Àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run méjì ló ṣèkilọ̀ ohun tó gbé mi dé ọgbà ẹ̀wọ̀n fún mi ṣùgbọ́n mi ò gbọ́ ìkìlọ̀ - Baba Ijesha

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajumọ oṣere tiata, Olanrewaju Omiyinka ẹni ti ọpọ mọ si Baba Ijesha ti sọ pe awọn ojiṣẹ Ọlọrun meji ni wọn ṣekilọ fun oun ṣaaju ki oun to ri iṣoro to gbe oun de ọgba ẹwọn.

O ni awọn ojiṣẹ Ọlọrun naa ti sọ fun oun pe maa ni iṣoro pẹlu awọn obinrin eyi to ṣeeṣe ko di ounti awọn n lọ sile ẹjọ si ṣugbọn oun ko kọbi ara si ikilọ wọn.

Baba Ijesha sọ pe oludasilẹ ijọ Love of Christ Generation Church ti ijọ Cherubim ati Seraphim, iranṣẹ Ọlọrun, Abimbola Ajayi ati oludasilẹ ijọ Genesis Global Ministry, Pasitọ Israel Ogundipe ti ọpọ mọ si Genesis ni wọn ṣekilọ naa fun oun.

Nibi eto Agbaletu ti Dele Adeyanju jẹ olootu rẹ ni Baba Ijesha ti sọrọ naa.

Nigba to n ṣeranti bi Ajayi ṣe ba oun sọrọ, o ni orilẹ ede United Kingdom ni awọn mejeeji ti pade ni ile ijọsin rẹ nigba ti oun ṣe irinajo lọ sorilẹ ede naa fun ere kan.

O ni oun fẹ lọ wọ ọkọ oju irin ni ki ẹni to gbe oun lọ si UK rọ oun lati lọ sibi eto ile ijọsin naa kan to n waye nibẹ.

O ni nigba ti awọn debẹ ni ojiṣẹ Ọlọrun naa beere fun aaye lati bao un sọrọ.

O ṣalaye pe Ajayi ṣekilọ fun oun pe ki oun ṣọra fun awọn obinrin paapaa ẹni to ba kuru, to ni omi lara, to si ṣeeṣe ki oun koju ohun to maa fa ki awọn maa lọ sile ẹjọ.

"Ẹmi Ọlọrun ni ki n ṣekilọ fun ẹ nipa awọn obinrin," o ṣeranti oun ti Ajayi sọ fun.

"O sọ fun pe emi Ọlọrun ni ki oun sọ fun mi pe ki n ṣọra fun obinrin to ba kuru, to si dudu.

"O ni mo maa ko sinu wahala, ti mo si maa ko sinu igbẹjọ, to si ni ki n gbadura daadaa ki n to jẹ irọ ma dabi ootọ ṣẹlẹ si mi."

O fi kun pe ikilọ naa ya oun lẹnu, ti oun si beere pe ki ni oun le ṣe lati fi dena ajalu naa ti wọn si sọ fun oun pe adura nikan ni o le yanju iṣoro naa, pe ki oun wa ri oun ti oun ba ti pada si Naijiria.

Baba Ijesha wa ni oun ko tẹle gbogbo ikilọ ti wọn fun oun nigba ti oun pada si Naijiria bi o tilẹ jẹ pe oun pada gbiyanju lati kan si iya Ajayi ṣugbọn ti oun ko rib ikan sii.

Nigba to n sọrọ nipa bi Genesis ṣe ṣekilọ fun-un lori iṣẹlẹ naa, Baba Ijesha ni kete ti oun de ile rẹ ni o darukọ eeyan kan fun oun to si beere pe ta ni ẹni naa ninu awọn ọrẹ ti oun ni ṣugbọn ti oun ko ri inu kankan ro nipa ẹnikẹni.

O ni lẹyin ti iṣẹlẹ to ṣẹlẹ si oun waye ni oun ṣẹṣẹ n ranti gbogbo ikilọ ti wọn ti fun oun ṣugbọn ti ẹpa ko boro mọ lori ọrọ naa.

"Ọgba ẹwọn ni adura ti n gba julọ"

Nigba to n sọrọ lori iriri rẹ lọgba ẹwọn, Baba Ijesha ni ọgba ẹwọn jẹ ibi ti adura ti maa n gba to si sọ pe ọpọ eeyan ti wọn kọ deedee maa n ṣubu lulẹ, jade laye lo jẹ pe adura awọn ẹlẹwọn lo n ran wọn lọ sọrun pẹlu adura wọn.

"Awọn eeyan maa n gbadura ni ọgba ẹwọn, awọn mii maa gbadura ebi pe wọn maa fi okuta ya ara wọn titi ti ẹjẹ fi maa jade ti wọn si maa gbe ara wọn ṣepe lori oun to gbe wọn de ọgba ẹwọn."

O ni igba oun lẹwọn jẹ eyi to buru gan-an nitori awọn ẹṣọ aabo ọgba ẹwọn ko mọ ẹnikan yatọ si ẹlomiran ti o si jẹ ibi ti ọpọ eeyan ti n kẹkọọ.

O fi kun pe oun gbe igbe aye ẹlẹwọn nigba ti oun wa lẹwọn pẹlu bi oun ṣe jẹ ilumọọka to nitori awọn ẹṣọ aabo ọgba ẹwọn ko fẹ mọ pe eeyan kan jẹ ilumọọka.

"Awọn ẹṣọ aabo ọgba ẹwọn ko mọ ẹni to n jẹ ilumọọka, wọn kii gbọ redio tabi mọ ohunkohun to n lọ, iṣẹ ti wọn ni lati fiya jẹ ọdaran."

Baba Ijesha ni iyalẹnu lo jẹ fun oun bi wọn ṣe n ṣe sawọn to jẹ ilumọọka, awọn gbajumọ awujọ ni ọgba ẹwọn.

O ni ọpọ eeyan tawọn araalu maa n ro pe wọn wa niluu oyinbo lo jẹ pe ọgba ẹwọn ni wọn wa, tawọn ẹṣọ aabo ọgba si maa n ṣe wọn bi araalu lasan.

Ẹ o ranti pe ni ọdun 2022 ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Eko sọ Baba Ijesha si ẹgba ẹwọn fun ọdun marun-un fun ẹsun fifi ipa ba ọmọde lo pọ.

Lẹyin naa ni ijọba ipinlẹ Eko fi orukọ Baba Ijesha sara awọn eeyan eeyan ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe wọn jẹbi ẹsun iwa ifipabanilopọ.