Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Iṣẹ́ abẹ márùn ún ni mo ṣe nítorí àti bímọ, ọkọ mi wọ aṣọ kan náà fún ọjọ́ mẹ́sàn án kí n lè bímọ - Toyosi Adesanya
Gbajumọ oṣere tiata, Toyosi Adesanya, ti sọ pe oju oun ri to ki Ọlọrun to sọ oun di ọlọmọ laye.
Oṣere ori itage naa to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe ''ẹmarun-un ni mo ṣiṣẹ abẹ lọdun 2022 nitori mo n wa ọmọ.
Nigba to de asiko kan, dokita gan an sọ fun mi pe o to gẹẹ.''
Toyosi ni wiwa ọmọ ati riri ọmọ wa lọwọ Ọlọrun.
O sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo ti o ṣe pẹlu BBC Yoruba wi pe gbogbo ọna ti eeyan maa fi n wa ọmọ ni oun gba fi wa ọmọ.
''Ọdun mẹẹdogun ni mo lo ninu igbeyawo mi akọkọ ti n ko si ri ọmọ bi nibẹ.
Ọkọ mi ti Ọlọrun pada jogun ọmọ fun mi lati ọdọ rẹ yii naa ti bi akọ, wọn si ti bi abo ka to pade.
Ọkọ mi yii si ba mi rinrin ajo naa gan an, laarin ọdun mẹfa ti emi ati Ajibola Oyin-Adejobi fi rinrin ajo wiwa ọmọ yii; ko si ọkunrin to ba mi rin iru irinajo yẹn ri.
Wọn ni ki ọkọ mi wọ aṣọ kan naa fun ọjọ mẹsan an tori ki n le bimọ, wọn si ṣe bẹẹ nitori mi.
Mo loyun nigba yẹn loootọ, amọ, awọn nnkankan tun ṣẹlẹ, lẹyin naa ni mo tun ṣiṣẹ abẹ.''
Adesanya ni agbo oṣere mi titi nigba toun pada bimọ, iyalẹnu lo si jẹ foun gan an.
O ni awọn kan tiẹ sọ pe oju oun ko jọ oju ẹni to n woju Ọlọrun fun ọmọ.
Toyosi ni loootọ loun o jọ iṣoro airọmọbi tori oun ni igbagbọ wi pe Ọlọrun yoo sọ oun di ọlọmọ lọjọ kan
Gbajumọ oṣere naa ni ''mo gbagbọ pe ayọ gbogbo awọn to n woju Ọlọrun fun ọmọ naa yoo de bi ayọ temi naa ṣe de.''