Ẹ má sunkún tí mo bá kú, àrá máa sán pa ẹni tó bá ké nítorí mi- Oba Solomon

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

"Bi ẹ ba gbọ pe mo ku, ẹni to ba ké, Àrá maa pa a."

Gbajugbaja sọrọsọrọ ori ayelujara nni, Adelana Adekunle Solomon tawọn eeyan mọ si Oba Solomon, tabi Oba Agbaye, lo sọrọ yii laipẹ yii.

Ninu fidio kan loju opo ayelujara Instagram, nibi ti Oba Solomon ti wọ aṣọ adura to si n ba awọn ọmọ ijọ rẹ sọrọ lo ti sọ pe:

"Lẹyin iyẹn, ti wọn ba ti kede iku mi, ẹni to ba ke, Àrá maa san pa.

"Ẹ sunkun ara yin, ẹ ma sunkun mi. Emi naa ki i ke fun eeyan, fun idi eyi, ẹ ma sunkun mi."

Oba Solomon tẹsiwaju pe:

"Ẹ gbẹ bẹẹdi mi kuro ki ẹ sin mi yara mi''

Gẹgẹ bi pasitọ ti waasu rẹ maa n yatọ naa ṣe wi fawọn ọmọ ijọ rẹ ninu fidio naa, o ni ki wọn wo ile to wa laaarin ninu awọn ile kan to wa nitosi ṣọọṣi naa.

"Ẹ gbọ mi daadaa, ti mo ba ku, ẹ gbẹ bẹẹdi mi kuro ni yara mi kẹ ẹ sin mi sibẹ, ile mi niyẹn.

"Ẹnikẹni to ba yi aṣẹ yii pada maa ku ni, nitori ile mi ni."

Bakan naa lo tun kilọ pe ki wọn ma ṣe gbe oun sinu yinyin tabi ṣeto ati pa ara oun mọ fun igba pipẹ lẹyin iku.

Oba Solomon sọ pe ki wọn ma ṣe fi kẹmika kankan si oun lara lati mu oun duro ju bo ṣe yẹ lọ ki wọn too sinku oun.

"Ti mo ba ku, ẹ fi mi silẹ fun bii wakati mẹrin, boya mo le tun ero mi pa, lẹyin iyẹn, ẹ sin mi.

"Ti mo ba ku laaarọ, ẹ fi mi silẹ di nnkan bii aago mẹrin irọlẹ. To ba jẹ pe alẹ ni, ẹ fi mi silẹ di bii ọwọ ọsan,bi mi o ba ji, ẹ sin mi."

"Iwọ iyawo mi le ni ibalopó lọjọ keji iku mi, nitori to ba jẹ iwọ naa lo ku, mo maa ni ibalopọ lọjọ iku rẹ gan-an"

Si iyawo rẹ, Oba Solomon sọ pe lọjọ keji toun di ero ọrun ni anfaani ti wa fun obinrin naa lati fẹ ni ibalopọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi:

"Iwọ ti o jẹ iyawo mi,anfaani wa fun ọ lati maa ni ibalopọ rẹ lọ lọjọ keji, tori ka ni iwọ naa lo ku, lọjọ yẹn gan-an, ma a ni ibalopọ."

Bi wọn yoo ba fi posi sin oku rẹ, Oba Solomon sọ pe igikigi ti wọn ba ti ri naa ni ki wọn lo.

O ni ko sohun to kan oun to bẹẹ ju bẹẹ lọ pẹlu posi.

Nipari ọrọ naa lo ti ni aṣẹ ni gbogbo ohun ti oun wi ọhun, ki I ṣe aba rara, o ni ki ẹnikẹni ma ṣe gbiyanju lati yi I pada, ki wọn jẹ ko wa bẹẹ ni.

Ta ni Oba Solomon

Ọmọ bibu ilu Ikale, nipinle Ondo ni Oba Solomon. Sọrọsọrọ ni lori ayelujara, bẹẹ naa lo si tun jẹ oludari ijọ.

Ọjọ Karun-un oṣu Karun-un ni wọn bi I gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe fi han.

Ibeju-Lekki, nipinlẹ Eko ni won si bi I si.

Oba Solomon gbajumọ fun bo ṣe maa n sọrọ lai da ohunkohun pe, paapaa ọrọ nipa ibalopọ ọkunrin ati obinrin.