Makinde ṣàlàyé ìdí tó fi ń tako Tinubu fún ipò Ààrẹ lásìkò ìdìbò 2027

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bi irin ajo eto idibo apapọ ọdun 2027 ṣe ti bẹrẹ lati nnkan bi oṣu diẹ sẹyin, ni oniruuru ọrọ ti n jade nipa bi eto idibo naa yoo ṣe ri.

Awọn oludije ati ẹgbẹ oṣelu ni wọn ti n sọ gbogbo ohun ti wọn yoo ṣe fawọn araalu nigba ti wọn ba de ipo.

Gomina Seyi Makinde tipinlẹ Oyo to jẹ oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All People's Movement, APM ti jade sita lati sọ awọn idi pataki to fi fẹẹ dije du ipo Aarẹ, paapaa lati tako Aarẹ Bola Ahmed Tinubu toun naa fẹẹ pada fun saa keji.

Makinde tu gbogbo awọn aṣiri idi to fi fẹẹ gba ipo naa mọ Aarẹ Tinubu lọwọ, ati gbogbo awọn ohun to ṣẹẹ to fi pada lẹyin rẹ.

Oludije sipo aarẹ naa jẹ ko di mimọ pe oun ko nigbagbọ kankan mọ ninu iṣejọba Aarẹ Tinubu, ati pe iṣakoso naa ko le dari Naijiria sọna ilẹ ileri.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Makinde ṣatilẹyin Aarẹ Tinubu lọdun 2023, pẹlu bo ṣe wa ninu ẹgbẹ alatako, People's Democratic Party, PDP lọdun naa.

Kí ló dé tí Makinde fẹ́ẹ́ díje tako Ààrẹ Tinubu?

Ṣugbọn nigba to n sọrọ, Makinde jẹ ko di mimọ pe kii ṣe pe oun deedee pinnu lati tako Tinubu nitori wi pe awọn jọ pinya, bi ko ṣe nipa ọjọ iwaju Naijiria to jẹ oun logun, ati awọn oniruuru anfaani to wa fawọn ọmọ Naijiria.

Makinde lo tu gbogbo awọn aṣiri yii ninu ọrọ to gbe jade soju opo ipolongo idibo rẹ to pe ni Reset Nigeria l'Ọjọbọ to kọja.

Nibẹ lo ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa erongba ati afojusun rẹ nidi oṣelu, ati awọn agbeyẹwo iṣakoso Tinubu.

Gomina naa sọ pe oun ṣatilẹyin fun Aarẹ Tinubu nitori igbagbọ toun ni pe Aarẹ yoo mu iṣọkan ba gbogbo ọmọ Naijiria, ti yoo si ṣe ijọba oniṣọkan, ati awọn igbagbọ pe yoo koju awọn ipenija to n koju eto ọrọ aje.

Ṣugbọn ṣa, o ni agbeyẹwo toun ṣe, ti yi ọkan oun pada laaarin ọdun mẹta ti Aarẹ Tinubu fi wa ni iṣakoso.

"Mo ṣatilẹyin fun Aarẹ Tinubu nitori pe mo nigbagbọ wi pe yoo mu gbogbo eeyan wa papọ ni iṣọkan lati gbe ijọba oniṣọkan larugẹ. Mo nigbagbọ pe iṣakoso rẹ yoo koju ipenija eto ọrọ aje wa, ti yoo si ṣilẹkun ọpọ anfaani tuntun silẹ fawọn ọmọ Naijiria lati gbe igbe aye to dara," Makinde sọ bẹẹ.

"Ọdun mẹta lẹyin rẹ, nko nigbagbọ pe iṣakoso rẹ n gbe wa lọ si awọn ibi ti mo fojusun yii mọ."

Irú èèyàn wo ni Makinde?

Gomina Oyo naa ṣalaye pe oun ko jade lati inu idile olowo tabi akuṣẹ, o sọ pe iṣẹ olukọ ni baba oun yan laayo, ko to di pe o tun kọṣẹmọṣẹ nipa eto iṣiro owo, nigba ti mama jẹ jẹ amoju ẹrọ foonu nileeṣẹ ijọba.

O ni bo tilẹ jẹ pe awọn obi oun kii ṣe ọlọrọ, ṣugbọn oun dagba ninu Naijiria ti idile nigbagbọ pe eto ẹkọ, titẹra mọṣẹ ati ipinnu le ṣilẹkun anfaani gidi silẹ fun awọn ọmọ wọn.

Makinde loun lọ sile ẹkọ Bishop Phillips Academy to wa niluu Ibadan, ko to tẹsiwaju ni fasiti ipinlẹ Eko (UNILAG), nibi to ti kẹkọọ nipa iṣẹ imọ-ẹrọ.

Onimọ-ẹrọ naa sọ pe oun pada tẹpa mọ iṣẹ naa lati da ileeṣẹ Makon Engineering and Technical Services silẹ nigba toun pe ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye siwaju, O ni ileeṣẹ naa gbera daadaa to fi di pe boun ṣe n ṣiṣẹ ni Naijiria, loun tun n fi orukọ ileeṣẹ naa ṣiṣẹ nilẹ okeere, pẹlu boun ko ṣe jade lati inu idile olowo tabi ọlọrọ, tabi nibi ti wọn ti mọ eeyan nidi oṣelu.

"Nko de awọn ipo yii nitori pe mo wa lati inu idile olowo tabi ọlọrọ, tabi ibi ti wọn ti mọ eeyan nidi oṣelu. Mo ni eto ẹkọ, mo si kọ awọn ẹkọ to wulo fun mi, bẹẹ ni mo ri awọn anfaani ti mo ṣiṣẹ fun lati ṣe amulo wọn," o fidi eyi mulẹ.

"Naijiria lo fun mi ni anfaani lati gbe igbe aye ala mi. Awọn nnkan to n si kọmi lominu ree nipa Naijiria ti a ni lonii."

Makinde ni ibeere toun maa n beere ni pe boya ọdọ Naijiria le ri irufẹ anfaani naa, paapaa lẹyin ti wọn ba pari eto ẹkọ wọn lati ri iṣẹ ati lati da iṣẹ silẹ.

O ni awọn ipinnu oun ni lati pese orileede ti ọmọ Naijiria yoo ri ọgbọn ninu wi pe titẹra mọ iṣẹ le mu igbe aye rere ba wọn.

Kí ló gbé Makinde dé ìdí òṣèlú?

Oludije sipo Aarẹ lẹgbẹ APM jẹ ko di mimọ pe erongba oun latilẹ ni ṣiṣe aanu fun awọn eeyan lagbegbe toun ba wa, nipa ṣiṣe atilẹyin fun eto ẹkọ awọn eeyan, iranlọwọ fun awọn idile ati awọn agbekalẹ ọtun fawọn agbegbe kaakiri.

Makinde ni lẹyin toun bẹrẹ awọn nnkan wọnyi, loun ṣakiyesi pe owo to n wọle foun ko le jẹ koun tọju ọpọ eeyan, bi ko ṣe awọn perete, nigba to jẹ pe ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ Naijiria lo nilo anfaani.

O jẹ ko di mimọ pe awọn ipinnu oun yii lo jẹ koun ronu lati wọnu oṣelu, koun si le ṣoju araalu.

O ni laarin ọdun 2007 si 2015, oun dije fun ipo aṣofin tii ṣe sẹnetọ lẹẹmeji ati gomina, toun si padanu awọn idibo naa.

Siwaju sii lo sọ pe erongba ti afojusun oun ni ko jẹ koun ni irẹwẹsi ọkan, idi toun tun fi gbe apoti lọdun 2019, toun si jawe olubori.

"Mo de ipo gomina lai ni baba isalẹ nidi oṣelu. Mo si maa n sọ ọ ni gbogbo igba wi pe nko ni baba iṣalẹ, bi ko ṣe Ọlọrun tii ṣe baba mi," O sọ bẹẹ.

Makinde sọ siwaju pe awọn iriri toun ni ninu iṣejọba lo foun lanfaani lati jẹ ki awọn erongba oun di ilana ati eto, toun si ni iwuri nla lawọn aṣeyọri oun jẹ foun gẹgẹ bi gomina ipinẹ Oyo laaarin ọdun meje.

O ni iṣakoso oun ti ṣafihan wi pe ijọba le ṣe ohun ọtun nipa ṣiṣilẹkun awọn anfaani silẹ fun awọn eeyan.

Bakan naa sọ pe didari iṣakoso yatọ si didari ileeṣẹ to n ṣe daadaa lawujọ, to si loun ṣe aṣiṣe, pẹlu bo ṣe tọrọ idajriji.

O ni awọn iriri toun ni ti ro igbagbọ oun lagbara wi pe awọn agbekalẹ oun le ran gbogbo araalu Naijiria lọwọ.

Kí ló dé tí Makinde kò dúró de ọdún 2031?

Nigba to n sọrọ nipa idi ti ko fi duro ki iṣakoso Tinubu pari ko too jade du ipo naa, iyẹn lọdun 2031, tabi pe ko duro de ọdun 2035, Makinde sọ pe ibi ti wọn n wa tukọ eto ọrọ aje Naijiria lọ, lo n kọ oun lominu.

O ni ọjọ iwaju awọn iran to n bọ lẹyin, loun nilo lati daabo bo pẹlu ibi ti iṣakoso yii n dori eto ọrọ aje kọ.

Siwaju sii lo ni awọn ọdọ ti wọn ṣe n dide pẹlu oniruuru imọ, ẹkọ ati ọgbọn atinuda, ṣugbọn ti wọn ko ri isẹ fi ṣe.

Bakan naa lo tun mẹnuba awọn okoowo ti wọn n tiraka nitori iṣoro aisi ina mọnamọna ati owo ọkọ to lọ soke.

Makinde sọ pe ọpọ araalu lo jẹ pe wọn ti ba ijakulẹ pada nipa awọn agbekalẹ iṣakoso yii, ti wọn si nigbagbọ pe ibo wọn ko le ko ipa kankan."Ọrọ ijakulẹ naa ye mi. A ni gbọ awọn oniruuru ileri sẹyin. A ti ri wọn ijọba to n wa, to n lọ. Gbogbo igba ni wọn si n sọ fun wa pe nnkan yoo dara, sibẹ ọmọ ọmọ Naijiria lo ṣi n lakaka lati ri jẹ," Makinde sọ siwaju.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe, "Ṣugbọn nko gba pe ohun ti Naijiria le jẹ niyi."

o sọ siwaju pe ki ijọba apapọ rii daju pe wọn n ṣagbeyẹwo awọn ipinnu ti wọn n ṣe daadaa, ko ma ba a ṣakoba fun awọn ipinlẹ.

"O n kọmi lominu pe bi a ba ṣi aṣiṣe lori ọdun mẹrin to n bọ, akoba ti yoo sẹ fun eto ọrọ aje ati iran to n bọ lọna.

"Idi ree ti nko le fi duro. Idi ti mo fi gbagbọ ree wi pe a nilo lati ṣayipada lori ibi ti a n lọ lọdun 2027," Makinde sọ bẹẹ.