan boya odun meji to ku fun Aarẹ Trump yoo rọ ọ lọrun tabi bẹẹ kọ ni pasẹ iye ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ to jawe olubori.

Democrat pọju ti Republican lọ nile aṣofin ti wọn dibo rẹ bayii yatọ si marundinlogoji ninu ipo ọgọrun un ti aṣofin agba naa.

Ọdun mẹfa ni senatọ n lo lori ipo ti wọn yoo ti jiroro lori awọn aba ti awọn aṣofin kekere ba gbe wa siwaju wọn.

Wo ibi ti ǹkan dé dúró nínú ìbò awọn ọmọ Amẹrika tí yóò sọ bí ìgbẹ̀yìn ìjọba Trump yóò ṣe rí

Awọn ọmọ ilẹ Amẹrika ti bẹrẹ eto idibo to maa n waye laarin saa ijọba, eyii ti wọn n pe ni 'midterm elections'.

Ninu eto idibo yii lawọn araalu yoo ti dibo yan awọn eeyan sipo aṣojuṣofin ati ipo awọn aṣofin.

Esi eto idibo naa lo ṣeeṣe ko sọ ibi ti awọn ọmọ ilẹ naa yoo dojukọ ninu eto idibo Aarẹ ọdun 2028.

Ipinlẹ marun un ọtọtọ ni yoo dibo lori ẹto awọn ọkunrin ti wọn fi iṣẹ abẹ parada si obinrin atawọn obinrin ti wọn pa ara wọn da si ọkunrin.

Lawọn ipinle mii, ọrọ ẹtọ lori oyun ṣiṣẹ lo kan awọn, nigba ti ọrọ owo ori fun awọn olowo gọbọi kan awọn eeyan California.

Fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrat, eyii yoo jẹ igba akọkọ ti wọn yoo maa dibo lẹyin ti wọn lulẹ ninu eto idibo gbogbogbo to waye lọdun 2024.

Fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican ẹwẹ, afojusun wọn ni lati jẹ ki awọn ti yoo wọ ile igbimọ aṣofin jẹ awọn ti yoo ṣe ti Aarẹ Trump.

Bo tilẹ jẹ pe awọn iroyin kan n fi han pe o ṣeeṣe ki ẹgbẹ oṣelu Democrat ṣaṣeyọri ninu eto idibo naa, o digba ti wọn ba ka esi ibo naa tan ki a to le fidi awọn to jawe olubori mulẹ.

Lara awọn agbegbe ti eto idibo naa ti kọkọ bẹrẹ ni Vermont, lẹyin naa lo bẹrẹ lawọn agbegbe mii bii New York, New Jersey, Virginia ati Maine.

Ṣaaju eto idibo naa ni Aarẹ Trump ti kọkọ juwe awọn oludije ninu ẹgbẹ oṣelu Democrat gẹgẹ bii awọn ti ipo ijọba ko tọ si.

O tun sọ pe asiko yii ni awọn araalu n pa owo to pọ julọ wọle ninu itan, lẹyin naa lo mẹnuba ọrọ irinajo awọn ọmọ ilẹ mii si Amẹrika ati ogun Iran.

Wayi o, awọn iwadii kan fidi rẹ mulẹ pe pupọ awọn ọmọ Amẹrika ni inu wọn ko dun si Trump, paapaa lori ọwọngogo to gbode ati ogun ti ilẹ naa ati Israel n gbe ti Iran.