Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Pásítọ̀ tó ṣokùnfà ikú èèyàn 191 rí ẹ̀wọ̀n igba ọdún he
Ile ẹjọ kan ni Kenya ti ṣedajọ ẹwọn igba ọdun fun Paul Mackenzie, to jẹ olori ijọ kan fun pipa eeyan ti iye wọn to 191.
Wọn ni Paul Mackenzie, toun ti eeyan mejidinlọgbọn mii jẹbi ẹsun ipaniyan lẹyin ti wọn paṣẹ fun awọn ọmọ ijọ naa pe ki wọn fi ebi pa awọn ọmọ wọn titi ti wọn yoo fi ku ki wọn le ba Jesu jọba.
Adajọ Diana Mochache sọ pe ẹbi Mackenzie lo pọ ju lẹyin to paṣẹ fun awọn ọmọ ijọ rẹ ki wọn gbaawẹ titi iku yoo fi de ba wọn.
Ọkunrin naa, to pe ara rẹ ni pasitọ kọkọ ko sọwọ ọlọpaa ninu ọdun 2023 lẹyin ti wọn ṣawari oku eeyan to le ni irinwo ninu igbo Shakahola to wa lẹba eti okun Kenya.
Awari naa jẹ ara meeriri fun ọpọ araalu ti ọpọ eeyan kaakiri agbaye si pe fun iwadii lori iku awọn eeyan ọhun.
Ile ẹjọ sọ Mackenzie si ẹwọn ọgọrun ọdun fun ipaniyan ati ọgọrun ọdun mii fun ẹsun to ni ṣe pẹlu mi mọọmọ fi ebi pa eeyan.
Apapọ iye ọdun ti wọn ni ọdaran naa yoo lo lọgba ẹwọn jẹ igba ọdun.
Mackenzie tun koju ẹsun mimọọmọ gbẹmi eeyan ati iwa igbesunmọmi amọ o ni oun ko jẹbi awọn ẹsun naa.
Awọn agbẹjọro ijọba sọ pe idajọ iku lo yẹ ki ọkunrin naa gba latari bi ẹsun ti wọn fi kan an ṣe lagbara to.
Amọ adajọ Mochache kọ lati ṣe idajọ iku fun ọdaran naa bo tilẹ jẹ pe o ni ẹsẹ rẹ tọ si idajọ iku.
Adajọ naa sọ pe idajọ iku ko ni fun ọkunrin naa lanfani lati ronupiwada.
Ko si ẹnikẹni to tii gba idajọ iku ni Kenya lati ọdun 1987.
Lara awọn mejidinlogun mii to jẹjọ pẹlu Mackenzie lawọn ẹṣo rẹ to maa n fi agidi mu awọn ọmọ ijọ rẹ gbaawẹ.
Gbogbo wọn ni wọn gba idajọ ẹwọn ti apapọ rẹ to ọdun 160.