Lẹ́yìn ikú Toluwanisings, ilé aṣòfin àgbà dábàá kókó méjìlá fún ìtọ́jú aláìsàn pàjáwìrì àti ìjìyà ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà fún títako àbá náà

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ile asofin agba nilẹ wa ti gbe aba kan kalẹ eyi to n tako iwa kọlọransi tawọn ile iwosan atawọn ibudo ilera maa n hu sawọn alaisan.

Aba naa lo n gbe igbesẹ lati rọ awọn ibudo ilera to jẹ ti ijọba ati tawọn aladani lati maa tete gbe igbesẹ lori awọn alaisan pajawiri ti wọn ba gbe de iwaju wọn laarin isẹju mẹẹdogun pere ti wọn ba gbe alaisan naa de sibẹ.

Aba naa eyi ti Sẹnatọ Abdulaziz Yar'Adua se onigbọwọ rẹ, lo wa lati se atunse si ofin eto ilera tọdun 2014.

N jẹ ki lo wa ninu awọn aba naa ati awọn ayipada ti yoo mu ba eto ilera ni Naijiria, alaye ree.

Wo koko mejila to wa ninu aba atunse ofin eto ilera naa

Ninu aba ti Sẹnatọ Yar'Adua gbe kalẹ, awọn koko to wa ninu aba naa ree eyi ti yoo mu ayipada ba ofin eto ilera to wa nilẹ lati ọdun 2014.

Aba naa si lo wa lati se agbekalẹ ofin ti yoo pọn ni dandan fawọn ile iwosan atawọn ibudo ilera gbogbo lati maa se itọju oju ẹsẹ fun alaisan.

  • Ile iwosan gbọdọ bẹrẹ itọju lara alaisan ti wọn ba gbe de ọdọ wọn laarin isẹju mẹẹdogun pere.
  • Awọn ile iwosan ati ibudo ilera, boya ti ijọba ni tabi ti aladani gbọdọ du ẹmi alaisan naa, ko si gbewọn si laarin ọgbọn isẹju.

  • Bi o ba di dandan pe ki wọn gbe alaisan naa lọ sile iwosan to ga ju tiwọn lọ, awọn ile iwosan to ba kọkọ tọju alaisan bẹẹ gbọdọ pari igbesẹ gbigbe alaisan naa kuro lọ si ibomiran laarin wakati mẹta.
  • Aba naa tun wa lati se idanilẹkọ to yẹ fawọn osisẹ eleto ilera, ki wọn le mọ ohun to yẹ ki wọn se ti awọn alaisan to nilo itọju pajawiri ba de ile iwosan wọn.
  • Bakan naa, ofin eto ilera yii yoo se agbekalẹ igbesẹ tawọn osisẹ eleto ilera yoo gbe, to ba nilo pe ki wọn gbe alaisan naa lọ sile iwosan to ga ju tiwọn lọ fun itọju.
  • Bi dokita ko ba si ni arọwọto, ofin eto ilera yii yoo pọn ni dandan fawn olutọju alaisan to jẹ akọsẹmọsẹ, to ni iwe ẹri to yẹ, lati seto ilera pajawiri naa fun alaisan to ba nilo rẹ.
  • Awọn osisẹ eleto ilera nile iwosan tabi ibudo ilera lorilẹede yii, boya labẹ ijọba ni tabi ti aladani, to ba kuna lati se itọju alaisan to nilo itọju pajawiri, yoo fi ẹwọn osu mẹfa jura tabi ko sanwo ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira owo itanran tabi ko se mejeeji.
  • Abadofin naa lo tun n fẹ kawọn ile iwosan pese awọn ohun eelo gbẹmiro fun itọju pajawiri to fi mọ ipese afẹfẹ ti alaisan yoo mi sinu, fifa oogun sara alaisan latinu isan, mimu adinku ba irora alaisan ati sise ayẹwo lati mọ irufẹ aisan to n se alaisan laarin ọgbọn isẹju ti wọn ba gbe alaisan naa de si ile iwosan.
  • Aba naa tun pọn ni dandan fawọn ile iwosan lati gbe igbesẹ́ idoola ẹmi, to fi mọ jiji alaisan to ba daku pada, sise akoso ọna ti afẹfẹ n gba lọ simu wọn ati mimu adinku ba ẹjẹ to n da lai dawọ duro lasiko ti isẹlẹ to le gba ẹmi alaisan ba waye.
  • Lasiko ti alaisan b anilo ki wọn da duro sile iwosan, ile iwosan gbọdọ pese ibusun fun alaisan laarin wakati meji, eyiun ti ibusun b awa nilẹ.
  • Amọ ti ko ba si ibusun nilẹ ti wọn le fun alaisan naa, ile iwosan gbọdọ gbe igbesẹ lati kọ tọju alaisan naa laarin wakati meji to ba de sibẹ, tabi ni kete ti okun ba ti de ba agọ ara alaisan, to si lokun diẹ, ko to ni ki wọn gbe lọ sile iwosan miran.
  • Aba ọhun tun n fẹ kawn ile iwosan pese ọkọ alaisan pajawiri taa mọ si Anbulansi fun gbigbe alaisan naa lọ si ile iwosan miran laarin ọgbọn isẹju pere.

Ki lo se okunfa agbekalẹ aba yii?

Nigba to n tẹ pẹpẹ aba naa siwaju ile nibi ijọko ile to waye ni ana Ọjọru, Asofin agba Yar'Adua ni atunse ofin eto ilera naa ni yoo dojukọ awọn alafo nla to wa nidi ilana ipese eto ilera to poju owo ni Naijiria.

O ni atunse ofin naa si ni yoo ri daju pe awọn alaisan ri itọju gba lasiko ailera pajawiri, gba itọju ti yoo doola ẹmi wọn lai naani ipo ti wọn wa ni awujọ, bi wọn se lowo si, agbara ti wọn ni ati agbegbe ti wọn n gbe.

Sẹnatọ Yar'Adua ni "Ẹgbẹ awọn onisegun ati olutọju eyin nilẹ Naijiria, to fi mọ ẹgbẹ awọn olutọju alaisan ati agbẹbi, yoo fọwọsowọpọ lati mu agbega ba ilana ipese ilera pajawiri fun alaisan.

Bakan naa, gbogbo awn osisẹ eleto ilera lapapọ ni wọn yoo gba niyanju lati lọ fun idanilẹkọ ati gbigba iwe ẹri loore koore laarin ọdun kan ati osu mẹfa.

"Bi dokita ko ba si ni arọwọto, ofin eto ilera yii yoo pọn ni dandan fawọn olutọju alaisan to jẹ akọsẹmọsẹ, to ni iwe ẹri to yẹ, lati seto ilera pajawiri naa fun alaisan to b anilo rẹ.

"Awọn osisẹ eleto ilera nile iwosan tabi ibudo ilera lorilẹede yii, boya labẹ ijọba ni tabi ti aladani, to ba kuna lati se itọju alaisan to nilo itọju pajawiri, yoo fi ẹwọn osu mẹfa jura tabi ko sanwo ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira owo itanran tabi ko se mejeeji."

Yar'Adua ni aba eto ilera yii lo wa nibamu pẹlu ofin ilera ti wọn n lo lawọn orilẹede agbaye gbogbo bii ilẹ Ghana, South Africa, Kenya, United Kingdom ati Amẹrika.

Bawo ni ile asofin agba naa se kin aba yii lẹyin?

Nigba to n fara mọ aba naa, Akojanu ile, Sẹnatọ Mohammed Monguno (APC, Borno North), ni ti aba naa ba di ofin tan, eyi yoo fopin si iku aiyẹ to maa n waye lati ipasẹ iajmba loju popo atawọn ailera pajawiri to n su yọ lasiko ibimọ.

O wa koro oju si bawọn osisẹ eleto ilera kan se maa n kẹyin si itọju ilera pajawiri eyi to maa n ja si iku ojiji ti ko yẹ.

Monguno fikun pe aba ofin ilera tuntun naa yoo sọ titapa si ofin ọhun di iwa ọdaran, gẹgẹ bo se kan ipese itọju pajawiri.

Bawọn ile iwosan bii meje se kọ lati se itọju akọrin ẹmi, Toluwanisings, to fi jade laye

Bi ẹ ko ba gbagbe, gbajumọ olorin ẹmi kan, Olayemi Bayonle Bolaji, ti ọpọ eeyan mọ si Toluwanisings lo jade laye lẹyin to sadede subu lulẹ.

Ọjọ Kẹrinla osu Kẹwa ọdun 2026 ni isẹlẹ naa waye, gbogbo igbiyanju awn ẹbi rẹ lati doola ẹmi akọrin ẹmi naa, si lo ja si pabo.

Koda, amugbalẹgbẹ rẹ, Gbolabo sọ fun BBC News Yoruba pe awọn gbe oloogbe naa de ile iwosan bii meje si mẹjọ nilu Ibadan sugbọn ti gbogbo wọn kọ lati se itọju oloogbe naa.

Ile iwosan to gbẹyin ti Gbolabo salaye pe o gba oloogbe naa kede pe o ti jade laye.

Isẹlẹ yii si lo mu ki awọn ọmọ Naijiria maa para poro pe ẹmi eeyan ko jọ awọn eeyan loju ni Naijiria, paapaa, awọn osisẹ eleto ilera, ijiroro nipa isẹlẹ yii si lo gba ori ayelujara kan.