Àlàyé rèé lórí bí Nkechi Blessing ati ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àtijọ́, Opeyemi Falegan ṣe parí ìjà; àmọ́ ṣé ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tún padà sáàrin wọn bí?

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Yoruba ni arẹmaja kan ko si, ajamarẹ ni ko sunwọn, bẹẹ si ni ọrọ ọkọ ati iyawo, oju Oluwa nikan lo le to.

Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ eeyan nigba ti wọn gbọ pe gbajumọ osere tiata lobinrin, Nkechi Blessing ati ọrẹkunrin rẹ atijọ, Opeyemi Falegan, ti pada tọrọ aforijin lọwọ ara wọn.

Bi ẹ ko ba gbagbe, losu kẹrin ọdun 2022, aarin awọn mejeeji lo daru, ti ọrọ ifẹ wọn si daru gidi, koda, wọn ko ara wọn wa sori ayelujara, ti wọn si n sọ oko ọrọ sira wọn.

Aawọ awọn mejeeji le to bẹẹ gẹ debi pe ọpọ eeyan lo da si nigba naa, ti awọn mejeeji si n sọ ọrọ kobakungbe sira wọn.

Amọ lẹyin ọdun mẹrin ti wọn ti kọju oro sira wọn, ti egbé ti regbé, tí egbè sì ti regbè, bawo ni wọn tun se pade pada, ti wọn fi gbagbe ọrọ ana.

Bawo ni ija se pari laarin Nkechi ati Falegan?

Fidio kan lo gba ori ayelujara kan ni ijẹta Ọjọ Aiku, nipa Opeyemi Falegan, to jẹ gbajumọ oloselu ati oludije sipo gomina tẹlẹ fun ẹgbẹ oselu Accord nipinlẹ Ekiti.

Ninu fidio naa to wa loju opo TikTok ni Falegan ati Nkechi ti foju han, ti obinrin osere tiata naa si n sọ fun oloselu naa pe ko tọrọ aforijin lori awọn ọrọ kobakungbe to ti sọ fun oun saaju.

O ni bi itọrọaforijin naa ko ba waye, aawọ to wa laarin awn mejjeji ko le yanju.

O fikun pe ọrọ ti Falegan sọ si oun naa lori ayelujara, ninu eyi to ti fẹsun kan Nkechi pe o n fẹ oun nitori owo to wa lọwọ oun ati ibalopọ, lo sokunfa bi ija se waye laarin awọn.

Agba osere naa ni se ni awọn eeyan si n lo eebu naa lori ayelujara, bẹẹ si ni oun maa n duro lati daabo bo Falegan bawọn eeyan ba n bu bi o tilẹ jẹ pe aarin awn ko gun.

O fikun pe lọpọ igba ni oun ti maa n sọrọ lati gbe Falegan lẹyin lasiko ti wọn ba n naka abuku si lori ayelujara lori iwa to ba hu.

Koda, o salaye pe lasiko ti wọn n fẹsun kan Felgan pe o gba awọn, Nkechi ni oun ni oun n salaye fawọn eeyan pe kii se Opeyemi Falegan lo gba wọn.

Nkechi sọ fun oloselu naa pe" Ni osu keji ọdun yii, tori nnkan to sọ si mi lọdun mẹrin sẹyin, awọn eebu ti ko tọna, ni awọn kan n lo lati sọrọ abuku si mi lanaa.

Eyi n foju han pe gbogbo ohun to ba ti bọ sori ayelujara, ko le di ohun igbagbe laelae, amọ n ko le dari jin ọ lai jẹ pe o tọrọ aforijin."

Opeyemi Falegan tọrọ aforijin lọwọ Nkechi Blessing lẹyin o rẹyin

Ninu fidio ti Falegan ti foju han loju opo TikTok naa lati gbọ gbogbo ẹhonu Nkechi, lo ti wa tọrọ aforijin lọwọ rẹ.

Falegan wa kede pe oun kabamọ lori aawọ to waye laarin awọn mejeeji, to si fọwọ gbaya fun osere tiata naa pe oun ti n dagba si, ti ayipada si ti ba aye oun lati ọdun mẹrin sẹyin.

Agba oselu naa wa rọ osere tiata naa pe ko jẹ kawọn gbagbe ọrọ ana nitori ti a ko ba gbagbe ọrọ ana, a ko le ri ẹni ba sere.

O ni ẹni kọọkan awọn lo ni ero ọtọọtọ nipa isẹlẹ to waye naa, to si parọwa pe yoo dara ki awọn jẹ ki isẹlẹ naa lọ sokun igbagbe, kawọn si tẹsiwaju ninu igbe aye awọn.

"Lati inu ọkan mi, mo bẹ ọ, Nkechi, ma binu. Isẹlẹ naa ti kọja lọ, mo si ri pe iwọ naa ti dagba si, o tun ti gbọn si.

Ko yẹ ki ọkunrin maa gba ọrọ bii ẹni gba igba ọti pẹlu awọn obinrin.

Ohun ti mo si fẹ ki o mọ ni pe iru eeyan ti mo jẹ lanaa kọ ni mo jẹ lonii."

Nibayii ti ija ti pari, se Falegan ati Nkechi yoo bẹrẹ ifẹ wọn pada?

Bi Falegan ati Nkechi se pari ija aarin wọn yii lo jẹ iduunu awọn ololufẹ wọn, ti wọn si n fi ero wọn han pe o seese kawọn mejeeji bẹrẹ ere ifẹ wọn pada.

Amọ se bẹẹ ni ọrọ yoo ri bi?

Ohun to ya ni lẹnu ni pe Falegan ati Nkechi ti sọrọ loju opo Instagram ikọọkan wọn pe lootọ lawọn pari ija amọ ko tii si pe ọrọ ifẹ pada saarin awọn.

Gẹgẹ bi Nkechi se sọ loju opo Instagram rẹ, o ni oun ko ni lero lati bẹrẹ ere ifẹ pada pẹlu Opeyemi Falegan.

O salaye pe tori pe awọn pari ija ko tumọ si pe awọn ti n fẹ ara awọn pada amọ tori pe amọ tọrọ aforijin lori ọrọ kobakungbe atẹyinwa, kii se pe awọn tun fẹ maa fẹra pada.

Nkechi ni oun gbe igbesẹ alaafia ati aforijin amọ eyi ko sọ pe ki oun tun pada maa se ohunkohun ti ko mu agbega ba igbe aye oun.

" Mo ti ri daju pe didagba kii se kii eeeyan ni ilọsiwaju nikan amọ o tun nilo ki eeyan gba alaafia laaye nipa awọn isẹlẹ to ti wo ọ palẹ nigba kan ri.

Ni ọdun mẹrin sẹyin, ọpọlọpọ nnkan ni wọn sọ lori ayelujara, ọpọ isẹlẹ lo waye, ọpọ ero inu la fi han.

Amọ ọdun mẹrin ti pẹ ju lati maa gbe ohun to dun eeyan sọkan boya ẹhonu ni tabi ibinu."

Nkechi Blessing tun tẹsiwaju petitọrọ aforijin kii se kikede ibẹrẹ ajọsepọ tuntun, sisunmọ ara ẹni ko tumọ si pe ere ifẹ miran fẹ bẹrẹ.

Bakan naa lo ni ta ba gba ki ẹdun ọkan lọ sokun igbagbe ko sọ pe a tun n silẹkun miran silẹ fawọn ohun ti iriri ti kọ ni lati ti pa.

Gbajumọ osere tiata naa ni o dara ki eeyan tilẹkun mọ awọn ajọsepọ kan patapata tori bi eeyan ba ba eeyan kan sọrọ, ko sọ pe ki eeyan tun gba wọn pada sinu aye ẹni.

"Eyi kii se ikorira, idagbasoke ni. Kii se ẹjẹ buburu, ko si irora ọkan ninu rẹ, n ko pada sẹyin mọ. Mo ti dari jin, mo ti wosan ninu ọgbẹ ọkan, mo si ti tẹsiwaju.

Ero iranti rẹ lo yẹ kawọn eeyan kan wa, kii se ninu ọjọ iwaju rẹ, eleyi naa si dara."

Ki ni Opeyemi Falegan sọ?

Ninu ọrọ to sọ loju opo Facebook rẹ nipa isẹlẹ naa, Opeyemi Falegan ni oun ati Nkechi Blessing yatọ si iru eeyan tawọn dijọ jẹ lasiko ti isẹlẹ naa sẹlẹ.

O fikun pe aigbọraẹniye ati akoko to le jẹ ara ohun ti ẹda ko le se lai la kọja.

Amọijiroro tootọ, gbigbọ ara ẹni ye ati agbara lati gbagbe awọn isẹlẹ atẹyinwa le e seranwọ lati mu ki alaafia pada.

"Fun gbogbo eeyan to n tẹle wa ninu irinajo wa, to fi itara wọn han, to gbe imọran kalẹ, to si gbadura fun wa tabi se atilẹyin lasiko iyapa wa.

A fẹ se alabapin nnkan lati inu ọkan wa.

Inu wa dun lati sọ fun yin pe a ti pari ija wa, ti a si wa loju opo to dara bayii.

A ti pinnu lati gbagbe awn isẹlẹ to waye lati ẹyin wa, a si gba igbọraẹniye laaye, a si n tẹsiwaju pẹlu aanu ati ibọwọfunraẹni."

Bakan naa ni Falegan wa rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn to ti duro sẹyin ikọọkan wọn tẹlẹ, tabi fi ero wọn han sẹyin nipa awọ naa, pe ki wọn gbagbe ọrọ naa.

'"A mọ riri ifẹ ati ilakaka yin, amọ a bẹ yin pe ki ẹ jẹ ki isẹlẹ naa lọ sokun igbagbe.

Ko si idi fun ariyanjiyan kankan lori eleyi, inaka aleebu sira ẹni tabi sisọ ọrọ odi sira ẹni.

Ko si ẹni to pe, a si mọ pe agbara wa ninu idarijin, digba soke ninu igbọraẹniye ati bo se rẹwa lati yan alaafia laayo."

Falegan fikun pe awọn ko ni ikunsinu si ẹnikẹni, ti ireti si wa pe ẹni to ba nifẹ awọn yoo fara mọ ki onikaluku awọn tẹsiwaju pẹlu igbe aye awọn.

Ki lo fa ija laarin Falegan ati Nkechi lọdun 2022?

Ibẹrẹ oṣu Kẹrin ọdun 2022 ni ipinya waye laarin awọn mejeeji to ti fi igba kan jẹ ololufẹ.

Lasiko naa, niṣe ni wọn n gba eebu, epe ati titu aṣiri ara ẹni sita bi ẹni gba igba ẹmu, loti ayelujara.

Eyi waye fun bi ọsẹ kan si meji gbako.

Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba ti Ọgbẹni Falegan tọrọ aforiji lọwọ Nkechi ni ọjọ diẹ sẹyin.

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lori ayelujara pẹlu gbajumọ agbohunsafẹfẹ, Ifedayo Olarinde, Daddy Freez lọjọ Iṣẹgun lo ti ṣe eyi.

Ṣaaju ki wọn o to tuka, ọkọ ati iyawo ni Nkechi ati Opeyemi ma n pe ara wọn.

Bakan naa ni Nkechi ma n wọ oruka igbeyawo, eyi to mu ọpọlọpọ eeyan gbagbọ pe wọn ti ṣe igbeyawo.

Yatọ si eyi, ọpọ igba ni wọn jọ ya fọto ninu aṣọ anko.

Amọ nigba to n sọrọ, Opeyemi sọ pe ootọ ni awọn nifẹ ara wọn.

O ni to ba jẹ pe eeyan radarada ni oun ko ni i ma fi oun han araye, bẹẹ ni oun paapaa ko ni maa pe ni iyawo oun.

"Ko si igbeyawo kankan ni aarin wa, sugbọn ifẹ wa.

Bo tilẹ jẹ pe Falegan gbe oriyin fun Nkechi ṣaaju, iyalẹnu lo jẹ nigba to tun fi fidio mii sita lati tabuku rẹ.

O ni oun tọrọ aforijin lọwọ Nkechi ki awọn le gbagbe ọrọ ana, kii ṣe nitori ki awọn le di ololufẹ pada.

Falegan sọ pe idi ti oun fi fi Nkechi silẹ ni pe o ni ọbun, kii fọ pata tabi fọ eyin rẹ lai jẹ pe oun sọ fun.

"Emi ni ma a sọ fun obinrin pe ko paarọ pata lẹyin ọjọ kẹta, ran leti pe ko fọyin ni owurọ.

"Mi o le faramọ iru nkan bẹẹ."

Ohun to yẹ ki o mọ nipa oṣerebinrin, Nkechi Blessing

Nkechi Blessing Sunday ni apeja orukọ rẹ.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 1989 ni wọn bi si agbegbe Surulere nipinlẹ Eko.

Bo tilẹ jẹ pe ọmọ bibi ẹya Igbo ni lati ipinlẹ Abia, oṣere Yoruba ni.

Ọdun 2008 lo kopa fun igba akọkọ ninu fiimu kan, Omo Bewaji.

O si ti kopa ninu fiimu to le ni ọgbọn lati igba naa.