Kò yẹ kí àwùjọ wa máa f'ojú ẹni yẹ̀yẹ́ wo obìnrin tí kò lọ́kọ, ó yẹ ká máa yìn wọn ni- Lola Idijẹ ẹ

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lawujọ wa lonii, onka awọn obinrin ti ko si nile ọkọ mọ amọ ti wọn ti bimọ ti wọn si n da bukata awọn ọmọ naa gbọ ti pọ.

Ọpọ igba lo si jẹ pe oju abuku ati ẹni yẹpẹrẹ ni awujọ fi maa n wo awọn obinrin bẹẹ.

Eyi ni agba oṣere tiata, Toyin Afolayan ti ọpọ eeyan mọ si Lola Idijẹ ẹ, da si laipẹ yii pẹlu alaye pe, ko tọna lati maa foju tẹmbẹlu obinrin ti ko si nile ọkọ, amọ ti wọn n tọ awọn ọmọ wọn funra wọn.

Idijẹ sọrọ naa lori eto kan, African A-List, pe:

"Pe obinrin ko lọkọ ko tumọ si pe ọ̀dẹ̀ ni tabi pe ko mọ ohun to n ṣe. Niṣe lo yẹ ka maa yin iru obinrin bẹẹ.

"Ọta lo fa a ti obinrin mi-in ko ṣe si nile ọkọ mọ, iṣoro mọlẹbi lo fa ti awọn ẹlomi-in.

"Ki i ṣe gbogbo obinrin to n da ọmọ tọ lo wu ki ọrọ wọn ri bẹẹ, ohun to ju wọn lo to ṣẹlẹ si wọn lo sọ wọn di iya to n da ọmọ tọ."

Agba oṣere naa tẹsiwaju, o ni o yẹ ki awujọ wa mọ, pe ki i ṣe gbogbo obinrin ni yoo tete lọkọ.

Idijẹ ẹ sọ pe awọn kan wa ti ko ni lọkọ bi won ko ba pe ogoji ọdun si aadọta. (40-50).

O ni aitete rọkọ fẹ naa ko tumọ si pe wọn ko mọ ohun ti wọn n ṣe, kadara lo n ṣiṣẹ tọ wọn bo ṣe sọ.

Bakan naa ni Idijẹ ẹ sọ pe gbogbo obinrin kọ ni yoo ni anfaani ọkọ gidi ti yoo maa ba wọn tọmọ bo ṣe yẹ ko ri.

Fun awọn ti wọn maa n da obinrin laamu pe ko lọ mu ọkọ wa lọjọ ori ti ko ti i ju ogun lọ (20), Idijẹ ẹ sọ pe ohun to maa n fa aṣiyan ọkọ nigba mi-in niyẹn.

"Ti ẹ ba n yọ wọn lẹnu pe ki wọn lọ mu ọkọ wa lọjọ ori ti ko ju ogun lọ, bawo le ṣe fẹ le fọwọ sọya pe wọn o ni i ṣiyan?" Bẹẹ ni agba oṣere naa beere.

'Sotayo Gaga ko ni igberaga, ẹni ti ko ba sun mọ ọn ko le mọ ọn"

Ninu ifọrọwerọ naa ni ọrọ ti kan oṣere tiata mi-in, Tayo Sobola tawọn eeyan mọ si SoGaga.

Nigba to n ṣalaye iru eeyan ti Sotayo jẹ, Lola Idije ẹ sọ pe eeyan daadaa, ọmọ Alubarika to ni iwa jẹjẹ ni.

O ni bi Sotayo ṣe maa n da wa lawọn eeyan mi-in fi ro pe onigberaga ni.

Idijẹ ẹ sọ pe isunmọni la a mọṣe ẹni. O ni ẹni to ba sunmọ Sotayo yoo mọ pe eeyan ni.

Gẹgẹ bo ṣe wi:

"Ọmọ daadaa ni Sotayo,bawọn eeyan ko ba sun mọ ọn, wọn a ro pe o buru ni.

Sotayo fẹran ko maa da wa, ki i ṣe ti igberaga."

Lola Idijẹ ẹ fi kun pe oun naa ni iru iwa bẹẹ lọwọ, o ni lasiko toun ba wa loko ere loun maa n ba awọn eeyan ṣere, aaye awada ko fi bẹẹ yọ lai si idi kan bo ṣe sọ.