Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Ìlérí ìpèsè iná ọba déédé tí Tinubu ṣe ní 2023 tí wọ́n fi ń takò ó báyìí, ki ni Ààrẹ sọ nígbà náa gan-an?
Lọwọlọwọ yii, awọn alatako n gbena woju Aarẹ Bola Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu APC, nitori ileri ipese ina ọba fun araalu ti wọn ni Aarẹ ṣe nigba to n polongo ibo ni 2023.
Ileri naa ni wọn ni Tinubu ko muṣẹ titi dasiko yii, to jẹ ina ọba n buru si I ni.
Ẹsun ti wọn fi n kan Aarẹ Tinubu
Awọn eeyan bii Atiku Abubakar, Peter Obi, Seyi Makinde ati bẹẹ bẹẹ lọ to n tako Tinubu n sọ pe Aarẹ ṣeleri lati pese ina ọba fawọn ọmọ Naijiria bi wọn ba dibo fun un nigba naa, ti ina ọhun ko ni I ṣẹju.
Wọn ni Tinubu sọ ọ nita gbangba, akọsilẹ si tun wa fun un pẹlu, bẹẹ ni fidio rẹ tun wa, pe boun ko ba pese ina ọba naa ni saa akọkọ, kawọn eeyan ma dibo foun ni saa keji mọ.
Amọ ileri naa ko wa si imuṣẹ ni ẹsun ti wọn fi n kan Tinubu bayii, wọn ni kaka ko pese ina to ṣeleri, niṣe ni ina ọhun n buru si i.
Ẹsun mi-in ti wọn ka si Aarẹ lẹsẹ ni pe o loun yoo fopin si ki araalu maa sanwo ina nilana iṣiro mita aṣonka (Estimated billing).
Pe iye ina ti araalu ba lo nikan ni wọn yoo maa sanwo rẹ pẹlu onka boun ba di Aarẹ.
Tinubu ko tun ṣe eyi naa ni ẹsun mi-in ti awọn alatako fi n kan an, o si pẹlu ohun ti wọn fi n tako ipinnu rẹ lati tun fẹ lọ fun saa keji bayii.
Ki ni Tinubu sọ nigba naa gan-an?
Ninu fidio kan ti Tinubu ti sọ ọrọ to pada di awuyewuye yii lọdun naa, Tinubu sọ pe:
"Ni ọna yowu ko jẹ, gbogbo ọgbọ́n, ẹ gbọdọ ni ina ẹlẹtiriki, ẹ o si ni i sanwọ ina oni-biili ti wọn n ṣe onka rẹ mọ. (Estimated billings).
"Ileri ti eeyan ba ṣe, o gbọdọ mu un ṣẹ, ti mo ba yẹ adehun naa ti mo si wa pada wa pe ki ẹ dibo fun mi ni saa keji, ẹ ma dibo fun mi mọ, otitọ ibẹ niyẹn.
"Afi ti mo ba fun yin ni idi gboogi ti mi o fi le ṣe ohun ti mo sọ."
Bẹẹ ni Aarẹ Tinubu sọ ninu fidio ọhun.
Ọrọ naa lo di ohun ti wọn fi n tako o bayii.
Wọn ni ko yẹ ki Tinubu tilẹ loun yoo tun dupo aarẹ Naijiria mọ, nigba ti ko mu adehun ina ọba atawọn nnkan mi-in to ṣe lakọkọ ṣẹ.