Wọ́n ní Gómìnà Adeleke jẹ gbèsè kún gbèsè l'Osun, àmọ́ Gómìnà Osun ní pínrín òun kò yá owó kankan látòkè òkún!

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ti sọ pe irọ ni iroyin to n lọ ni igboro pe oun ya owo loke okun lati igba ti oun ti gori oye ninu oṣu kọkanla, ọdun 2022.

Adeleke lo sọrọ naa lasiko to n fesi ti ọrọ ajọ to n ri si gbese ijọba, Debt Management Office (DMO) sọ pe iye gbese ipinlẹ Osun gbera soke si $26.56m laarin oṣu Kejila, ọdun 2024 si oṣu Kẹfa, ọdun 2026.

Gẹgẹ bii ohun ti DMO sọ, nigba ti yoo fi di inu oṣu Kẹfa, ọdun 2026, iye gbese ipinlẹ ọhun loke okun ti di $101.70 miliọnu lati $75.14 miliọnu to wa lọjọ kọkanlelọgbọn, ọdun 2024.

Atupalẹ gbese naa, gẹgé bii DMO fi han gbese naa gbera lati nnkan bi $67.60 miliọnu loṣu Kejila ọdun 2024 si $94.15 miliọnu ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2026, ti gbese mii tun gbera latu $7.54 miliọnu si $7.55 miliọnu lasiko kan naa.

Ko ri bẹẹ o, irọ nla gbaa ni – Adeleke

Nigba to n ṣalaye bi gbese naa ṣe pọ si, Adeleke ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Olawale Rasheed fi lede sọ pe gbese kan ti iye rẹ jẹ $25.8 miliọnu ti DMO ka fun ijọba Adeleke lo jẹ eyii ti ijọba to wa lori alefa ṣaaju rẹ ti jẹ ko to gori oye.

Rasheed sọ pe gbese naa ni wọn ya fun eto ọgbin igberiko labẹ eto iyẹn Rural Access and Agricultural Marketing Project (RAAMP).

O ṣalaye pe inu oṣu Kejila ọdun 2025 lo yẹ ki ijọba san owo naa pada lo jẹ ki DMO kaa mọra gbese ijọba Adeleke.

Ijọba Osun sọ siwaju si pe ijọba to wa lori oye ṣaaju Adeleke tun ya owo nigba mẹrin mii to yẹ ki wọn san pada amọ ti ko san, eyi ti wọn wa n ka mọ ara gbese ijọba Adeleke bayii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ijọba Adeleke ko ya owo kankan lati oke okun, eyii to jẹ ọkan lara awọn igbesẹ rẹ lati daabo bo ọrọ aje ipinlẹ Osun.

Lẹyin naa lo ni alaimọkan lawọn to n sọ pe ijọba Adeleke n ya owo lati oke okun.

Atẹjade naa ni "O ṣe pataki lati ṣalaye yii. Ti ijọba wa ba tilẹ fẹ ya owo fun idi kankan, a o jẹ ki gbogbo araalu mọ pe a fẹ ya owo ati ohun ti a fẹ fi owo naa ṣe."