Wo ọkùnrin ọmọ ijọ́ Ajẹ́rìí-Jehofa tó kú torí ó kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀ àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ìjọ́ yí òfin mágbẹ̀jẹ̀ padà

    • Author, Aleem Maqbool
    • Role, Religion editor
    • Author, Catherine Wyatt
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni osu kẹjọ ọdun yii, Isaac Valdez tii se ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ni aisan warapa ki mọlẹ lasiko to n kawe nile iyawe-kawe to wa lagbegbe rẹ, eyi to mu ki giri mu u, to si n lẹ ori mọlẹ.

O daku rangbọndan amọ nigba to ya, wọn ri nile iwosan pe Isaac ti lẹ ori rẹ mọlẹ debi pe ẹjẹ ti kun inu ọpọlọ rẹ.

Amọ itọju rẹ le gidi gan tori pe o jẹ ọmọ ijọ Ajẹri-Jehovah, eyi to tumọ si pe wọn ko gbọdọ fa ẹjẹ sinu ara rẹ nitori igbagbọ ati ofin ijọ rẹ lati mase gba ẹjẹ.

Idi ree ti wọn ko le fa ẹjẹ kuro ninu ọpọlọ Isaac.

Amọ awọn ẹbi rẹ to wa lati ilu Waxahachie, nipinlẹ Texas, ni iwuri ba tori pe ọmọ wọn ji pada lẹyin to daku, to si pada sọrọ.

Bakan naa lo si duro lori igbagbọ rẹ pe ko gbọdọ si ẹjẹ.

Amọ se ni ayọ awọn obi rẹ ko pẹ titi tori se ni Isaac pada da ku rangbọndan, ti ilera rẹ si buru si.

Dokita onisegun nipa aisan ọpọlọwa sọ fawọn ẹbi Isaac pe ọna kan soso ti oun fi le doola ẹmi ọmọ wọn ni pe ko se isẹ abẹ pajawiri eyi ti wọn nilo lati fa ẹjẹ si lara.

Amọ se ni awọn ẹbi rẹ duro lori ipinnu Isaac lati mase gba ẹjẹ nitori pe ofin ijọ Ajẹri Jehovah titi ayeraye ni pe ki ọmọ ijọ wọn kankan mase gba ẹjẹ.

Isaac, ẹni to jẹ ibeji, ti ibeji rẹ, Jacob Valdez sapejuwe bii ọlọpọlọ pipe to maa n fi ara rẹ jin lati ran awọn agbalagba lọwọ, lo ku ni ọjọ kẹrindinlọgbọn osu kẹjọ ọdun 2026 lasiko ti awọn dokita pa ina lara ẹrọ to n gbe ẹmi rẹ ro.

"Ka ni awọn adari Ajẹri-Jehovah tete gbe ayipada ofin naa jade ni, ibeji mi ko ba ti ku"

Amọ o se ni laanu pe lẹyin ọjọ mẹtalelogun ti Isaac ku, ni igbimọ oludari fun ijọ Ajẹri-Jehovah kede iyipada si ilana wọn.

Iyipada yii ni ko ba si fun Isaac ni asẹ lati gba iwosan ti ko ba doola ẹmi rẹ=, eyi to kọ lati se.

Iyipada ojiji yii lo tumọ si pe kii se eewọ tabi ẹsẹ fun awọn ọmọ ijọ Ajẹri Jehovah mọ lati gba ẹjẹ amọ ipinnu lati gba ẹjẹ lasiko aisan wa ku si ọwọ ẹni kọọkan wọn.

Jacob, ẹni to si n sọfọ iku arakunrin rẹ, ni inu bi pupọ si awọn asaaju ijọ Ajẹri Jehovah pe wọn ko tete gbe ipinnu wọn tuntun naa jade.

Jacob sọ fun BBC pe arakunrin oun ko ba si wa laye to ba jẹ pe ijọ Ajẹri-Jehovah tete gbe ipinnu tuntun naa lati gba ẹjẹ sita.

Bawo ni ofin "Mase gba ẹjẹ" se waye ninu ijọ Ajẹri-Jehovah ati idi ti wọn se yi ofin naa pada lẹyin ọdun mọkanlelọgọrin?

Lati ọdun 1945 ni ijọ Ajẹri-Jehovah ti gbe ilana mase gba ẹjẹ silẹ, lasiko ti ogun agbaye keji n pari lọ, akoko yii si ni asa fifa ẹjẹ si ni lara gbalẹ kan. Awọn adari ijọ Ajẹri Jehovah si kede nigba naa pe awọn ko fun ọmọ ijọ wọn kankan lasẹ lati gba ẹjẹ.

Eyi si da lori bi wọn se tumọ bibeli lati majẹmu laelae si majẹmu tuntun, eyi to n fofin de mimu ẹjẹ, to fi mọ iwe Ise Awọn Aposteli to pasẹ fawọn onigbagbọ lati rin jinaa si ẹjẹ, ounjẹ ti wọn fi bọ orisa ati jijẹ awọn ẹranko ti wọn ba fun ni ọrun pa.

Ki lo wa mu ki igbimọ oludari ijọ Ajẹri-Jehovah ti ibujoko rẹ wa nilu New York nilẹ Amẹrika, se wa yi ipinnu rẹ pada lẹyin ọdun mọkanlelọgọrin to kede ofin naa?

Ipinnu naa lo waye lẹyin ọpọ atẹnumọ fun iyipada ninu ati nita ijọ naa, amọ bawọn adari ijọ naa se sapejuwe ayipada ipinnu wọn naa kọ ni eyi

"Iyipada yii lo da lori sise amulo ilana inu Bibeli si eto isegun aye ode oni ati ilana rẹ"

Eyi agbẹnusọ fun ijọ Ajẹri Jehovah lagbaye, Paul Gillies sọ ẹni to se apejuwe ofin tuntun lati gba ẹjẹ naa bii atungbeyẹwo ọtun si iwe mimọ gẹgẹ bo se kan ilọsiwaju imọ isegun.