Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Kí o tó ti ìka àbámọ̀ bẹnu lórí lílo afẹ́fẹ́ gáàsì CNG fún ọkọ̀ rẹ, tàbí wọ inú ọkọ̀ tó ń lò ó, yẹ àwọn ìkìlọ̀ yí wò
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
O ṣe e se ko ti rí fídíò ọkọ̀ bọ́ọ̀sì tó deede gbiná lórí ìrìn ni Berger, ipinle Eko, lẹyin ti silinda CNG to n lo gbina. Ori ko ero mẹtadinlogun to wa ninu rẹ yọ, àmọ́ ọkùnrin kan jona kọjáala.
Lootọ ni Afẹfẹ CNG dinwo ju bentiroolu lọ, sugbon ohun tó ń bẹ leyin ọfà ju oje lo.
Ko to sọ ọkọ̀ rẹ di èyí tó ń lo CNG:
- Ọkọ rẹ gbọdọ wa ni ipo tó dára - kò sì pe epo tàbí ọili ń jó, gbogbo àwọn wáyà inu rẹ n ṣíṣẹ dáadáa, ẹnjini ọkọ̀ naa da pé, ọ̀pá tó ń gbé èéfín jáde ń ṣíṣẹ to péye. Bi ọkọ̀ rẹ ko ba dára, CNG yóò túbọ̀ mú kó pọ̀ sí ní.
- Ríi dájú pé akọṣẹmọṣẹ ti jọba fọwọsi lo ba ọ ṣètò CNG rẹ, Ki wọ pàápàá o si kẹkọ akọye nipa lilo rẹ
- Ko to gbé ọkọ̀ náà jáde lojoojumọ, ṣe ayẹwo boya gaasi n run, ma gbé ẹrù sori agolo CNG, ma kò èrò akoju, Ma se atunse ọkọ ni ibi ti a ko fowo si ma je ki ero joko leti silinda, ma si foju fo apẹ̀rẹ̀ kankan.
Fún eyín èrò tẹ ń wọ ọkọ̀ to n lo CNG:
- Ki e to wọle, wa ami CNG.
- Ti ero ba joko lori gaasi, ma wọle.
- Ma joko leti silinda.
- Ṣi ferese silẹ daadaa
- Ti e ba n gboorun gaasi tabi ti ẹ ba n gbọ pé silinda n pariwo,
- Sọ fun awakọ ki o duro, ko pa enjini, ki ẹ si jade ni lalaafia
- Owo ọkọ̀ to san ko to ẹ̀mí rẹ