Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Èèyàn méje kú, àwọn tó lé lọ́gọ̀rún farapa níbi ìjàmbá reluwé tó wáyé ní Egypt
Ko din ni eeyan meje ti wọn ti padanu ẹmi wọn nibi ijamba ọkọ oju irin tii ṣe reluwe to waye niluu Giza, orileede Egypt
Yatọ si awọn meje to padanu ẹmi wọn, awọn eeyan to le ni ọgọrun kan ni wọn tun farapa yannayanna lasiko ijamba naa.
Awọn alakoso reluwe lorileede naa sọ pe ọkọ reluwee meji lo fori sọ ara wọn lasiko ti awọn mejeeji n rin irin ajo.
Wọn ni ọkọ reluwe kan to n rin irin ajo lati ẹkun Guusu Giza ati Cairo ni wọn fori sọ ara wọn, to si jẹ ki ọkọ naa danu lori irin rẹ.
Loju ẹsẹ ni awọn to wa nitosi ti ranṣẹ si awọn ileeṣẹ tọrọ naa kan lati dide iranlọwọ fun awọn fara kaaṣa.
Alaye wo nijọba orilẹede Egypt n ṣe lori ọrọ naa?
Aarẹ orilẹede Egypt, Abdul Fattah al-Sisi sọ pe oun ti paṣẹ fun gbogbo awọn to yẹ lati "ṣe iwadi ohun to ṣokunfa ijamba naa, ki wọ̀n si fi gbogbo awọn ti aje rẹ ba ṣi mọ lori jofin".
Awọn alaṣẹ sọ pe iye awọn to ku ṣi le pọ sii.
Ijọba orilẹede Egypt ṣalaye pe wọn ti ni ki awọn ileewosan lagbegbe naa wa ni igbaradi fun bi wọn yoo ṣe maa ko awọn to fi ara pa yoo ṣe maa wọle.
Minisita fun eto ilera, Dokita Khaled Abdel Ghaffar ṣalaye pe ọpọ awọn to farapa ni wọn ti n tọju fun ẹgun dida ati ọgbẹ ori.
Ẹgbẹ oloṣupa pupa lorilẹede Egypt, 'Egyptian Red Crescent', sọ pe awọn ti n ṣe ipese itọju to yẹ fun awọn to fara kaasa ijamba naa ati idile wọn.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Awakọ ọkan ninu awọn reluwe naa, wa lara awọn to ku ninu ijamba naa, gẹgẹbi awọn alaṣẹ ṣe sọ.
Ọkọ reluwe to kọkọ farakaaṣa ijamba naa la gbọ wi pe o n gbera lati Giza lọ si Fayoum lẹkun Gusu ilu Cairo ki o to lugbadi ijamba naa nigba to kọlu ẹyin reluwe miran to n lọ lati ẹkun gusu ilu Cairo lọ si Aswan, amọ to duro loju opo naa nigba ti iṣẹlẹ naa waye.
Awọn alakoso ti wa paṣẹ pe ki gbogbo iṣẹ awọn ọkọ oju irin laaarin Giza si Upper Egypt da iṣẹ duro titi digba ti wọn yoo fi pari eto lati gbe awọn ọkọ oju irin to ni ijamba naa kuro.
Bakan naa ni awọn alakoso ọkọ oju irin jẹ ko di mimọ pe awọn ko nii gba ọpọlọpọ asiko lati fi palẹmọ awọn ọkọ oju irin to ni ijamba naa kuro.
Ijamba to waye yii ni wọn loo ṣẹlẹ nitosi ibi ti ijamba ọkọ oju irin to waye ninu oṣu Keji, ọdun 2002 ti waye laaarin Kafr Ammar ati Al-Raqqa ni Al-Ayyat.
A gbọ pe ina lo ṣẹyọ ninu ọkọ oju irin to n rin irin ajo lati Cairo lọ si Luxor nigba naa.
Awọn to le aadọrinlelọọdunrun ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe wọn padanu ẹmi wọn lọdun naa, bo tilẹ jẹ pe awọn kan sọ pe iye awọn to ku ju bẹẹ lọ.
Ijamba meji miran to tun ṣẹlẹ lawọn agbegbe yii lọdun 2009 pa ogunlọgọ awọn eeyan.
Àwọn aráàlú dìde ìfẹ̀hónú hàn
Ni bayii, lọjọ Aiku to kọja yii ni oniruuru ifẹhonuhan ti dide ni Egypt, nibi ti awọn araalu ti n pariwo pe ki minisita feto irinna kọwe fipo silẹ lori ijamba oju irin to ṣẹlẹ.
Ṣugbọn ṣa, awọn olori orileede kaakiri agbaye ni wọn ti ba orileede Egypt kẹdun ijamba naa, to fi mọ awọn to fara kaaṣa.
Ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ okeere ni Saudi Arabia ti wa fi atilẹyin wọn han si Egypt, to si fi ifẹ han pe ki ara awọn to farapa tete le koko.
Bakan naa ni aṣoju Turkey si Egypt kọ ọ soju opo 'X' rẹ pe oun ba orileede naa kẹdun.