Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Kóòtù gba ẹ̀rí ìjọba wọlé, tako ẹ̀bẹ̀ ológun mẹ́fa tí wọ́n ní wọ́n fẹ́ gbàjọba mọ́ Tinubu lọ́wọ́
Ile ẹjọ giga ilu Abuja ti tako ẹbẹ awọn ologun mẹfa ti wọn fẹsun kan pe wọn gbiyanju lati fipa gbajọba mọ Aarẹ Bola Tinubu lọwọ.
Ọjọbọ, ọjọ karun-un oṣu Kọkanla ọdun 2026 ni kootu kọ ẹbẹ naa.
Adajọ Joyce Abdulmalik, kọ alaye tawọn eeyan naa ṣe pe awọn ologun fipa mu awọn jẹwọ ẹṣẹ ninu fidio ti won ti gba ohùn ẹnu awọn kalẹ lori ẹsun naa ni.
Adajọ sọ pe ko si ẹri to fi eyi han.
Alaye kootu
Ninu ọrọ Adajọ Abdumalik, o ni ẹri ijọba fi han pe awọn olujẹjo naa lo funra wọn sọrọ to wa ninu fidio ọhun nigba ti wọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo, funra wọn ni wọn si farahan ninu fidio naa.
Adajọ sọ pe lẹyin igbẹjọ ninu igbẹjọ toun ṣe lati mọ boya wọn fipa mu wọn ni, oun ri i pe ko si ẹri kankan to fi han pe ẹnikẹni fipa mu wọn sọrọ.
O ṣapejuwe ọrọ awọn olujẹjọ bii ti atẹyin-kọgbọn-aja, ati eyi ti ko ṣee gbagbọ.
Adajọ Abdumalik loun ko gba pe awọn ologun fiya jẹ awọn eeyan naa tabi fipa mu wọn lati jẹwọ ninu fidio ọhun.
Bayii lo ni ọrọ ẹnu wọn ati fidio naa ti di ẹri to tako wọn, ti kootu yoo si mu lo bii ẹri gidi.
Awọn wo ni olujẹjọ mẹfa naa, ki ni wọn si sọ ninu fidio?
Awọn olujẹjọ mẹfa naa ni:
Ọgagun Mohammed Gana, Ajagunfẹyinti Erasmus Victor, Inspector Ahmed Ibrahim, Zekeri Umoru, Bukar Goni ati Abdulkadir Sani.
Lara ẹsun ti wọn fi kan wọn logunjọ oṣu Kẹrin,ti Rotimi Oyedepo (SAN) to ṣoju ijọba fun ẹka idajọ gbe kalẹ ni:
Iditẹmọ ijọba, igbesunmọmi, kikuna lati sọ ọna aabo,kikowo jọ lọna aitọ ati fifi owo naa ran igbesunmọmi lọwọ.
Wọn foju wọn ba kootu lọjọ kejilelogun oṣu Kẹrin lori ẹsun mẹtala.
Ọjọ kọkanla oṣu Karun-un ni wọn ṣe igbẹjọ onigunmeji (Trial-within-trial), lẹyin ti agbẹjọro awọn olujẹjọ kọ lati gba ẹri to wa ninu fidio ti ijọba fẹ gbe wa si kootu wọle.
Agbẹjọro awọn olujẹjọ sọ pe awọn eeyan oun ko sọrọ naa pẹlu ifẹ inu, bi ko ṣe pe wọn fipa mu wọn jẹwọ.
Igbẹjọ n tẹsiwaju, pẹlu bi Adajọ Joyce Abdulmalik ṣe sun un si ọjọ keje ati ikẹwaa oṣu Kejila ọdun 2026.
Ki lo ṣẹlẹ ṣiwaju
Iroyin nipa igbiyanju lati ditẹ gbajọba mọ Aarẹ Tinubu lọwọ jade loṣu Kẹsan-an ọdun 2025.
Nigba naa ni ileeṣẹ ologun kede pe oun ti mu awọn ṣọja kan ti wọn pọ niye, ti awọn mi jẹ ajagunfẹyinti, awọn mi-in si wa lẹnu iṣẹ ninu wọn.
Koda, wọn fi kun un nigba naa pe awọn ti ki I ṣe ṣọja naa wa ninu wọn pẹlu, wọn ni wọn lọwọ si igbiyanju iditẹgbajọba naa.
Lẹyin eyi ni iwadii bẹrẹ, awọn ṣọja si pada fawọn le ẹka to yẹ lọwọ fun idajọ.