Àlàyé lórí ohun tó ń mú èèyàn ṣàdédé ṣubú lulẹ̀ kú láì ṣàìsàn àti ọ̀nà àbáyọ

    • Author, Olumide Owaduge
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ eleto ilera agbaye, WHO ti fidi rẹ mulẹ pe eeyan bii ọgọta miliọnu lo n ku kaakiri agbaye lọdọdun.

Eyii n tumọ si pe nnkan bii eeyan meji lo n ku laarin iṣẹju aaya kan lagbaye.

Ninu awọn eeyan wọnyii, WHO sọ pe ohun to n ṣokunfa pupọ ninu awọn iku naa ni aisan ti ko le ran ẹlomiran eyii to ko ida 74% ninu awọn iku ọhun.

Lara awọn aisan naa ni awọn aisan ọkan ati rọparọsẹ, to fi mọ aisan jẹjẹrẹ.

Wayi o, lọpọ igba lawọn eeyan maa n ṣadede ṣubu lulẹ, ti wọn a si gba ibẹ jẹ ipe Eledua.

Fun awọn eeyan naa ati mọlẹbi wọn, wọn le ro pe wọn gbadun amọ ti aisan adakẹpani bii ẹjẹ riru tabi aisan ọkan ti wa lara wọn tẹlẹ

Awọn oniṣegun ati onimọ ijinlẹ ti fidi rẹ mulẹ pe o ṣeeṣe ki eeyan ni awọn aisan adakẹpani lara amọ ki irufẹ aisan bẹẹ ma farahan titi to maa fi gbẹmi ẹni bẹẹ.

Ki lo maa n mu ki eeyan dede ṣubu lulẹ ko si gba ibẹ lọ?

Lẹnu lọlọ yii lọpọ awọn gbajumọ kan ni Naijiiria bẹrẹ si n ku ti a si maa n gbọ pe iku naa waye lẹyin ti irufẹ ẹni bẹẹ ṣadede ṣubu lulẹ, yala ninu ile ni tabi ni ita gbangba.

BBC Yoruna kan si oniṣegun kan, Babalola Festus Rotimi, to jẹ dokita nile iwosan ijọba apapọ, FMC, to wa niluu Owo, nipinlẹ Ondo, lati tan imọlẹ si ọrọ naa.

Babalola sọ pe irufẹ awọn aisan to n gbẹmi eeyan bẹẹ kii sẹ nnkan ti eeyan maa n foju si, koda, o ni irufẹ awọn aisan naa kii fi apẹrẹ han paapaa.

Amọ nipa ti awọn apẹrẹ ti eeyan le ri o ni "Ẹlomii le sọ pe aya kan n dun oun lasan, pupọ awọn to maa n ṣẹlẹ si wa ninu awọn ti kii ṣe ayẹwo ara wọn loorekore.

"Fun awọn mii, wọn maa n ṣe ayẹwo ara wọn amọ to jẹ pe wọn kii lo oogun wọn bo ṣe yẹ ki wọn lo o.

"Ẹlomiran a sọ pe aya n dun oun, paapaa aya ni apa osi, igba mii ẹlomiran a sọ pe aya oun kan bẹrẹ si n ṣe pi pi pi pi ni.

"Igba mii ẹlomiran a sọ pe ori kan bẹrẹ si n fọ oun lojiji, amọ eyii to pọ ju ni ti aya yẹn."

"Eeyan le ku laarin iṣeju kan si wakati kan pere"

Gẹgẹ bi Babalola ṣe sọ, irufẹ aisan ti eeyan ko ka si bayii le gbẹmi eeyan laarin iṣẹju kan pere.

Fun awọn mii ti wọn ri aanu gba, o ni ṣeeṣe ko to ọjọ kan ki wọn to papoda amọ gẹgẹ bo sọ, laarin iṣeju kan si wakati kan, o pọ ju, si ọjọ kan lo maa n pa eeyan.

Dokita naa ṣalaye oniruru nnkan lo le ṣẹlẹ ninu ago ara eeyan laarin wakati kan ti iku ojiji ba de.

"CPR le gbẹmi eeyan la ko to pẹ ju"

Dokita Babalola sọ pe ti eeyan ba ṣadede ṣubu lojiji, o ṣeeṣe lati gba ẹmi irufẹ ẹni bẹẹ la ti wọn ba le ṣe nnkan ti wọn n pe ni CPR fun irufẹ ẹni bẹẹ

CPR yii jẹ ọna lati mu ki ẹjẹ ati afẹfẹ oxygen pada sinu agọ ara ẹbi bẹẹ, paapaa inu ọpọlọ rẹ ko to pẹ ju.

O fidi rẹ mulẹ pe o tọ lati ni idanilẹkọ nipa bi wọn ṣe n ṣe CPR ki eeyan to dawọle, amọ CPR naa le wulo ki irufẹ ẹni to ṣubu lulẹ naa to dele iwosan.

Ki ni ọna abayọ si irufẹ iku ojiji bayii?

Lọna ati dena ṣiṣubu lulẹ fun iku ojiji, Babalola gba awọn eeyan nimọran ki wọn maa ṣayẹwo ara loorekoore.

O ni "Idi niyi ti a fi maa n sọ fun awọn eeyan ki wọn maa ṣayẹwo ara wọn loorekoore.

"Eeyan ko gbọdọ duro de asiko ti aisan ba ki i mọlẹ ko to lọ ṣayẹwo ara rẹ nile iwosan"

Oniruru ayẹwo ara ni eeyan le ṣe nile iwosan, amọ Babalola sọ pe lara awọn ayẹwo to ṣe pataki julọ ni ayẹwo ẹje ati ṣuga ninu ara.

Ninu ọrọ rẹ, o ni "O yẹ ki eeyan maa ṣayẹwo ẹjẹ riru ati ayẹwo itọ ṣuga ara looreloore."

Nipa iye igba ti eeyan gbọdọ ṣe awọn ayẹwo yii, dokita ọhun sọ pe o kere tan, ayẹwo naa yẹ ko maa waye nigba kan si igba meji laarin ọdun, yala irufẹ ẹni bẹẹ gbadun tabi bẹẹ kọ.