Wo orílẹ̀-èdè 23 tí Amẹrika kìlọ̀ fáwọn ọmọ ilẹ́ náà pé wọn ò gbọdọ̀ rìnrìn àjò lọ àti ìdí abájọ

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Orilẹede Amẹrika ti kilọ fawọn ọmọ ilẹ naa wi pe wọn o gbọdọ rinrin lọ sawọn orilẹede agbaye mẹtalelogun kan.

Ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ile okeere l'Amẹrika lo fi ikilọ yii lede loju opo Facebook rẹ ni ibẹrẹ ọsẹ yii.

Ileeṣẹ ijọba naa ṣalaye pe igbesẹ yii ko sẹyin nnkan to n ṣẹlẹ lawọn orilẹede naa ati aini anfaani ijọba Amẹrika lati ṣeranwọ to yẹ fawọn ọmọ ilẹ naa to ba wa lawọn orilẹede ọhun.

Irufẹ awọn orilẹede yii ni wọn pe ni ''Level 4'' eyi to tumọ si pe awọn ọmọ orilẹede Amẹrika ko gbọdọ lọ sibẹ.

Ijọba Amẹrika ni ewu n bẹ lawọn orilẹede mẹtalelogun ọhun lawọn fi kilọ pe awọn ọmọ orilẹede naa ko gbọdọ rinrin ajo lọ sibẹ.

Wọnyi ni orilẹede mẹtalelogun ti Amẹrika kilọ pe awọn ọmọ ilẹ naa ko gbọdọ rinrin ajo lọ:

Afghanistan

Belarus,

Burkina Faso

Burma

The Central African Republic

Chad

The Democratic Republic of the Congo

Haiti

Iran

Iraq

Lebanon

Libya

Mali

Niger

North Korea

Russia

Somalia,

South Sudan

Sudan

Syria

Uganda

Ukraine

Yemen.

Ipele mẹrin lawọn irufẹ orilẹede ti Amẹrika kilọ fawọn ọmọ ilẹ naa nipa wọn pin si.

Ijọba Amẹrika fikun ikilọ rẹ fawọn ọmọ orilẹede naa to ba wa lawọn orilẹede mẹtalelogun yii.

Ipele akọkọ ti wọn pe ni ''Level 1'' ni awọn orilẹede ti Amẹrika ti ni kawọn ọmọ orilẹede naa ṣora ti wọn ba wa nibẹ tabi ti wọn ba fẹ rinrin ajo lọ sibẹ.

Ijọba Amẹrika ṣe afikun ikilọ rẹ fawọn ọmọ orilẹede naa to ba wa lawọn orilẹede to wa ni ipele keji eyi to jẹ ''Level 2.''

Awọn orilẹede to wa ni ipele kẹta to jẹ ''Level 3'' ni ijọba Amẹrika gbawọn ọmọ ilẹ naa nimọran pe ki wọn ro o daadaa ki wọn to rinrin ajo lọ sibẹ.

Ipele kẹrin ti i ṣe Level 4 ni ijọba Amẹrika kilọ fawọn ọmọ orilẹede naa wi pe wọn o gbọdọ lọ sibẹ rara tori ewu to wa nibẹ.