Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà fẹ́ fi àbá ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ránṣẹ́ sí Tinubu
Ni bayii, ile igbimọ aṣofin agba ilẹ Naijiria ti sọ pe igbesẹ ti bẹrẹ lati gbe aba idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ lọ fun Aarẹ Bola Tinubu fun ibuwọlu.
Eyi n waye lẹyin ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ mejidinlọgbọn (28) ti gba aba naa wọle.
Akọwe ile igbimọ aṣofin agba, Kamoru Ogunlana, lo kede eyi lọjọ Iṣẹgun.
O ni awọn ipinlẹ to ti gba aba naa wọle ti ju mẹrinlelọgbọn ti ofin paapaa la kalẹ lọ.
"Latari awọn ifontẹlu ta a ti ri latọdọ awọn ipinlẹ, awọn igbesẹ to kan n lọ lọwọ lati ri i pe a taari aba naa si ọlọla julọ Aarẹ Naijiria fun ontẹ, gẹgẹ bo ṣe wa labala ofin CAP A2, (LEN) 2004."
Bẹẹ ni Akọwe ile naa ṣalaye.
Ki ni aba yii wa fun?
Ko sohun meji ti aba idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ yii wa fun ju lati ṣe atunṣe si ofin ọdun 1999, ti yoo jẹ ki wọn le pin ọlọpaa si awọn ipinlẹ, ti ko ni I maa jẹ ijọba apapọ nikan ni alaṣẹ wọn.
Ẹ o ranti pe ọrọ idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ti wa nilẹ tipẹ, ti ọpọ eeyan n pe fun un lati ni afikun eto aabo.
Gẹgẹ bi Ogunlana ṣe wi, wọn fi aba naa ṣọwọ sawọn ile igbimọ aṣofin mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2026.
O ni ile igbimọ aṣofin agba fi ṣọwọ si wọn fun apero ati ibuwọlu, awọn si ni ki wọn je abọ pada laaarin ọgbọn ọjọ.
Ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹwaa ni ọjọ abọ naa pe, o ni ṣugbọn awọn ṣi n gba abọ naa lọwọ awọn ipinlẹ yooku titi ti awọn yoo fi taari aba ọhun si Aarẹ.
Ilana ọlọpaa ijọba apapọ nikan ni Naijiria n lo lọwọ, eyi ti ko fun awọn ipinlẹ lagbara ati aṣẹ ọlọpaa.
Bi wọn ba fi aba naa ṣọwọ si Aarẹ tan, yoo kan abala miran.
Akọwe ile igbimọ aṣofin agba naa sọ pe awọn yoo maa fi to araalu leti bo ba ṣe n lọ.
Ki lo wa ninu aba idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ?
Labẹ aba tuntun yii, ọlọpaa ijọba apapọ ko ni i yọju si iṣẹ awọn tipinlẹ, afi awọn eyi to ba le gidi ti apa ipinlẹ ko ka.
Gomina ipinlẹ tọrọ kan ni yoo pe ọlọpaa apapọ ki wọn too le dide iranwọ fun wọn.
Bakan naa ni aba tuntun yii n pe fun ayipada nipa bi wọn ṣe n yan ọlọpaa sipo.
Ninu aba naa ni wọn ti ni ki Aarẹ maa yan ọga agba ọlọpaa pata, pẹlu imọran latọdọ igbimọ apapọ ọlọpaa Naijiria, ṣugbọn aba naa sọ pe gomina ni yoo maa yan kọmiṣanna ọlọpaa fun ipinlẹ rẹ.
Yoo maa yan kọmiṣanna naa lara awọn ọlọpaa to n ṣiṣẹ fun ilu rẹ, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ni yoo si pada buwọlu u.
Ninu aba yii, gomina lagbara lati paṣẹ fun kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ rẹ lori ọrọ aabo ilu.
Ṣugbọn bi kọmiṣanna naa ba ri i pe aṣẹ ọhun ko ba ofin mu, tabi ti lodi si ofin iṣẹ ọlọpaa, wọn le dari ọrọ naa si ọdọ igbimọ ọlọpaa ijọba apapọ, ohun ti awọn iyẹn ba si sọ ni abẹ ge.
Ṣugbọn ṣa, aba tuntun yii ṣi nilo kawọn aṣofin agba pinnu lori rẹ ko to le di ofin.
Bakan naa ni ìdá meji ninu mẹta ninu awọn ile igbimọ aṣofin Naijiria gbọdọ buwọ lu u, ki Aarẹ too fọwọ si i pe ko di ofin.