Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Afurasí mẹ́rin dèrò àtìmọ́lé l'Osun lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn àti gígé orí òkú
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi mẹrin lori ẹsun ipaniyan ati gige ori pẹlu apa oku.
Ilu Ikire ati Iwo ni ọlọpaa sọ pe ọwọ ti tẹ awọn afurasi ọhun, ti wọn si ti wa nibi ti wọn ti n fọrọ wa wọn lẹnu wo fun iwadii kikun.
Nurudeen Ademakinwa, ẹni ọgbọn ọdun ti wọn tun n pe ni Igboya Aye-Nuru; Agboluaje Usman, ẹni ọdun mẹtalelogun; ati Awoniran Toheeb, toun jẹ ọmọ ogun ọdun ni awọn mẹtẹẹta tọwọ kọkọ tẹ niluu Ikirun.
Bakan naa lọwọ tun tẹ Babalola Saheed, ẹni ọdun mejilelogoji lori ẹsun gige ori oku ọmọbinrin ẹni ọdun mejilelogun ti wọn ṣẹṣẹ sin, Rukibat Babatunde niluu Iwo.
Gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe ṣalaye, ẹnikan to n jẹ Seun Ajayi la gbọ pe awọn afurasi mẹta tọwọ tẹ niluu Ikirun pa danu nibi to ti lọ gẹ irun ori rẹ ladugbo Oja-Ale.
Kí ló ṣẹlẹ̀ tọ́wọ́ fi tẹ afurasi mẹ́ta?
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abiodun Ojelabi ninu atẹjade to fi sita fawọn akọroyin sọ pe ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ni iṣẹlẹ naa waye.
O ni nnkan bi agogo meje aabọ alẹ ọjọ naa ni wọn fi to ẹkun ileeṣẹ awọn ti Ikirun let iwi pe awọn janduku kan ti Ademakinwa lewaju wọn yabo ṣọọbu ẹnikan to n gẹ irun.
Nnkan bi aago mẹfa irọlẹ lo sọ pe awọn janduku naa yabo ṣọọbu naa pẹlu nnkan ija oloro bi ada ati aake, ti wọn si ṣa Ajayi pa sibẹ.
Ajayi ati ọrẹ kan toun raaye na papa bora lo sọ pe ni agbẹnusọ naa sọ pe awọn janduku yii ṣe ikọlu si, ko to di pe ọrọ di pẹntuka fawọn to wa nitosi.
O ni kete ti wọn ti fi to ileeṣẹ wọn leti ni iwadii ti bẹrẹ, to si lọwọ tẹ awọn afurasi mẹtẹẹta lọjọ karun-un, oṣu Kẹwaa.
Ojelabi jẹ ko di mimọ pe aake, ọbẹ oloju meji ati foonu olowo nla mẹta ni wọn gba lọwọ awọn afurasi ọhun ni kete tọwọ palaba wọn segi.
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe ṣaaju ọjọ naa ni Ademakinwa ti fi ohun ikilọ ranṣẹ si gbogbo awọn olugbe agbegbe Wasimi lati fi agbegbe naa silẹ, tabi ki wọn jẹ iyan wọn niṣu.
Bakan naa lo tun sọ pe iwadii ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe Ademakinwa ti ṣeku pa awọn meji kan lasiko ikọlu si awọn ọlọpaa ẹkun Ikire lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ ọdun yii.
Nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan yòókù
Siwaju sii ni atẹjade ọlọpaa tun fidi rẹ mulẹ pe Babalola Saheed, ẹni ọdun mejilelogoji lo lọ wu oku Rukibat Babatunde, ẹni ọdun mejilelogun.
Ojelabi sọ pe Rukibat lo ṣaisan, ti aisan naa si pada gba ẹmi rẹ, iyẹn lọjọ kejila, oṣu Kẹwaa ti a wa yii.
Gẹgẹ bi Musulumi ti oloogbe naa jẹ, Ojelabi sọ pe ọjọ naa ni wọn sinku Rukibat si agboole Olomo to wa lagbegbe Feesun niluu Iwo.
Agbẹnusọ yii sọ pe nnkan bi agogo meji oru ọjọ keji ti wọn sinku Rukibat ni Saheed lọ sibi ti wọn sin in si, to lọ wu jade.
Nibẹ lo ti ge ori ati apa osi rẹ kan, ko to na papa bora.
Awọn ara agbegbe naa lo ṣakiyesi ohun to ṣẹlẹ, ti wọn si lọ fi to ọlọpaa leti.
Iwadii ti awọn ọlọpaa ṣe lo tu aṣiri Saheed, ko to di pe ọwọ palaba rẹ segi, toun funra rẹ si jẹwọ pe iṣẹ eṣu ni, gẹgẹ bi agbẹnusọ naa ṣe ṣalaye.
Ojelabi sọ pe gbogbo ẹya ara oku ti Saheed ge ni awọn ti gba pada lọwọ rẹ, ti wọn si ti ko wọn pada fun baba oloogbe lati tun un sin.
Ṣé Saheed nìkan ló ṣiṣẹ́ burúkú yìí ni?
Agbẹnusọ ọlọpaa naa ṣalaye siwaju pe Saheed jẹwọ fun ọlọpaa wi pe awọn mẹta ni awọn jọ ṣiṣẹ buruku naa.
O ni awọn ti gba ada to fi ṣiṣẹ buruku naa lọwọ rẹ, ati pe awọn ṣi n wa awọn meji yooku ti wọn jọ ṣiṣẹ naa.
Ṣugbọn ṣa, ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, Ibrahim Zungura, ti bu ẹnu atẹ lu iwa ọdaju ti awọn afurasi naa hu, to si ni wọn ko nii lọ lai foju winna ofin.
Zungura wa fọkan awọn araalu balẹ wi pe idajọ ododo yoo waye lori gbogbo awọn oniṣẹ ibi naa.
Bẹẹ lo rọ awọn araalu lati ma ṣe bo ẹnu wọn nigba ti wọn ba kofiri awọn afurasi ọdaran lagbegbe wọn, paapaa awọn ti wọn ti n wa tipẹ.