Wo bí wọ́n ṣe gún àwọn ọmọdé márùn-ún níbi ayẹyẹ Halloween

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa Hampshire ti sọ pe ko din ni ọmọde marun-un ti awọn afurasi kan gun lọbẹ lasiko ti wọn n ṣe ayẹyẹ Halloween lọwọ.

Nnkan bi gogo mẹwaa aabọ alẹ ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, ọsẹ to kọja yii ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Agbegbe ti wọn pe ni Part Road to wa ni Chandler's Ford, nitosi Eastleigh ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Awọn ọmọ tọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹrindinlogun si mẹtadinlogun lọ, ni awọn amookunṣeka naa gun lọbẹ, ko to di pe wọn na papa bora.

Bo tilẹ jẹ pe niṣe lọrọ di boo lọ o yago lọna nigba ti awọn afurasi naa bẹrẹ sii ṣiṣẹ buruku wọn, ṣugbọn nigba ti wọn lọ tan, awọn to wa nibẹ sare gbe wọn lọ sile iwosan fun itọju.

Ileeṣẹ Hampshire sọ pe, igbagbọ awọn ni wi pe awọn afurasi naa wọ inu ọgba ti awọn ọmọ naa ti n ṣayẹyẹ wọn lati adugbo Park Road, ko to di pe wọn bẹrẹ iṣẹ buruku wọn.

Awọn agbofinro ti wa rọ awọn eeyan to ba ni iroyin tabi ohunkohun nipa awọn afurasi naa, ki wọn tete wa fi to wọn leti, lati le rọwọ to wọn.

Titi di ọjọ Aiku to kọja yii, ni awọn agbofinro fi n ṣe iwadii, pẹlu bi wọn ṣe di oju ọna pa.

Ọkan lara awọn agba oniṣẹ iwadii nileeṣẹ ọlọpaa, Elizabeth Pirie gbe oṣuba kare fawọn olugbe agbegbe naa lori ipa ti wọn ko, to si dupẹ lọwọ wọn fun suuru ti wọn ni.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ba BBC sọrọ, to si jẹ ko di mimọ pe awọn oluranlọwọ iṣẹlẹ pajawiri ti wa sibẹ.

Ẹlomiran ti iṣẹlẹ ọhun tun ṣoju rẹ sọ pe awọn ri ẹnikan to n sare jade lati inu ile ti ikọlu naa ti ṣẹlẹ, to si n pariwo wi pe wọn ti gun oun, ati pe awọn meji kan n le oun lẹyin.

Ọlọpaa wa jẹ ko di mimọ pe awọn mọ bi iṣẹlẹ naa ṣe lara awọn olugbe agbegbe ọhun.

Ninu atẹjade to wa lori ikanni 'X' lọjọ Aiku, Eastleigh MP Liz Jarvis sọ pe: "Ero mi wa lara awọn to fara kaaṣa ati mọlẹbi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ni Chandler's Ford lalẹ ana, ati pe mo fẹẹ fi idupẹ mi fun awọn ọlọpaa, lori bi wọn ṣe tete dide si iṣẹlẹ naa.

"O ṣe pataki lati ma ṣe sọ ahesọ tabi gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri."