Lẹ́yìn tó gba lẹ́tà ìkìlọ̀ lọ́dọ̀ ìjọba àti ìlérí pé òun ò sí lábẹ́ ẹnikẹ́ni, Oluwo ṣèpàdé bínúkonú pẹ̀lú àwọn eléégún

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọpọ awọn to ri Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi nibi to ti n ṣe ipade pẹlu awọn Eleegun ninu Aafin rẹ lo lanu silẹ, ti wọn si fẹẹ le paa de, nitori to jẹ iyalẹnu fun wọn.

Kabiyesi naa lo ti fi ọpọlọpọ ọdun kẹyin si aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba, paapaa awọn ẹlẹsin abalaye nilu Iwo.

Ọba Akanbi nibi ipade to ṣe pẹlu awọn eleegun naa jẹ ko di mimọ pe oun ko kẹyin si aṣa Yoruba, bi ko ṣe pe ohun ti wọn n fi aṣa naa ṣe loun lodi si.

Pupọ ninu awọn to mọ ọba naa, ni wọn mọ pe latilẹ ni Oluwo ti lodi di awọn ẹlẹsin ibilẹ, to si maa n sọ ọ nita gbangba wi pe oun kii ṣe ikeji oriṣa, bi ko ṣe alaṣẹ lori gbogbo oriṣa.

Nigba to n sọrọ, Oluwo, Telu akọkọ sọ pe nnkan toun koro oju si ni ki wọn maa lo ọdun Egungun lati maa fi ṣiṣẹ ibi, eyi to n gbogun ti alaafia ilu.

Kabiyesi naa jẹ ko di mimọ pe gbogbo iwa ipa ti wọn maa n fi ọdun Egungun ṣe, loun ko ṣe fẹẹ tẹle wọn.

O ni bi ki wọn maa fipa ba awọn obinrin laṣepọ, ki wọn maa ṣa awọn eeyan lada nitori ọdun Egungun loun ko ṣe fẹẹ gba ti wọn.

Ninu ọrọ rẹ, o ṣaaye pe, "Mi o ni ki ẹ ma ṣe ọdun Egungun yin, ṣugbọn ẹ ko gbọdọ fa wahala, mi o fẹ ki iwa ipa ṣẹlẹ lasiko temi. Egungun n bẹ, ṣugbọn ẹ jẹ ka jo, ka dunnu.

"Ọdun lẹ sọ pe ẹ n ṣe, kii ẹ ka maa ṣa ara wa ni ada. Eegun to ba ti maa sọ pe oun ma maa mu ada lọwọ, ko le wọ aafin mi, ko lọ sibomiran.

Taa ló dá gbogbo wàhálà náà sílẹ̀

Ọba Akanbi sọ pe ẹnikan to n jẹ Sokoti, toun pe ni Eleegun Ọba lo maa n ṣa awọn eeyan lada, toun si sọ pe oun ko fẹẹ rii mọ ninu aafin oun.

Kabiyesi sọ ọ di mimọ pe o digba ti Sokoti naa ba yipada kuro ninu lilo eEgungun lati maa ṣa awọn eeyan lada, koun to le jẹ ko pada sinu aafin.

O wa sọ pe inu oun dun bayii, nitori pe alaafia ti n jọba pada, nitori pe wọn kii fi bẹẹ lo ọdun Egungun lati maa fi ṣiṣẹ ibi laaarin ilu mọ.

O ni alaafia ati iṣọkan lo yẹ ki awọn ọdun aṣa ibilẹ maa gbe ga, kii ṣe ki wọn maa fi da ogun silẹ.

"Ṣokoti la pe ni Eegun Ọba, nitori rẹ ni nko ṣe gba ko wọbi, nitori pe nigba ti ẹni ti a pe ni eegun ọba ba n mu adad ani, ṣe o fẹ ki gbogbo eegun yooku maa mu ada lọwọ ni," Oluwo sọ bẹẹ.

"Nnkan to si n fa ki wọn maa ṣa awọn eeyan lada niyẹn. Lo wa bo o ṣe ma jo, bi o ṣe ma maa pidan. Ka jọ jo ninu aafin, aṣa niyẹn.

"Onikaluku le rin lasiko yii, Aafa le rin, Pasitọ le rin, bi wọn ba n ṣe eegun, lai jẹ pe wọn n ṣa awọn eeyan lada.

"Were lẹni to ba n ṣe ọdun, to n ṣa awọn eeyan lada, tabi to n lu awọn eeyan kaakiri. Ọpọ awọn ẹlẹsin lo n ṣe ọdun, ṣugbọn ti wọn kii na eeyan lẹgba tabi ṣa eeyan lada."

"Ki awọn ẹlẹsin too de la ti n ṣe Egungun n'Iwo"

Ọba Akanbi sọ pe aṣa ilẹ Iwo ni Egungun, ati pe aṣa naa ti wa ki ẹsin Kristẹẹni ati Egungun too de.

O ni ki lo de to jẹ pe aṣa ibilẹ ati adayeba ni wọn n lo lati maa fi huwa jagidijagan, eyi to ni ko bojumu to.

"A ri awọn to n ṣe Keresimesi ati Ileya, ṣugbọn wọn kii na eeyan. O ṣe a jẹ ohun ti a pe ni aṣa ibilẹ wa ni Iwo, ko to di pe ẹsin Kristẹẹni ati Musulumi de, ni wọn wa fi n ṣa awọn eeyan lada?

"Awa n tun aṣa naa ṣe, a si n ṣe afọmọ rẹ. Awọn eeyan ti n wọ aṣọ ofi ati abeti aja lasiko yii. Emi maa n wọ ọ, mo si maa n ṣakọ pẹlu ẹ. Maa wọ aṣọ Yoruba, maa tun fi ṣakọ.

"Aṣa wa dun, ti ko ba ti si pipaayan ninu rẹ, tabi a n lu eeyan. Wọn ko na eeyan mọ nile Keu gan lasiko. Awọn ile-ẹkọ gan an ti dinwọ lilu akẹkọọ ku.

"Ohun to kan mi ni aṣa Yoruba, ti ko ni jẹ ki awọn eeyan maa bẹru. Alaafia ati idunnu lo yẹ ka maa fi ṣe aṣa wa.

"Ko si nnkan to kan ẹnikẹni pẹlu ohun ti onilu ba lu nilu. Bi onilu ba lu ilu ọtẹ, iwọ lo wa kan lati mọ boya iwọ lo n ba wi, tabi bẹẹ kọ. Wọn n fi ilu ji ọba laye atijọ ni. Ilu ti wọn ko ba fi ji ọba, ilu ogun ati ọtẹ ni.

"Ko si ilu teeyan yoo lu nilẹ Yoruba loni, yatọ si eyi ti wọn ma fi n ji mi laarọ, ilu ogun ati ọtẹ ni. Awọn to si n lu ilu naa, adura ni wọn tun fi n ṣe e.