Ètò ìsìnkú Toluwanisings bẹ̀rẹ̀ lónìí

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbogbo eto lo ti n lọ lọwọ bayii lati sinku gbajugbaja akọrin ẹmi nni, Olayemi Bolaji Bayonile, ẹni tọpọ mọ si Toluwanisings.

Gẹgẹ bi iwe ipe ati itọni ti awọn mọlẹbi Oloogbe naa fi oju opo rẹ laipẹ yii, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe oni tii ṣe ọjọ Aje, ọjọ kẹsan, oṣu Kọkanla, ọdun 2026 ni eto isinku ọhun yoo waye.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ni Toluwanisings jade laye, nigba ti awọn mọlẹbi rẹ sọ pe niṣe lo deedee ṣubu lulẹ.

Inu gbọngan ayẹyẹ Banjola to wa ni opopona Hope, agbegbe Alakia ni eto isinku ọhun yoo ti waye niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo, bẹrẹ lati agogo mẹsan owuro.

Gẹgẹ bi awọn mọlẹbi naa ṣe ṣalaye, wọn ni eto isinku naa yoo waye laaarin agopo mẹsan si mẹwaa owurọ.

Lẹyin eyi ni wọn jẹ ko di mimọ pe wọn yoo pada fi eeru fun eeru, ati erupẹ fun erupẹ laaarin agogo mẹwaa si mọkanla owurọ.

Ṣugbọn ṣa, awọn mọlẹbi naa ko sọrọ nipa ibi ti wọn yoo sinku Oloogbe naa si.

Ati pe, eto isinku naa ni yoo fopin si gbogbo ariyanjiyan ati faakaja to ti waye lori ibi ti oloogbe naa yoo sun si.

Bakan naa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti pe awọn mọlẹbi oloogbe naa lati tọwọ bọwe adehun lati gba alaafia laaye.