Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń lo ìpara àbaadì, ẹ wá wo tuntun tí NAFDAC ṣàwárí l'Ekoo

Oríṣun àwòrán, NAFDAC
Lẹyin ọsẹ diẹ ti ajọ to n ri si ounjẹ ati oogun lilo lorilẹede yii, NAFDAC, ṣawari ibudo ayederu ọti nibudo itaja niluu Eko (Lagos Trade Fair Complex), ajọ naa tun ti ri awọn nnkan ipara ti ko lorukọ atawọn ohun ti wọn fi n ṣe e nibudo kan naa.
NAFDAC ninu fidio kan ti won fi lede loju opo X lọjọ Abamẹta, ṣalaye pe abala ti wọn maa n ko nnkan eelo si ni wọn ti ṣawari naa lọja ọhun.
Ninu fidio naa ni wọn ti fi awọn ike ti wọn n ko ipara si han, pẹlu awọn ọṣẹ ti ko lorukọ.
Ọpọ awọn nnkan ti wọn yoo sọ di ipara abaadi amọ ti ko ni akọle tabi iforukọsilẹ lo kun ibudo naa ni paali-paali.
Bẹẹ ni awọn kan wa ti wọn ti po pọ ti wọn si ti pari.
Ile alaja meji ni ile ti wọn ṣe awọn nnkan ipara yii lọjọ si bi NAFDAC ṣe fidi ẹ mulẹ, lati ibẹrẹ de opin rẹ si ni awọn nnkan ti ko lorukọ naa wa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ẹ o ranti pe ọpọ igba ni ajọ NAFDAC ti kilọ pe awọn nnkan ipara ati iṣaraloge bawọnyi le ṣe akoba fun ara.
Bakan naa ni wọn si rọ araalu lati maa tete fi to ajọ naa leti bi wọn ba kẹẹfin iru nnkan yii.
Loṣu keji ọdun yii ni NAFCAC kede pe oun ṣawari awọn nnkan iṣaraloge ayederu ti ijọba ti fofin de, ti iye re le ni biliọnu mẹta naira.
Ninu ile ikẹru si kan ni wọn tọju awọn ayederu ipara naa si bi NAFDAC ṣe ṣọ, bẹẹ ni ile akọku ni ibẹ pẹlu.
APT Trade Fair Complex ni wọn pe orukọ ibẹ.
Lara awọn nnkan ti NAFDAC kede pe oun ri nigba naa ni: paali ọṣẹ Crusader 728, ọṣẹ E45 ti iye rẹ jẹ 718 ati awọn ọṣẹ Extract Gold whitening kan ti ijọba ti fofin de.

























