Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Kò sí Ebola tuntun ní Naijiria, àyẹ̀wò fi hàn pé kò sí lára àwọn méjì tí a kéde l'Ariwa- NCDC
Ẹka ilera to n ri si ajakalẹ arun ati idena rẹ ni Naijiria NCDC, ti fidi ẹ mulẹ pe awọn meji ti wọn fura si pe won ni arun Ebola nipinlẹ lapa Ariwa orilẹede yii (Adamawa) ko ni arun naa.
Ajọ naa kede eyi loju opo X won.
NCDC sọ pe ayẹwo ẹẹmeji fi han pe awọn eeyan naa ko ni Ebola, to tumọ si pe ko si arun naa lorilẹede yii bayii.
Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni ajọ naa kede pe o ṣee ṣe ki eeyan meji mi-in ti lugbadi arun naa ni Ariwa-Ila-Oorun Naijiria, bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ ipinlẹ to jẹ pato.
Amọ ninu atẹjade ti ọga agba ajọ NCDC, Jide Idris, fi lede lalẹ ọjọ Satide, o ni ayẹwo ẹẹmeji fi han pe ayẹwo ti wọn ṣe fun awọn eeyan meji naa fi han pe wọn ko ni Ebola.
Wọn fi kun un pe ibi tawọn fura si tẹlẹ naa ni Yola, nipinlẹ Adamawa.
Ọgbọnjọ oṣu Kẹwaa yii ni wọn ni awọn eeyan meji fi apẹẹrẹ Ebola han.
Idris sọ pe ko si ayẹwo to fidi ẹ mulẹ bayii pe Ebola wa ni ipinlẹ Adamawa.
O ni akọkọ ti wọn ri l'Abuja tẹlẹ yẹn naa ni eyi ti akọsilẹ wa fun ni Naijiria di bayii.
NCDC rọ araalu lati fọkan balẹ, ki wọn si maa gbọ bo ṣe n lọ lati ẹka to fẹsẹ mulẹ.
Bi ẹnikẹni ba n ri apẹẹrẹ ailera bii iba, ori fifọ, ara riro, eebi, igbọnsẹ gbuuru tabi ki ẹjẹ maa jade lara lai nidii, paapaa bi ẹni naa ba ti ni ifinrakinra ju, ki wọn tete kan si ileewosan.
Wọn ni ki wọn fi to awọn eleto ilera leti, tabi ajọ to ba n ri si irinajo ti wọn rin laipẹ.
Bi o ṣe le dena arun Ebola
Lara awọn ọna lati dena arun Ebola gẹgẹ bii ajọ NCDC ṣe sọ ni fifọ ọwọ rẹ pẹlu omi ati ọṣẹ loorekoore, paapaa ti o ba gbọnsẹ tan.
Ṣọra fun omi ara ẹni to ni arun naa; lara omi ara bẹẹ ni itọ́, ìtọ̀, ẹjẹ ati igbọnsẹ wọn.
Da ara rẹ lẹkọọ nipa awọn apẹrẹ Ebola ki o le mọ bi o ṣe le tete yẹra fun.
Tẹlẹ imọran awọn eleto ilera ti o ba ni nnkan lati ṣe pẹlu ẹni to ni arun naa.
Ṣọra fun fifi ọwọ kan awọn ẹranko to ti ku bii adan.
Yẹra fun pinpin awọn nnkan ti omi ara ẹlomii n kan bii aṣọ, abẹrẹ atawọn nnkan mii.
Ma ṣe itọju ẹni to ni ebola funra rẹ lai kii ṣe onimọ eto ilera tabi lai ni imọ itọju alaarun naa ṣaaju.