Mi ò sí lábẹ́ ẹnikẹ́ni, abẹ́ Ọlọ́run nìkan ni mo wà, Oluwo sọ̀rọ̀ sókè lẹ́yìn tó gba lẹ́tà ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ ìjọba Osun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oluwo ti ilẹ Iwo, Oba Abdulrosheed Akanbi, ti da a pada fun ijọba Gomina Ademola Adeleke ipinlẹ Osun wi pe Ọba Alade ni oun ati wi pe Ọlọrun nikan loun n jabọ fun un.

Ọba Akanbi to koro oju si bi ijọba ipinlẹ Osun ṣe kọ lẹta si i lati kilọ fun un, sọ fun Gomina wi pe o yẹ ko beere ilanilọyẹ lọwọ oun ti nnkankan ba ru u loju.

Oluwo to sọrọ ninu fidio kan eyi to ti lu ori ayelujara pa sọ pe ''Ọba alaye ni mi, ọba si maa n ba a lori ohun gbogbo ni.

Mi o si labẹ ẹnikẹni afi Ọlọrun Ọba, Ọba to tẹ ilẹ bi ẹni tẹni.

Ọba ti gomina ati aarẹ n bẹ labẹ rẹ, Ọba tawọn sẹnẹtọ wa labẹ rẹ.

Ọlọrun ọba yii naa ni Dangote Olowo Naijiria wa labẹ rẹ.

Awa mọ ipo ọba lo nibi yii, mo si gbadura wi pe Ọlọrun yoo maa wa pẹlu wa.

A ki ijọba naa wi pe wọn ku iṣẹ o, amọ, mo rọ ijọba wi pe ki wọn maa gbiyanju lati wa maa ba mi ni aafin.

Wọn si tun le ranṣẹ si mi pe ki n wa si ọfiisi gomina naa.''

Oluwo ni t'ilu tifọn loun yoo fi lọ pade gomina ti awọn mejeeji yoo si jọ jo papọ ti gomina ba ranṣẹ si oun pe koun wa.

''Ko si si nnkan ti ẹnikẹni le ṣe, awọn to ba n binu mi yoo binu lọ ko sodo ni''

Ọba Akanbi sọ pe oun fẹ ki ijọba maa beere ọrọ lọwọ oun na ki wọn to kọ lẹta.

Kabiyesi Oluwo ni o yẹ ki ijọba maa beere nipa ọrọ to ba ni i ṣe pẹlu aṣa ati iṣe niluu ki ijọba to kọ lẹta.

Oluwo ni oun lẹtọọ lati ṣalaye bi ọrọ ba ṣe jẹ fun gomina ti wọn ba ranṣẹ soun.

Kabiyesi Oluwo sọ pe oun kii ṣe adari ẹsin tabi adari aṣa bi ko ṣe ọba alaye.

''A kii ṣe ọta ara wa, awọn kan lo wa nidii ọrọ naa.

Ko si si nnkan ti ẹnikẹni le ṣe, awọn to ba n binu mi yoo binu lọ ko sodo.

Gbogbo awọn to n binu si mi ni inu wọn ko ni dun, tori inu ọta mi ko gbọdọ dun,'' Oluwo lo sọ bẹẹ.

Ijọba Osun kilọ fun Oluwo lori ọrọ to n sọ nipa ẹsin

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Osun ti kilọ fun Oluwo lori awọn ọrọ to n sọ eyi ti ijọba sọ pe o le da ija ẹsin ati ilu si ilu silẹ.

Ninu lẹta ọhun ti ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ oye jijẹ ati ijọba ibilẹ nipinlẹ Osun ti kilọ pe ọrọ ti kabiyesi naa n sọ le da omi alaafia ru laarin awọn eeyan ti ẹsin wọn yatọ.

Ninu lẹta ọhun ni akọwe agba ileeṣẹ ijọba naa, Wale Alliyu, ti sọ pe ijọba n kọminu lori awọn ọrọ ti Oluwo n sọ.

Lẹyin ti Oluwo gba lẹta naa tan ni o sọrọ ninu fidio kan eyi ti o ti sọ pe oun ko si labẹ ẹnikẹni ayafi Ọlọrun.