Arìnrìn-àjò mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n kú, ọ̀pọ̀ farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi ní Senegal

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko din ni eeyan mẹrinlelọgbọn ti wọn ti padanu ẹmi wọn sinu ijamba ọkọ oju omi to waye lorileede Senegal.

Awọn arinrin-ajo ti wọn n lọ si Senegal ni gbogbo awọn to padanu ẹmi wọn naa, gẹgẹ bi iroyin orileede naa, APS ṣe gbe e.

Minisita fọrọ eto abẹle ni Senegal ti fidi rẹ mulẹ pe awọn omuwẹ ti doola ẹmi ẹnikan ni wọn ri doola, bo tilẹ jẹ pe ko tii sẹni to le sọ pato iye awọn to wa ninu ọkọ oju omi naa.

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni awọn omuwẹ ati awọn alakoso ṣi n tẹsiwaju igbiyanju lati ri awọn yooku ti wọn ri sinu omi.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn arinrin-ajo naa ni wọn wa lori igbesẹ lati lọ silẹ Yuroopu, ki wọn le tẹdo sibẹ fun igbe aye tuntun.

Bo tilẹ jẹ pe ko tii sẹni to le sọ pato asiko ti ijamba naa waye, ṣugbọn igbagbọ wi pe laaarin ọjọ Ẹti si Abamẹta, ọsẹ to kọja ni.

Itosi agbegbe kan ti wọn pe ni Loumpoul to wa ni ẹkun Ariwa Iwọ-Oorun Kébémer, to wa laaarin Dkar si Saint-Louis ni ijamba ọhun ti waye.

Aarẹ ilẹ Senegal, Bassirou Diomaye Faye fi aidunnu rẹ han lori ijamba naa, to si ba gbogbo mọlẹbi awọn oloogbe naa kẹdun.

Faye sọ pe awọn alakoso ti bẹrẹ igbesẹ lati rii daju pe gbogbo awọn to dawati ni ko wọn ṣawari wọn.

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ gangan?

O ṣee ṣe ki minisita fọrọ eto abẹle ṣabẹwo ibanikẹdun si mọlẹbi gbogbo awọn to padanu ẹmi wọn.

Ajalu yii lo waye lasiko ti ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ilẹ Iwọ-Oorun Afrika n Japa lọ si Canary Island lorileede Spain, to si jẹ pe ọpọ lo ti padanu ẹmi wọn lori irin ajo yii.

Lọjọ Ẹti, awọn alakoso Senegal mu ọkọ oju omi kan to gbe awọn arinrin-ajo mejilelogoje ti wọn n gbiyanju lati lọ si Spain.

Awọn ọlọpaa sọ pe obinrin mẹtalelogun, ọmọ ọwọ meji, ọmọde meji, to fi mọ awọn ọmọ ilẹ Senegal, Gambia, Guinea-Bissau, Guinea ati Nigeria.

Ṣugbọn ṣa, awọn alakoso El Hierro ni Spain ti kede pajawiri lori bi awọn arinrin-ajo ṣe n wọle si orileede wọn lọna aitọ.

Awọn to le ni ọọdunrun le lẹgbẹrun mẹta ni wọn ti wọ orileede naa pẹlu ọkọ oju omi ti ko din ni ọgbọn lati ibẹrẹ oṣu Kọkanla, gẹgẹ bi awọn alakoso ṣe sọ

Lọdun to kọja, awọn ẹgbẹrun kan le nigba eeyan ni wọn ku, tabi di awati ninu igbiyanju lati wọle si Canary Island lati ẹkun Iwọ-Oorun Africa, gẹgẹ bi ajọ IOM ṣe sọ.

Awọn alakoso orileede Senegal, Mauritania ati Morocco ti ko awọn ọmọ ogun sita lati maa mu awọn arinrin-ajo to n wọ orileede wọn lọna aitọ.