Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
Ohun tí a mọ̀ nípa ìkọlù sáwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú NDC l'Eko níbi tí Peter Obi ti fẹ́ báwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀
Awọn afurasi janduku kan da ipade ẹgbẹ oṣelu National Democratic Congress (NDC) ru niluu Eko lỌjọbọ ọjọ kejila oṣu Kọkanla yii.
Fidio kan to ti lu ori ayelujara pa bayii ṣafihan bawọn janduku ọhun ṣe ba ọpọ dukia jẹ nibi ipade ọhun.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn eeyan kan farapa nibi iṣẹlẹ naa.
Ipade ọhun to yẹ ko waye ni gbọngan Classique Event Centre lagbegbe Oregun niluu Eko ni a gbọ pe oludije aarẹ fẹgbẹ NDC, Peter Obi, ti fẹ bawọn ololufẹ rẹ sọrọ.
Nnkan ti a gbọ ni pe Obi ko tii de ibi ti ipade naa yoo ti waye ti rogbodiyan fi bẹ silẹ nibẹ.
Ọkan lara awọn to farapa nibi iṣẹlẹ naa sọ fun Channels TV wi pe ija bẹ silẹ lẹyin tawọn janduku to yabo gbọngan ti Obi ti fẹ bawọn ololufẹ rẹ sọrọ doju ija kawọn to wa ninu gbọngan na.
Ọkunrin ọhun to ni apa lori kọminu wi pe o ṣee ṣe ki eto idibo ọdun 2027 to n bọ ma lọ ni irọwọ rọsẹ pẹlu nnkan to ṣẹlẹ nibi ipade naa.
Awọn ẹṣọ eleto aabo pada lọ sibẹ, wọn si pẹtu sija to ṣẹlẹ nibẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ko tii sọrọ lori awọn to da ipade ẹgbẹ oṣelu NDC naa ru niluu Eko.
Ti ẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni iroyin kan sọ pe awọn janduku ṣekọlu si ọkọ to tẹle Peter Obi niluu Calabar nipinlẹ Cross River.