Ṣé lóòótọ́ làwọn jàǹdùkú kò já ààfin Awujale gbà? Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ogun ṣàlàyé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti jiyan iroyin kan to gba igbooro pe awọn ọmọ ganfe atawọn janduku ti gba gbogbo aafin Awujalẹ ilẹ Ijebu Ode kan.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn da awọn ọlọpaa si aafin naa lati da aabo bo ẹmi ati dukia ati pe awọn ko fẹ ki ẹnikẹni da omi alaafia ilu naa ru.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ọlọpaa ọlọpaa Ogun, Oluseyi Babaseyi sọ pe awọn da ọlọpaa si aafin naa lati mojuto eto aabo nibẹ ni, ki wọn si ri daju pe ohun gbogbo n lọ letoleto.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa naa tun ṣalaye idi ti wọn fi ranṣẹ pe Oloye Adebisi Adaran ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Gbenden, ti wọn si ni eeyan kan lo kọwe ẹsun ranṣẹ si ileeṣẹ ọlọpaa ti orukọ Adaran si wa ninu rẹ.

Babaseyi sọ pe Adaran yọju si ileeṣẹ ọlọpaa loootọ, ti wọn si fi ọrọ wa lẹnu wo lori ẹsun ọhun ki wọn to fun ni Iyanda lati maa lọ sile latari pe o jẹ ilu mọọka amọ to ni iwadii ṣi n lọ lori ẹsun naa.

Atẹjade naa rọ awọn eeyan lati ma rii ipe naa bi ẹni pe o jẹbi ẹsun kankan bayii nitori igbesẹ naa ko tumọ si o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

O sọ aridaju rẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa maa ṣe ohun gbogbo to yẹ, ti wọn ko si ni fi igba kan bọ omiran ninu, ti wọn si maa tẹle gbogbo ilana ti ofin la kalẹ lati ma tẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ.

Igbimọ Adele Oba Awujale-in-Council pe gomina lẹjọ lori yiyan Awujale tuntun

Ṣaaju ni iroyin kan ti jade pe igbimọ Adele Oba Awujale-in-Council ti pe gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ati igbimọ Awujale Interregnum Administrative Council lẹjọ ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Ogun to wa ni ilu Ijebu Ode.

Igbimọ naa ninu ẹsun ti wọn fi kan sọ pe awọn ti wọn fẹsun kan naa n gbiyanju lati da eto ifọbajẹ ni ilu Ijebu Ode ru.

Awọn mii ti wọn tun pe lẹjọ ninu iwe ipẹjọ naa ni Kọmiṣanna fun eto idajọ, Kọmiṣanna fun eto ileeṣẹ ijọba ibilẹ, Olisa Ijebu Ode, Oloye Rasheed Adesanya atawọn mii.

Atẹjade ti ọfiisi Adele Oba Awujale-in-Council fi lede, awọn mẹsan-an to wa ninu igbimọ naa eyi ti Ọgbẹni Ọja ti ilẹ Ijebu, Dokita Sonny Kuku ṣaaju rẹ n beere pe ki ile ẹjọ ri igbimọ wọn nikan gẹgẹ bi eyi to laṣẹ lori aṣa ati iṣe ilu Ijebu ṣaaju ki wọn to yan Awujale.

Bakan naa ni wọn n fẹ ki ile ẹjọ da gomina atawọn ileeṣẹ ijọba kan lọwọ kọ lori didasi tabi gbigbe aṣẹ igbimọ Adele Oba Awujale-in-Council ti eyi to le nipa lori ojuṣe wọn.

Wọn fi kun pe ki ile ẹjọ da igbimọ Awujale Interregnum Administrative Council duro lati ye ṣe ipade tabi gbe igbesẹ ofin lori Ijebu Ode.

Ẹ o ranti pe awọn oloye Ijebu-Ode ati igbimọ Awujalẹ Interregnum Administrative Council ti ijọba ipinlẹ Ogun gbe dide ninu oṣu Kẹjọ ọdun to kọja lẹyin ti Ọba Sikiru Adetona re iwalẹ aṣa fẹnuko lati tu igbimọ naa ka, ki wọn si gbe igbimọ Adele Oba Awujale-in-Council dide lati maa ri si ọrọ ilu Ijebu Ode titi ti wọn fi maa yan Awujalẹ tuntun.