Ìwọ ń wo ẹ̀dà ọ̀rọ̀-nìkan ti ìkànnì yìí tí ó máa ń lo dátà díẹ̀. Wo ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìkànnì náà pẹ̀lú gbogbo àwòrán àti fídíò.
2027 Election: INEC fẹ́ ṣe 'ètò ìdìbò ààrẹ' lóṣù kọkànlá ọdún 2026, ìdí rèé
Ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria, Independent National Electoral Commission, INEC ti kede pe awọn maa ṣe idanrawo ranpẹ lati fi ṣe igbaradi lati mọ bi eto idibo gbogbogbo gangan ṣe maa lọ pẹlu awọn atunṣe ti wọn ti ṣe sawọn ẹrọ ti wọn fẹ lo fun eto idibo naa.
Ni ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Kọkanla ni wọn kede pe idanrawo ranpẹ naa maa waye, to si maa waye kaakiri gbogbo orilẹ ede Naijiria.
Alaga ajọ INEC, Joash Amupitan lo fi ikede naa fi lede lọjọbọ lasiko ijiroro kan ti wọn ṣe pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ Kimpact Development Initiative ni Chatham House ni ilu London.
Amupitan ni idanrawo naa maa ṣe iranwọ fun ajọ naa lati ṣayẹwo gbogbo awọn irinṣẹ ti wọn maa lo lati ṣe iforukọsilẹ awọn oludibo ati eyi ti wọn yoo maa fi fi esi idibo ṣọwọ lori ayelujara nibi eto idibo gbogbogbo loṣu Kiini ati oṣu Keji ọdun to n bọ.
O fi kun pe ajọ naa ti ṣagbedide awọn ilana lati fi dena awọn ohun to le mu ki esi idibo ni ẹja n bakan ninu, to si tun maa dena fifi awọn esi idibo to ba ti le kun ju bi o ṣe yẹ lọ lati wọ ẹrọ ajọ naa.
"A ri pe ohun to maa n fa kudiẹkudiẹ nibi esi idibo ati kikede esi ibo ni Naijiria kii ṣe ohun to n waye ni ibudo idibo bikoṣe oriko ti wọn ti maa n ko esi ibo jọ.
"Ni ọdun 2023, awọn apẹẹre wa pe awọn esi idibo ti wọn kede ko pe, tawọn mii si ṣafihan pe awọn esi ibo ti wọn fi ranṣẹ si IReV ju iye ibo ti wọn di lawọn ibomiran lọ.
O ṣalaye pe awọn ti wa ni ilana ati imọ ẹrọ lati fi ṣe atunṣe eyi ati pe ti esi ibo ko ba ti poju ow obo ṣe yẹ ko w ani ibudo idibo, ko ni wọ IReV rara.
Ki ni ayipada to ti ba BVAS ati IReV?
Amupitan fi kun pe idanrawo naa yoo ṣeranwọ lati fi mu igbooro ba ẹrọ Bimodal Voter Accreditation, BVAS atawọn ẹrọ ti wọn maa n lo lati fi ṣe amojuto esi idibo latari awọn kudiẹkudiẹ to waye nibi eto idibo gbogbogbo ọdun 2023.
O tẹsiwaju pe INEC ti mu amugbooro ba awọn ẹrọ to ṣe kumọkumọ lasiko eto idibo 2023 paapaa awọn ti ooru ati ibi ti wọn ko wọn pamọ si ṣokunfa dipo rira awọn ẹrọ tuntun.
O sọ pe ajọ naa ti n kọ ibudo ti wọn yoo maa ko awọn ohun elo idibo pamọ si eyi ti yoo wa ni ibamu pẹlu bi ayipada oju ọjọ ṣe n waye ni gbogbo ipinlẹ kaakiri to wa ni orilẹ ede Naijiria ati pe awọn ti ra afikun BVAS lati lo lasiko eto idibo.
Alaga INEC tun fi kun pe awọn ti mu adinku ba iye orukọ oludibo to le wa lori BVAS lati 1,250 si 850.
Nibi eto idibo gbogbogbo to kọja, oniruuru awuyewuye lo waye lori fifi esi ibo ranṣẹ lati ori ori ayelujara nipasẹ lilo imọ ẹrọ IReV eyi to mu ki ọpọ eeyan ma ni igbagbọ lori lilo imọ ẹrọ naa.
Amupitan naa sọrọ lori eyi to si ni ọpọ awọn eeyan ni ko i tii ni igbagbọ ninu INEC lori lilo imọ ẹrọ naa lati ọdun 2023.
O sọ pe INEC tun ṣawari rẹ pe awọn ibudo ti wọn ti n ko esi idibo ni kudiẹkudiẹ ti maa n waye dipo ibudo idibo gangan, to si ni iṣẹ ti bẹrẹ lati ṣe atunṣe eyi.
O ni igbagbọ wa pe gbogbo igbesẹ ati ilana ti awọn ti gbe maa mu ayipada ba bi esi idibo ti wọn maa n kede ni ibudo idibo ṣe maa n yatọ si eyi to maa n jade lati ibudo ti wọn ti n ko esi idibo jọ.
O fi kun pe igbesẹ ti awọn gbe yii yoo mu kawọn oludibo ni igboya ninu esi idibo ni kete to ba ti jade.
Bawo ni wọn ṣe maa n ṣe idanrawo eto idibo?
Ajọ INEC maa ṣa awọn ibudo idibo kan ti wọn maa lo lati fi ṣe eto idibo idanrawo naa.
Wọn maa ranṣẹ pe awọn oludibo to ba wa ni awọn ibudo idibo ti wọn ba mu lati wa fun eto idibo naa.
Wọn maa ṣe ayẹwo kaadi idibo awọn eeyan naa pẹlu ẹrọ BVAS.
Bakan naa ni wọn maa ṣayẹwo ika ati oju wọn ti wọn lati fi mọ boya BVAS n ṣiṣẹ bo ṣe yẹ.
Lọpọ igba, eto idibo kii waye lasiko idanrawo eto idibo yii, ti wọn si kii gbe esi idibo kankan jade.