Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Wo bí o ṣe lè mọ̀ bó yá o wà lára àwọn ọmọ Naijiria tí yóò jẹ ànfààní ₦50,000 tí ìjọba Tinubu ń pín fáwọn mẹ̀kúnnù
Ijọba apapọ ti bẹrẹ pinpin N50,000 fawọn mẹkunnu lorilẹede Naijiria gẹgẹ bi owo iranwọ latari bi ebi ati iṣẹ ti n ba ọpọ eeyan finra.
Oniruuru ọna ni ijọba n gba lati pin owo naa fawọn ti ko rọwọ họri lawujọ pẹlu bi ounjẹ ṣe wọn gogo ti epo bẹntiroolu si n gbowo lori loorekoore.
Lara awọn banki ori ayelujara ti ijọba n lo lati pin owo naa fawọn eeyan ni Opay wa.
Ẹwẹ, OPay ti wa kilọ fawọn ọmọ Naijiria wi pe ki wọn ṣọra ki wọn ma baa ko sọwọ awọn to le lu wọn ni jibiti lori ọrọ owo N50,000 ti ijọba n pin fawọn mẹkunnu.
Bi o ṣe le mọ pe o wa lara awọn ti yoo janfaani N50,000 ti ijọba n pin fawọn mẹkunnu ree
Ileeṣẹ ifowopamọ Opay ṣalaye loju opo X rẹ pe awọn to ni awọn amuyẹ kan nikan ni o le ri owo yii gba.
Ati pe ileeṣẹ banki Opay kọ lo n mu awọn eeyan ti ijọba n sanwo yii fun un lori aapu Opay.
Opay ṣalaye loju opo X rẹ wi ẹnikẹni ti ijọba ba fẹ fun lowo naa yoo ri atẹjiṣẹ kan gba lori aapu Opay rẹ.
Lati ibi atẹjiṣẹ yii ni iru ẹni bẹẹ yoo ti mọ igbesẹ to ba kan fun oun lati gbe ki o le ri N50,000 naa gba.
Ileeṣẹ ifowopamọ yii wa rọ awọn onibaara wọn pe ẹnikẹni ti ko ba ti ri atẹjiṣẹ yii lori aapu Opay rẹ ko si lara awọn ti owo iranwọ naa wa fun niyẹn.
Opay tun fidi rẹ mulẹ pe ileeṣẹ awọn kọ n lo mu awọn eeyan to n gba owo naa.
Opay wa rọ awọn eeyan lati kan si ajọ National Emergency Relief and Stabilisation Intervention, NERSI, to n ṣakoso eto naa lori nọmba foonu wọn yii – 07000222222 fun ẹkunrẹrẹ.
Ileeṣẹ Opay ko ṣai rọ awọn onibaara rẹ wi pe ki wọn ṣọra fawọn onijibiti tori Opay ko ni beere fun ''pin'' tabi ''password'' ẹnikan lati san owo iranwọ naa fun wọn.
Bakan naa ni ileeṣẹ ifowopamọ ọhun tun kilọ fawọn onibaara wọn wi pe wọn o gbọdọ sanwo kankan fun ẹnikẹni to ba n pe ara rẹ ni aṣoju tori ko si nnkan to n jẹ bẹẹ.
Opay tun rọ awọn eeyan wi pe ki wọn lo aapu wọn tabi nọmba USSD *955*20# lati le mọ bo ya wọn wa lara awọn ti yoo jẹ anfaani owo iranwọ naa.
''Ẹ ṣọra fawọn onijibiti, ẹ ko nilo aṣoju kankan lati gba N50,000 ti ijọba n pin''
Laipẹ yii ni ijọba apapọ kede pinpin N50,000 fawọn ọmọ Naijiria ti ko rọwọ họri labẹ ajọ NERSI to n ṣakoso eto naa.
Minisita to n ri si ṣiṣe aanu fawọn eeyan ati mimu adinku ba oṣi ati iṣẹ, Ọmọwe Bernard Doro, lo fidi ọrọ yii mulẹ lọgbọnjọ oṣu Kẹwaa to kọja.
Ọmọwe Doro sọ pe awọn mẹkunnu yoo maa gba N50,000 loṣooṣu bayii lati le ṣeranwọ fun wọn.
Amọ, o ni ijọba yoo ṣe agbeyẹwo eto naa ti o ba ya.
Minisita ṣalaye pe ijọba n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn banki ori ayelujara kan lati le pin owo naa fun araalu.
Awọn ti yoo jẹ anfaani owo yii yoo kọkọ gba atẹjiṣẹ lati beere iyọnda lati ọdọ wọn ki wọn to sanwo ọhun si akaunti wọn.
Awọn banki ori ayelujara ati USSD nọmba wọn ti ijọba n lo lati pin owo naa ni ALAT by Wema (*945*23#), MoMo PSB (*671*0#), NairaGram (*726*00#), OPay (*955*20#) ati Moniepoint (*557*327#).
Minista fikun ọrọ rẹ pe ẹnikẹni ko nilo aṣoju lati gba owo yii, o wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati kan si ajọ NERSI ti wọn ba ni ibeere lori ohunkohun nipa eto naa.