Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC tako ìdájọ́ tó yọ Atiku gẹ́gẹ́ bíi olùdíje sípò Ààrẹ, ó ní APC fẹ́ dáná sun Naijiria

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) ti bu nu atẹ lu idajọ to wọgile igun David Mark to n ṣakoso ẹgbẹ oṣelu ADC to si yọ Atiku Abubakar gẹgẹ bii ọkan lara awọn oludije sipo Aarẹ lọdun 2027.

Akọwe gbogbogbo ẹgbẹ naa, Mallam Bolaji Abdullahi sọ ninu atẹjade kan lọjọbọ pe idajọ naa n tumọ si pe ẹgbẹ oṣelu APC fẹ pa ẹgbẹ alatako rẹ ni ati pe o fẹ dana sun Naijiira.

ADC ni bi idajọ naa ṣe waye lẹyin nnkan bii wakati mẹrinlelogun pere ti obitibiti ero jade fun ipolongo oloṣelu ibo Atiku nipinlẹ Sokoto mu ifura lọwọ.

Atẹjade naa ni "A gbagbọ pe wọn ti kọ idajọ naa ṣaaju akoko yii. Ipolongo ibo to waye ni Sokoto lo mu wọn tete gbe idajọ naa kalẹ.

"Lana, ẹgbẹgbẹrun ọmọ Naijiria lo tu jade lati ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu ADC toun ti ileri wa lati maye dẹrun fun wọn.

"Lonii, wọn wa n sọ fun awọn eeyan naa pe wọn le fi idajọ ile ẹjọ wọgilẹ ẹgbẹ ati oludije ti wọn tẹle."

Ẹgbẹ ọhun sọ siwaju si pe idajọ naa le ṣakọba fun ẹgbẹgbẹrun eeyan to n du ipo ni ijọba ibilẹ, ijọba ipinlẹ atawọn oludije mii ni ipele ijọba apapọ.

Wọn ni ọrọ naa kọja ọrọ Atiku tabi David Mark, amọ o jẹ nipa ẹtọ ogunlọgọ araalu lati yan ẹni to wu wọn sipo.

ADC wa ni idajọ naa ko tẹ awọn lọrun, awọn yoo si pe e nija ni gbogbo ọna.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe awọn ọmọ Naijiria lo ni Naijiria; kii ṣe ẹgbẹ oṣelu APC, ati pe ipo Aarẹ kii ṣe oye idile.

Wọn ni "Ti Aarẹ Tinubu ba mọ daju pe oun ṣe daadaa nipo, ki lo n ba a lẹru?"

Lẹyin naa ni wọn rọ awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun ki wọn ṣe suuru, ki wọn ma si fi ofin sọwọ ara wọn.

Ilé-ẹjọ́ wọ́gilé igun David Mark tó ń ṣàkóso ẹgbẹ́ òṣèlú ADC, yọ Atiku gẹ́gẹ́ bí olùdíje sípò Ààrẹ

Ile ẹjọ giga apapọ to wa niluu Abuja ti yọ Atiku Abubakar kuro lara awọn oludije fun ipo aarẹ Naijiria ninu eto idibo ọdun 2027.

Ọjọbọ, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, ọdun 2026 ni ile-ẹjọ naa paṣẹ pe ilana ti ẹgbẹ oṣelu ADC ti Atiku fẹẹ gba jade lati dije fi yan awọn oludije ko bao fin eto idibo mu.

Ile-ẹjọ naa paṣẹ pe ohun wọgile igbimọ iṣakoso African Democratic Congress, ADC ti Sẹnetọ David Mark jẹ alakoso rẹ, ati gbogbo igbesẹ ti wọn ti gbe sẹyin.

Onidajọ Peter Lifu to gbe idajọ naa kalẹ sọ pe ọna ẹburu ni igbimọ iṣakoso David Mark gba de ipo naa, ati pe ki wọn lọ rọkun nile.

Onidajọ Lifu sọ pe gbogbo igbesẹ ti David Mark ati igbimọ rẹ gbe patapata lori eto idibo ọdun 2027 ko lẹsẹ nilẹ.

Bakan naa lo sọ pe ọna ti wọn gba yan Atiku, ẹni to ti figba kan ri jẹ igbakeji Aarẹ Naijiria, gẹgẹ bi oludije sipo Aarẹ lọdun 2027 ko ba ofin mu.

Bakan naa ni ile-ẹjọ tun da gbogbo eto ati ilana ti wọn gba minisita fọrọ abẹle tẹlẹ, Rauf Aregbesola gẹgẹ bi akọw agba, ati awọn miran nu.

Ninu ẹjọ naa ni nọmba rẹ jẹ FHC/ABJ/CS/1819/2025, eyi ti igbakeji alakoso agba ẹgbẹ oṣelu ADC tẹlẹ, Nafiu Bala Gombe pe, ni ile-ẹjọ ti fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn oludije ti igbimọ iṣakoso Mark yan lati kopa ninu eto idibo 2027 ni ki wọn lọ sinmi.

Bi ẹ ko ba gbagbe, asiko ti aawọ de sinu ẹgbẹ naa, ni wọn yan igbimọ adele ti David Mark yoo ṣakoso rẹ lati tukọ eto idibo abẹle.

Igbesẹ yii ni wọn sọ pe ko tẹ awọn kan lọrun ninu ẹgbẹ, ti wọn fi gba ile-ẹjọ lọ, lati beere fun idajọ ododo.

Kí ni ilé-ẹjọ́ sọ?

Onidajọ Lifu, nigba to n gbe idajọ naa kalẹ, sọ pe ọna David Mark ati igbimọ iṣakoso naa gba de ipo ọhun tako iwe ofin ẹgbẹ oṣelu ADC ati iwe ofin idibo, to fi mọ iwe ofin ilẹ Naijiria, ti ọdun 1999.

Bakan naa ile-ẹjọ tun sọ pe ki ajọ eleto idibo, INEC ma ṣe ri igbesẹ ti awọn alakoso ẹgbẹ naa gbe nibi ipade to waye lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2025, nitori pe ko ba ofin mu.

Ki ni idajọ yii tumọ si fun ẹgbẹ ADC ninu eto idibo to n bọ?

Nigba to n sọrọ lẹyin idajọ naa, agbẹjọro Gombe, Lukman Fagbemi ṣalaye pe "Gbogbo igbesẹ ti ẹgbẹ oṣelu ADC gbe lati ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keje, ni ile-ẹjọ ti wọgile."

Agbẹjọro miran, Luka Musa Haruna (SAN), fidi rẹ mulẹ pe idajọ naa ti sọ ẹgbẹ oṣelu ADC ni ẹgbẹ oṣelu ti ko nii kopa ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ.

Haruna sọ pe lati ori ipo Aarẹ, Gomina, Sẹnetọ, Ile-Igbimọ Aṣofin, ati awọn ipo yooku kaakiri Naijiria, ẹgbẹ naa ko nii ni aṣoju kankan mọ.

ADC yóò pe ẹjọ̀ kòtẹ́milọ́rùn

Ṣugbọn ṣa, akọwe to n ri sọrọ ọmọ ẹgbẹ fun ADC, toun naa wa ninu iwe ipẹjọ naa, Nkemakolam Ukandu, ti sọ pe awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa.

Ukandu jẹ ko di mimọ pe idajọ naa kii ṣe idajọ igbẹyin, nitori pe ile-ẹjọ kọtẹmilọrun ṣi wa nibẹ fun awọn.